God
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God
Hesekiah wí fún Isaiah pé, “Rere ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ìwọ sọ.” Nítorí ó rò nínú ara rẹ̀ pé, “Àlàáfíà àti ààbò yóò wà ní ìgbà ayé tèmi.”
Ẹ tù ú nínú, ẹ tu ènìyàn mi nínú, ni Ọlọ́run yín wí.
Sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ fún Jerusalẹmu kí o sì kéde fún un pé iṣẹ́ àṣekára rẹ̀ ti parí, pé à ti san gbèsè ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, pé ó ti rí i gbà láti ọwọ́ Olúwa ìlọ́po méjì fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.
Ògo Olúwa yóò sì di mí mọ̀, gbogbo ènìyàn lápapọ̀ ni yóò sì rí i. Nítorí ẹnu Olúwa ni ó ti sọ ọ́.”
Koríko ń rọ ìtànná sì ń rẹ̀, nítorí èémí Olúwa ń fẹ́ lù wọ́n. Nítòótọ́ koríko ni àwọn ènìyàn.
Koríko ń rọ ìtànná sì ń rẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa dúró títí láé.”
Ìwọ tí o mú ìyìn ayọ̀ wá sí Sioni, lọ sí orí òkè gíga. Ìwọ tí ó mú ìyìn ayọ̀ wá sí Jerusalẹmu, gbé ohùn rẹ sókè pẹ̀lú ariwo, gbé e sókè, má ṣe bẹ̀rù; sọ fún àwọn ìlú u Juda, “Ọlọ́run rẹ nìyìí!”
Wò ó, Olúwa Olódùmarè náà ń bọ̀ wá pẹ̀lú agbára, apá rẹ̀ sì ń jẹ ọba fún un. Wò ó, èrè rẹ̀ sì wà pẹ̀lú rẹ̀, àti ìdápadà rẹ̀ tí ń bá a bọ̀ wá.
Ta ni ó tiwọn omi nínú kòtò ọwọ́ rẹ̀, tàbí pẹ̀lú ìbú ọwọ́ rẹ̀ tí ó wọn àwọn ọ̀run? Ta ni ó ti kó erùpẹ̀ ilẹ̀ ayé jọ nínú apẹ̀rẹ̀, tàbí kí ó wọn àwọn òkè ńlá lórí ìwọ̀n àti òkè kéékèèké nínú òsùwọ̀n?
Ta ni ó ti mọ ọkàn Olúwa, tàbí tí ó ti tọ́ ọ ṣọ́nà gẹ́gẹ́ bí olùdámọ̀ràn rẹ̀?
Ta ni Olúwa ké sí kí ó là á lọ́yẹ àti ta ni ó kọ́ òun ní ọ̀nà tí ó tọ́? Ta ni ẹni náà tí ó kọ́ ọ ní ọgbọ́n tàbí tí ó fi ipa ọ̀nà òye hàn án?
Nítòótọ́ àwọn orílẹ̀-èdè dàbí i ẹ̀kún omi nínú garawa; a kà wọ́n sí gẹ́gẹ́ bí eruku lórí ìwọ̀n; ó wọn àwọn erékùṣù àfi bí eruku múnúmúnú ni wọ́n.
Níwájú rẹ̀ ni gbogbo orílẹ̀-èdè dàbí ohun tí kò sí; gbogbo wọn ló kà sí ohun tí kò wúlò tí kò tó ohun tí kò sí.
Ta ni nígbà náà tí ìwọ yóò fi Ọlọ́run wé? Ère wo ni ìwọ yóò fi ṣe àkàwé rẹ̀?
Òun jókòó lórí ìtẹ́ ní òkè òbírí ilẹ̀ ayé, àwọn ènìyàn rẹ̀ sì dàbí i láńtata. Ó ta àwọn ọ̀run bí ìbòrí ìgúnwà, ó sì nà wọ́n jáde gẹ́gẹ́ bí àgọ́ láti gbé.
Ó sọ àwọn ọmọ ọba di asán àti àwọn aláṣẹ ayé yìí ni ó ti sọ dòfo.
Gẹ́rẹ́ tí a ti gbìn wọ́n, kété tí a gbìn wọ́n, kété tí wọ́n fi gbòǹgbò múlẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó fẹ́ atẹ́gùn lù wọ́n gbogbo wọn sì gbẹ, bẹ́ ni ìjì líle sì gbá wọn lọ gẹ́gẹ́ bí ìyàngbò.
“Ta ni ẹ ó fi mi wé? Tàbí ta ni ó bá mi dọ́gba?” ni Ẹni Mímọ́ wí.
Gbé ojú rẹ sókè kí o sì wo àwọn ọ̀run. Ta ni ó dá àwọn wọ̀nyí? Ẹni tí ó mú àkójọpọ̀ àwọn ìràwọ̀ jáde wá ní ọ̀kọ̀ọ̀kan tí ó sì pè wọ́n ní orúkọ lọ́kọ̀ọ̀kan. Nítorí agbára ńlá àti ipá rẹ̀, ọ̀kan ṣoṣo nínú wọn kò sọnù.
Èéṣe tí o fi sọ, ìwọ Jakọbu? Àti tí o ṣàròyé, ìwọ Israẹli, “Ọ̀nà mi pamọ́ níwájú Olúwa; ìṣe mi ni a kò kọbi ara sí láti ọwọ́ Ọlọ́run mi”?
Ìwọ kò tí ì mọ̀? Ìwọ kò tí ì gbọ́? Olúwa òun ni Ọlọ́run ayérayé, Ẹlẹ́dàá gbogbo ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé. Agara kì yóò da bẹ́ẹ̀ ni kò ní ṣàárẹ̀, àti òye rẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò le ṣe òdínwọ̀n rẹ̀.
Ó ń fi agbára fún àwọn aláàárẹ̀ ó sì fi kún agbára àwọn tí agara dá.
ṣùgbọ́n àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé Olúwa yóò sọ agbára wọn di ọ̀tun. Wọn yóò fìyẹ́ fò lókè bí idì; wọn yóò sáré àárẹ̀ kò ní mú wọn, wọn yóò rìn òòyì kò ní kọ́ wọn.
Ta ni ó ti ṣe èyí tí ó sì ti jẹ́ kí ó wáyé, tí ó ti pe ìran-ìran láti àtètèkọ́ṣe? Èmi Olúwa pẹ̀lú ẹni kìn-ín-ní wọn àti ẹni tí ó gbẹ̀yìn, Èmi náà ni.”
“Ṣùgbọ́n ìwọ, ìwọ Israẹli, ìránṣẹ́ mi, Jakọbu, ẹni tí mo ti yàn, ẹ̀yin ìran Abrahamu, ọ̀rẹ́ mi,