Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. A pọ́n mi lójú gidigidi; Olúwa, sọ mi di ààyè, gẹ́gẹ́ bi ọ̀rọ̀ rẹ

  2. Olúwa, gba ìyìn àtinúwá ẹnu mi, kí o sì kọ́ mi ní òfin rẹ̀.

  3. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ayé mi wà ni ọwọ́ mi nígbà gbogbo, èmi kò ní gbàgbé òfin rẹ.

  4. Àwọn ẹni búburú ti dẹ okùn sílẹ̀ fún mi, ṣùgbọ́n èmi kò ṣìnà kúrò nínú ẹ̀kọ́ rẹ.

  5. Ọkàn mi ti lé pípa òfin rẹ mọ́ láé dé òpin.

  6. Èmi kórìíra àwọn ọlọ́kàn méjì, ṣùgbọ́n èmi fẹ́ òfin rẹ.

  7. Ìwọ ni ààbò mi àti asà mi; èmi ti mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ.

  8. Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin olùṣe búburú, kí èmi lè pa àṣẹ Ọlọ́run mi mọ́!

  9. Gbé mi sókè gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ, kí èmi kí ó lè yè Má sì jẹ́ kí ojú ìrètí mi kí ó tì mí.

  10. Gbé mi sókè, èmí yóò sì wa láìléwu; nígbà gbogbo ni èmi yóò máa júbà òfin rẹ.

  11. Ìwọ kọ gbogbo àwọn tí ó ṣìnà kúrò nínú òfin rẹ, nítorí ẹ̀tàn wọn asán ni.

  12. Gbogbo àwọn ẹni búburú ní ayé ni ìwọ yọ kúrò bí i ìdàrọ́; nítorí náà, èmi fẹ́ òfin rẹ̀.

  13. Ara mi wárìrì ní ìbẹ̀rù nítorí rẹ̀: èmi dúró ní ìbẹ̀rù òfin rẹ.

  14. Mú kí àlàáfíà ìránṣẹ́ rẹ dájú: má ṣe jẹ́ kí àwọn agbéraga ni mi lára.

  15. Ojú mi kùnà, fún wíwo ìgbàlà rẹ, fún wíwo ìpinnu òdodo rẹ.

  16. Ṣe pẹ̀lú ìránṣẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí dídúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ kí o sì kọ́ mi ní àṣẹ rẹ.

  17. Èmi ni ìránṣẹ́ rẹ; ẹ fún mi ní òye kí èmi lè ní òye òfin rẹ

  18. Ó tó àsìkò fún ọ láti ṣe iṣẹ́, Olúwa; nítorí òfin rẹ ti fọ́.

  19. Nítorí èmi fẹ́ràn àṣẹ rẹ ju wúrà, àní ju wúrà dídára lọ,

  20. nítorí èmi kíyèsi gbogbo ẹ̀kọ́ òtítọ́ rẹ̀, èmi kórìíra gbogbo ipa ọ̀nà búburú.

  21. Ìṣípayá ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú ìmọ́lẹ̀ wá; ó fi òye fún àwọn òpè.

  22. Èmi ya ẹnu mi mo sì mí hẹlẹ, nítorí èmi fojú ṣọ́nà sí àṣẹ rẹ.

  23. Yí padà sí mi kí o sì ṣàánú fún mi, bí ìwọ ṣe máa ń ṣe nígbà gbogbo sí àwọn tí ó fẹ́ràn orúkọ rẹ.

  24. Fi ìṣísẹ̀ mi múlẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ rẹ, má ṣe jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ borí mi.

  25. Rà mí padà lọ́wọ́ aninilára ènìyàn, kí èmi lè gbọ́ ẹ̀kọ́ rẹ.