God
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God
Òtítọ́ ni gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ; gbogbo òfin òdodo rẹ láéláé ni.
Àwọn alákòóso ṣe inúnibíni sí mi láìnídìí, ṣùgbọ́n ọkàn mi wárìrì sí ọ̀rọ̀ rẹ.
Èmi yọ̀ nínú ìpinnu rẹ bí ẹni tí ó rí ìkógun púpọ̀.
Èmi kórìíra mo sì kọ èké ṣíṣe ṣùgbọ́n mo fẹ́ràn òfin rẹ.
Èmi yìn ọ́ ní ìgbà méje lójúmọ́ nítorí òfin òdodo rẹ.
Àlàáfíà púpọ̀ wà fún àwọn tí ó ní ìfẹ́ sí òfin rẹ, kò sì ṣí ohun tí ó lè mú wọn kọsẹ̀.
Èmi yóò dúró de ìgbàlà rẹ, Olúwa, èmi yóò sì tẹ̀lé àṣẹ rẹ.
Èmi gba òfin rẹ gbọ́, nítorí mo fẹ́ràn wọn púpọ̀púpọ̀.
Èmi ṣe ìgbọ́ràn sí ẹ̀kọ́ rẹ àti òfin rẹ, nítorí ìwọ mọ gbogbo ọ̀nà mi.
Jẹ́ kí igbe mi wá sí iwájú rẹ, Olúwa; fún mi ní òye gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
Jẹ́ kí ẹ̀bẹ̀ mi wá sí iwájú rẹ; gbà mí gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ.
Ètè mi yóò sọ ìyìn jáde, nítorí ìwọ kọ́ mi ní ìlànà rẹ.
Jẹ́ kí ahọ́n mi kọ orin ọ̀rọ̀ rẹ, nítorí gbogbo àṣẹ rẹ jẹ́ òdodo.
Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ ṣetán láti ràn mí lọ́wọ́, nítorí èmi ti yan ẹ̀kọ́ rẹ.
Èmi wo ọ̀nà fún ìgbàlà rẹ, Olúwa, àti òfin rẹ jẹ́ dídùn inú mi.
Jẹ́ kí èmi wà láààyè ki èmi lè yìn ọ́, kí o sì jẹ́ kí òfin rẹ mú mi dúró.
Èmí ti ṣìnà bí àgùntàn tí ó sọnù. Wá ìránṣẹ́ rẹ, nítorí èmi kò gbàgbé àṣẹ rẹ.
Orin fún ìgòkè. Èmi ké pe Olúwa nínú ìpọ́njú mi, ó sì dá mi lóhùn.
Gbà mí, Olúwa, kúrò lọ́wọ́ ètè èké àti lọ́wọ́ ahọ́n ẹ̀tàn.
Ìrànlọ́wọ́ mi tí ọwọ́ Olúwa wá, ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé.
Òun kì yóò jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ kí ó yẹ̀; ẹni tí ó pa ọ́ mọ́ kì í tòògbé.
Kíyèsi, ẹni tí ń pa Israẹli mọ́, kì í tòògbé bẹ́ẹ̀ ni kì í sùn.
Olúwa ni olùpamọ́ rẹ; Olúwa ní òjìji rẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ.
Olúwa yóò pa ọ́ mọ́ kúrò nínú ibi gbogbo yóò pa ọkàn rẹ mọ́
Olúwa yóò pa àlọ àti ààbọ̀ rẹ mọ́ láti ìgbà yìí lọ àti títí láéláé.