God
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God
Àwọn ọ̀tá rẹ̀ ni èmi yóò fi ìtìjú wọ̀: ṣùgbọ́n lára òun tìkára rẹ̀ ni adé yóò máa gbilẹ̀.
Bí ìrì Hermoni tí o sàn sórí òkè Sioni. Nítorí níbẹ̀ ní Olúwa gbé pàṣẹ ìbùkún, àní ìyè láéláé.
Orin ìgòkè. Ẹ kíyèsi i, ẹ fi ìbùkún fún Olúwa, gbogbo ẹ̀yin ìránṣẹ́ Olúwa, tí ó dúró ní ilé Olúwa ní òru.
Ẹ gbé ọwọ́ yín sókè sí ibi mímọ́, kí ẹ sì fi ìbùkún fún Olúwa.
Olúwa tí ó dá ọ̀run òun ayé, kí ó bùsi i fún ọ láti Sioni wá.
Ẹ yin Olúwa. Ẹ yin orúkọ Olúwa; ẹ yìn ín, ẹ̀yin ìránṣẹ́ Olúwa.
Ẹ̀yin tí ń dúró ní ilé Olúwa, nínú àgbàlá ilé Ọlọ́run wa.
Ẹ yin Olúwa: nítorí tí Olúwa ṣeun; ẹ kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ̀; nítorí tí ó dùn.
Nítorí tí Olúwa ti yan Jakọbu fún ara rẹ̀; àní Israẹli fún ìṣúra ààyò rẹ̀.
Nítorí tí èmi mọ̀ pé Olúwa tóbi, àti pé Olúwa jù gbogbo òrìṣà lọ.
Olúwa ṣe ohunkóhun tí ó wù ú, ní ọ̀run àti ní ayé, ní Òkun àti ní ọ̀gbun gbogbo.
Ó mú ìkùùkuu gòkè láti òpin ilẹ̀ wá: ó dá mọ̀nàmọ́ná fún òjò: ó ń mú afẹ́fẹ́ ti inú ilẹ̀ ìṣúra rẹ̀ wá.
Ó sì fi ilẹ̀ wọn fún ni ní ìní, ìní fún Israẹli, ènìyàn rẹ̀.
Olúwa orúkọ rẹ dúró láéláé; ìrántí rẹ Olúwa, láti ìrandíran.
Nítorí tí Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀, yóò sì ṣe ìyọ́nú sí àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀.
Ẹ̀yin ara ilé Israẹli, ẹ fi ìbùkún fún Olúwa, ẹ̀yin ará ilé Aaroni, fi ìbùkún fún Olúwa.
Ẹ̀yin ará ilé Lefi, fi ìbùkún fún Olúwa; ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù Olúwa, fi ìbùkún fún Olúwa.
Olùbùkún ni Olúwa, láti Sioni wá, tí ń gbé Jerusalẹmu. Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí tí ó ṣeun; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run àwọn ọlọ́run: nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa àwọn olúwa, nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
Fún Òun nìkan tí ń ṣiṣẹ́ ìyanu ńlá; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
Fún ẹni tí ó fi ọgbọ́n dá ọ̀run; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
Fún ẹni tí ó tẹ́ ilẹ̀ lórí omi; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
Fún ẹni tí ó dá àwọn ìmọ́lẹ̀ ńlá; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.