Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Òòrùn láti jẹ ọba ọ̀sán; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

  2. Òṣùpá àti ìràwọ̀ láti jẹ ọba òru; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

  3. Fún ẹni tí ó kọlu Ejibiti lára àwọn àkọ́bí wọn; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

  4. Ó sì mú Israẹli jáde kúrò láàrín wọn; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

  5. Pẹ̀lú ọwọ́ agbára àti apá nínà; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

  6. Fún ẹni tí ó pín Òkun pupa ní ìyà; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

  7. Ó sì mú Israẹli kọjá láàrín rẹ̀ nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

  8. Ṣùgbọ́n ó bi Farao àti ogun rẹ̀ ṣubú nínú Òkun pupa; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

  9. Fún ẹni tí ó sin àwọn ènìyàn rẹ̀ la aginjù já nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

  10. Fún ẹni tí ó kọlu àwọn ọba ńlá; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

  11. Ó sì pa àwọn ọba olókìkí nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

  12. Sihoni, ọba àwọn ará Amori nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

  13. Àti Ogu, ọba Baṣani; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

  14. Ó sì fi ilẹ̀ wọn fún ni ní ìní, nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

  15. Ìní fún Israẹli, ìránṣẹ́ rẹ̀, nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

  16. Ẹni tí ó rántí wa ní ìwà ìrẹ̀lẹ̀ wa; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

  17. Ó sì dá wa ní ìdè lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

  18. Ẹni tí ó fi oúnjẹ fún àwọn ẹ̀dá gbogbo nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

  19. Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run ọ̀run; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

  20. Àwa ó ti ṣe kọ orin Olúwa ní ilẹ̀ àjèjì

  21. Olúwa rántí ọjọ́ Jerusalẹmu, lára àwọn ọmọ Edomu, àwọn ẹni tí ń wí pé, “Wó o palẹ̀, wó o palẹ̀ dé ìpìlẹ̀ rẹ̀!”

  22. Ti Dafidi. Èmi yóò yìn ọ́ tinútinú mi gbogbo; níwájú àwọn òrìṣà ni èmi ó kọrin ìyìn sí ọ.

  23. Èmi ó máa gbàdúrà sí ìhà tẹmpili mímọ́ rẹ̀ èmi ó sì máa yin orúkọ rẹ nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ àti òtítọ́ rẹ; nítorí ìwọ gbé ọ̀rọ̀ rẹ ga ju orúkọ rẹ lọ.

  24. Ní ọjọ́ tí mo ké pè é ọ́, ìwọ dá mi lóhùn, ìwọ sì fi ipa mú mi lára le ní ọkàn mi.

  25. Gbogbo àwọn ọba ayé yóò yìn ọ́, Olúwa, ní ìgbà tí wọn bá gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ.