God
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God
Olúwa Olódùmarè, agbára ìgbàlà mi, ìwọ ni ó bo orí mi mọ́lẹ̀ ní ọjọ́ ìjà.
Olúwa, máa ṣe fi ìfẹ́ ènìyàn búburú fún un; má ṣe kún ọgbọ́n búburú rẹ̀ lọ́wọ́; kí wọn kí ó máa ba à gbé ara wọn ga. Sela.
Èmi mọ̀ pé, Olúwa yóò mú ọ̀nà olùpọ́njú dúró, yóò sì ṣe ẹ̀tọ́ fún àwọn tálákà.
Nítòótọ́ àwọn olódodo yóò máa fi ọpẹ́ fún orúkọ rẹ; àwọn ẹni dídúró ṣinṣin yóò máa gbé iwájú rẹ.
Saamu ti Dafidi. Olúwa, èmi ké pè ọ́; yára wá sí ọ̀dọ̀ mi. Gbọ́ ohùn mi, nígbà tí mo bá ń ké pè ọ́.
Jẹ́ kí àdúrà mi ó wá sí iwájú rẹ bí ẹbọ tùràrí àti ìgbé ọwọ́ mi si òkè rí bí ẹbọ àṣálẹ́.
Fi ẹ̀ṣọ́ ṣọ́ ẹnu mi, Olúwa: kí o sì máa pa ìlẹ̀kùn ètè mi mọ́.
Ṣùgbọ́n ojú mi ń bẹ lára rẹ, Olúwa Olódùmarè; nínú rẹ̀ ni èmi ti rí ààbò, má ṣe fà mi fún ikú.
Maskili ti Dafidi. Nígbà tí ó wà nínú ihò òkúta. Àdúrà. Èmi kígbe sókè sí Olúwa; èmi gbé ohùn mi sókè sí Olúwa fún àánú.
Èmi tú àròyé mí sílẹ̀ níwájú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ní èmi fi iṣẹ́ mi hàn níwájú rẹ̀.
Nígbà tí ẹ̀mí mi ṣàárẹ̀ nínú mi, ìwọ ni ẹni tí ó mọ ọ̀nà mi. Ní ipa ọ̀nà tí èmi ń rìn ènìyàn ti dẹ okùn fún mi ní ìkọ̀kọ̀.
Èmi kígbe sí ọ, Olúwa: èmi wí pé, “Ìwọ ni ààbò mi, ìpín mi ní ilẹ̀ alààyè.”
Mú ọkàn mi jáde kúrò nínú túbú, kí èmi lè máa yin orúkọ rẹ. Nígbà náà ni àwọn olódodo yóò yí mi káàkiri nítorí ìwọ yóò fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ba mi ṣe.
Saamu ti Dafidi. Olúwa gbọ́ àdúrà mi, fetísí igbe mi fún àánú; nínú òtítọ́ àti òdodo rẹ, wá fún ìrànlọ́wọ́ mi.
Má ṣe mú ìránṣẹ́ rẹ wá sí ìdájọ́, nítorí kò sí ẹnìkan tí ó wà láààyè tí ó ṣe òdodo níwájú rẹ.
Èmi rántí ọjọ́ tí ó ti pẹ́; èmi ń ṣe àṣàrò lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ mo sì ṣe àkíyèsí ohun tí ọwọ́ rẹ ti ṣe.
Èmi na ọwọ́ mi jáde sí ọ: òǹgbẹ rẹ gbẹ ọkàn mi bí i ìyàngbẹ ilẹ̀. Sela.
Dá mi lóhùn kánkán, Olúwa; ó rẹ ẹ̀mí mi tán. Má ṣe pa ojú rẹ mọ́ kúrò lára mi kí èmi má ba à dàbí àwọn tí ó lọ sínú ihò.
Mú mi gbọ́ ìṣeun ìfẹ́ rẹ ní òwúrọ̀: nítorí ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé. Fi ọ̀nà tí èmi i bá rìn hàn mí, nítorí èmi gbé ọkàn mi sókè sí ọ.
Gbà mí kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi, Olúwa, nítorí èmi fi ara mi pamọ́ sínú rẹ.
Kọ́ mi láti ṣe ìfẹ́ rẹ, nítorí ìwọ ni Ọlọ́run mi jẹ́ kí ẹ̀mí rẹ dídára darí mi sí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú.
Nítorí orúkọ rẹ, Olúwa, sọ mi di ààyè; nínú òdodo rẹ, mú ọkàn mi jáde nínú wàhálà.
Nínú ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà, ké àwọn ọ̀tá mi kúrò, run gbogbo àwọn tí ń ni ọkàn mi lára, nítorí pé èmi ni ìránṣẹ́ rẹ.
Ti Dafidi. Ìyìn sí Olúwa àpáta mi, ẹni tí ó kọ́ ọwọ́ mi fún ogun, àti ìka mi fún ìjà.
Òun ni Ọlọ́run ìfẹ́ mi àti odi alágbára mi, ibi gíga mi àti olùgbàlà mi, asà mi, ẹni tí èmi gbẹ́kẹ̀lé, ẹni tí ó tẹrí àwọn ènìyàn ba lábẹ́ mi.