God
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God
Nítòótọ́, wọn ó máa kọrin ní ipa ọ̀nà Olúwa; nítorí pé ńlá ni ògo Olúwa.
Bí Olúwa tilẹ̀ ga, síbẹ̀ ó júbà àwọn onírẹ̀lẹ̀; ṣùgbọ́n agbéraga ni ó mọ̀ ní òkèrè réré.
Bí èmi tilẹ̀ ń rìn nínú ìpọ́njú ìwọ ni yóò sọ mi di ààyè; ìwọ ó na ọwọ́ rẹ sí àwọn ọ̀tá mi, ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò sì gbà mí.
Olúwa yóò ṣe ohun tí ń ṣe tèmi láṣepé; Olúwa, àánú rẹ dúró láéláé; má ṣe kọ iṣẹ́ ọwọ́ ara rẹ sílẹ̀.
Fún adarí orin. Ti Dafidi. Saamu. Olúwa, ìwọ tí wádìí mi, ìwọ sì ti mọ̀ mí.
Ìwọ mọ̀ ìjókòó mi àti ìdìde mi, ìwọ mọ̀ èrò mi ní ọ̀nà jíjìn réré.
Nítorí tí kò sí ọ̀rọ̀ kan ní ahọ́n mi, kíyèsi i, Olúwa, ìwọ mọ̀ ọ́n pátápátá.
Ìwọ sé mi mọ́ lẹ́yìn àti níwájú, ìwọ sì fi ọwọ́ rẹ lé mi.
Níbo ní èmi yóò gbé lọ kúrò ni ọwọ́ ẹ̀mí rẹ? Tàbí níbo ni èmi yóò sáré kúrò níwájú rẹ?
Bí èmi bá gòkè lọ sí ọ̀run, ìwọ wà níbẹ̀; bí èmí ba sì tẹ́ ẹní mi ní ipò òkú, kíyèsi i, ìwọ wà níbẹ̀ pẹ̀lú.
àní, níbẹ̀ náà ni ọwọ́ rẹ̀ yóò fà mí ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò sì dì mímú.
Nítòótọ́ òkùnkùn kì í ṣú lọ́dọ̀ rẹ; ṣùgbọ́n òru tan ìmọ́lẹ̀ bí ọ̀sán; àti òkùnkùn àti ọ̀sán, méjèèjì bákan náà ní fún ọ.
Nítorí ìwọ ni ó dá ọkàn mi; ìwọ ni ó bò mí mọ́lẹ̀ nínú ìyá mi.
Èmi yóò yìn ọ, nítorí tẹ̀rù tẹ̀rù àti tìyanu tìyanu ní a dá mi; ìyanu ní iṣẹ́ rẹ; èyí nì ni ọkàn mi sì mọ̀ dájúdájú.
Ẹ̀dá ara mi kò pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ rẹ, nígbà tí a dá mi ní ìkọ̀kọ̀. Tí a sì ń ṣiṣẹ́ ní àràbarà ní ìhà ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ayé,
ojú rẹ ti rí ohun ara mi nígbà tí a kò tí ì ṣe mí pé, àti nínú ìwé rẹ ni a ti kọ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sí, ní ọjọ́ tí a dá wọn, nígbà tí wọn kò tilẹ̀ tí ì sí.
Ọlọ́run, èrò inú rẹ tí ṣe iyebíye tó fún mi, iye wọn ti pọ̀ tó!
Èmi ìbá kà wọ́n, wọ́n ju iyanrìn lọ ní iye: nígbà tí mo bá jí, èmi yóò wà lọ́dọ̀ rẹ síbẹ̀.
Ọlọ́run ìbá jẹ́ pa àwọn ènìyàn búburú nítòótọ́; nítorí náà kúrò lọ́dọ̀ mi ẹ̀yin ọkùnrin ẹlẹ́jẹ̀.
Ẹni tí ń fi inú búburú sọ̀rọ̀ sí ọ, àwọn ọ̀tá rẹ ń pe orúkọ rẹ ní asán!
Olúwa, ǹjẹ́ èmi kò kórìíra àwọn tó kórìíra rẹ? Ǹjẹ́ inú mi kò a sì bàjẹ́ sí àwọn tí ó dìde sí ọ?
Ọlọ́run, wádìí mi, kí o sì mọ ọkàn mí; dán mi wò, kí o sì mọ ìrò inú mi.
Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi. Olúwa, gbà mi lọ́wọ́ ọkùnrin búburú u nì, yọ mí lọ́wọ́ ọkùnrin ìkà a nì,
Olúwa, pa mí mọ́ kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú; yọ mí kúrò lọ́wọ́ ọkùnrin ìkà a nì ẹni tí ó ti pinnu rẹ̀ láti bi ìrìn mi ṣubú.
Èmi wí fún Olúwa pé ìwọ ni Ọlọ́run mi; Olúwa, gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.