Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nítorí kò mọ̀ ọ́n mọ̀ mú ìpọ́njú wá tàbí ìrora wá fún ọmọ ènìyàn.

  2. Láti tẹ mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ gbogbo àwọn ẹlẹ́wọ̀n ní ilẹ̀ náà.

  3. Láti ṣẹ́ ọmọ ènìyàn fún ẹ̀tọ́ rẹ̀ níwájú Ọ̀gá-ògo jùlọ,

  4. láti yí ìdájọ́ ènìyàn padà, ǹjẹ́ Olúwa kò rí ohun bẹ́ẹ̀.

  5. Ta ni yóò sọ̀rọ̀ tí yóò rí bẹ́ẹ̀ tí Olúwa kò bá fi àṣẹ sí i.

  6. Ǹjẹ́ kì í ṣe láti ẹnu Ọ̀gá-ògo jùlọ ni rere àti búburú tí ń wá?

  7. Ẹ jẹ́ kí a yẹ ọ̀nà wa, kí a sì dán an wò, kí a sì tọ Olúwa lọ.

  8. Ẹ jẹ́ kí a gbé ọkàn àti ọwọ́ wa sókè sí Ọlọ́run ní ọ̀run, kí a wí pé,

  9. “Àwa ti ṣẹ̀ a sì ti ṣọ̀tẹ̀ ìwọ kò sì fi ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá.

  10. “Ìwọ fi ìbínú bo ara rẹ ìwọ sì ń lépa wa; ìwọ ń parun láìsí àánú.

  11. Ìwọ ti fi àwọsánmọ̀ bo ara rẹ pé kí àdúrà wa má ba à dé ọ̀dọ̀ rẹ.

  12. títí ìgbà tí Olúwa yóò síjú wolẹ̀ láti òkè ọ̀run tí yóò sì rí i.

  13. Mo pe orúkọ rẹ, Olúwa, láti ọ̀gbun ìsàlẹ̀ ihò.

  14. Ìwọ gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi, “Má ṣe di etí rẹ sí igbe ẹ̀bẹ̀ mi fún ìtura.”

  15. O wá tòsí nígbà tí mo ké pè ọ́, o sì wí pé, “Má ṣe bẹ̀rù.”

  16. Olúwa, ìwọ gba ẹjọ́ mi rò, o ra ẹ̀mí mi padà.

  17. O ti rí i, Olúwa, búburú tí a ṣe sí mi. Gba ẹjọ́ mi ró!

  18. Olúwa ìwọ ti gbọ́ ẹ̀gàn wọn àti ìmọ̀ búburú wọn sí mi,

  19. Olúwa san wọ́n lẹ́san ohun tí ó tọ́ sí wọn fún ohun tí ọwọ́ wọn ti ṣe.

  20. Fi ìbòjú bò wọ́n ní ọkàn, kí o sì fi wọ́n ré.

  21. Ni wọ́n lára kí o sì pa wọ́n run pẹ̀lú ìbínú, lábẹ́ ọ̀run Olúwa.

  22. Olúwa ti fi ihò kíkún fún ìbínú rẹ̀; ó sì tú ìbínú gbígbóná rẹ̀ jáde. Ó da iná ní Sioni tí ó jó ìpìlẹ̀ rẹ̀ run.

  23. Olúwa ti tú wọn ká fúnra rẹ̀; kò sí bojútó wọn mọ́. Kò sí ọ̀wọ̀ fún olórí àlùfáà mọ́, àti àánú fún àwọn àgbàgbà.

  24. Ẹni àmì òróró Olúwa, èémí ìyè wa, ni wọ́n fi tàkúté wọn mú. Àwa rò pé lábẹ́ òjìji rẹ̀ ni àwa yóò máa gbé láàrín orílẹ̀-èdè gbogbo.

  25. Ìwọ ọmọbìnrin Sioni, ìjìyà rẹ yóò dópin; kò ní mú ìgbèkùn rẹ pẹ́ mọ́. Ṣùgbọ́n, ìwọ ọmọbìnrin Edomu, yóò jẹ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ní yà yóò sì fi àìṣedéédéé rẹ hàn kedere.