God
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God
Bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí ń kọjá lọ kò wí pé, ìbùkún Olúwa kí ó pẹ̀lú yín: àwa ń súre fún yin ní orúkọ Olúwa.
Orin fún ìgòkè. Láti inú ibú wá ni èmi ń ké pè é ọ́ Olúwa
Olúwa, gbóhùn mi, jẹ́ kí etí rẹ kí o tẹ́ sílẹ̀ sí ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.
Olúwa, ìbá ṣe pé kí ìwọ máa sàmì ẹ̀ṣẹ̀, Olúwa, tá ni ìbá dúró.
Nítorí ìdáríjì wà lọ́dọ̀ rẹ, kí a lè máa bẹ̀rù rẹ.
Èmi dúró de Olúwa, ọkàn mi dúró, àti nínú ọ̀rọ̀ rẹ ni èmi ń ṣe ìrètí.
Ọkàn mi dúró de Olúwa, ju àwọn tí ń ṣọ́nà òwúrọ̀ lọ, àní ju àwọn tí ń ṣọ́nà òwúrọ̀ lọ.
Israẹli, ìwọ ní ìrètí ní ti Olúwa: nítorí pé lọ́dọ̀ Olúwa ni àánú wà, àti lọ́dọ̀ rẹ̀ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdáǹdè wà.
Òun ó sì dá Israẹli ní ìdè kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ gbogbo.
Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi. Olúwa àyà mi kò gbéga, bẹ́ẹ̀ ni ojú mi kò gbé sókè: bẹ́ẹ̀ ni èmi kò fi ọwọ́ mi lé ọ̀ràn ńlá, tàbí lé ohun tí ó ga jù mí lọ.
Israẹli, ìwọ ní ìrètí ní ti Olúwa láti ìsinsin yìí lọ àti láéláé.
Orin fún ìgòkè. Olúwa, rántí Dafidi nínú gbogbo ìpọ́njú rẹ̀.
Ẹni tí ó ti búra fún Olúwa, tí ó sì ṣe ìlérí fún alágbára Jakọbu pé.
títí èmi ó fi rí ibi fún Olúwa, ibùjókòó fún alágbára Jakọbu.
Àwa ó lọ sínú àgọ́ rẹ̀: àwa ó máa sìn níbi àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀
Olúwa, dìde sí ibi ìsinmi rẹ: ìwọ, àti àpótí agbára rẹ.
Kí a fi òdodo wọ àwọn àlùfáà rẹ: kí àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ kí ó máa hó fún ayọ̀.
Nítorí tí Dafidi ìránṣẹ́ rẹ̀, má ṣe yí ojú ẹni òróró rẹ padà.
Olúwa ti búra nítòótọ́ fún Dafidi, Òun kì yóò yípadà kúrò nínú rẹ̀, nínú irú-ọmọ inú rẹ ni èmi ó gbé kalẹ̀ sí orí ìtẹ́ rẹ.
Bí àwọn ọmọ rẹ̀ yóò bá pa májẹ̀mú mi mọ́ àti ẹ̀rí mi tí èmi yóò kọ́ wọn, àwọn ọmọ wọn pẹ̀lú yóò jókòó lórí ìtẹ́ rẹ láéláé.
Nítorí tí Olúwa ti yan Sioni: ó ti fẹ́ ẹ fún ibùjókòó rẹ̀.
Èyí ni ibi ìsinmi mi láéláé: níhìn-ín ni èmi yóò máa gbé: nítorí tí mo fẹ́ ẹ.
Èmi yóò bùkún oúnjẹ rẹ̀ púpọ̀púpọ̀: èmi yóò fi oúnjẹ tẹ́ àwọn tálákà rẹ̀ lọ́rùn.
Èmi yóò sì fi ìgbàlà wọ àwọn àlùfáà rẹ̀: àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ yóò máa hó fún ayọ̀.
Níbẹ̀ ni èmi yóò gbé mú ìwo Dafidi yọ̀, èmi ti ṣe ìlànà fìtílà kan fún ẹni òróró mi.