Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Olúwa ti sọ létí Samuẹli ní ọjọ́ kan kí Saulu ó tó dé pé,

  2. “Ní ìwòyí ọ̀la, èmi yóò ran ọmọkùnrin kan sí ọ láti ilẹ̀ Benjamini. Fi òróró yàn án gẹ́gẹ́ bí olórí lórí àwọn ọmọ Israẹli, yóò gba àwọn ènìyàn mi kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Filistini. Mo ti bojú wo àwọn ènìyàn mi, nítorí igbe wọn ti dé ọ̀dọ̀ mi.”

  3. Nígbà tí Samuẹli fojúrí Saulu, Olúwa sọ fún un pé, “Èyí ni ọkùnrin tí mo sọ fún ọ nípa rẹ̀, yóò darí àwọn ènìyàn mi.”

  4. Bí wọ́n ti ń sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìpẹ̀kun ìlú náà, Samuẹli wí fún Saulu pé, “Sọ fún ìránṣẹ́ náà kí ó máa lọ ṣáájú u wa,” ìránṣẹ́ náà sì ṣe bẹ́ẹ̀, “Ṣùgbọ́n kí ìwọ kí ó dúró díẹ̀, kí èmi kí ó lè sọ ọrọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run fún ọ.”

  5. Samuẹli sì mú ìgò kékeré tí òróró wà nínú rẹ̀, ó sì dà á sí orí Saulu. Ó sì fi ẹnu kò ó ní ẹnu, wí pé, “Olúwa kò ha tí fi òróró yàn ọ ní olórí lórí ohun ìní rẹ̀?

  6. “Nígbà náà, ìwọ yóò lọ láti ibẹ̀ títí yóò fi dé ibi igi ńlá Tabori. Ọkùnrin mẹ́ta tí wọ́n ń gòkè lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run ní Beteli yóò pàdé rẹ níbẹ̀. Ọ̀kan yóò mú ọmọ ewúrẹ́ mẹ́ta lọ́wọ́, èkejì, ìṣù àkàrà mẹ́ta àti ẹ̀kẹta yóò mú ìgò wáìnì.

  7. “Lẹ́yìn náà, ìwọ yóò lọ sí òkè Ọlọ́run, níbi tí ẹgbẹ́ ogun àwọn Filistini wà. Bí ìwọ ti ń súnmọ́ ìlú náà, ìwọ yóò bá àwọn wòlíì tí ó tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ bọ̀ láti ibi gíga, pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn, tambori àti fèrè àti haapu níwájú wọn, wọn yóò sì máa sọ àsọtẹ́lẹ̀.

  8. Ẹ̀mí Olúwa yóò sì bà lé ọ, ìwọ yóò sì sọtẹ́lẹ̀ pẹ̀lú wọn, ìwọ yóò sì di ẹni ọ̀tọ̀.

  9. Bí ìwọ bá ti rí àmì wọ̀nyí, ṣe ohunkóhun tí ọwọ́ rẹ bá bà láti ṣe, nítorí Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ.

  10. Bí Saulu ti yípadà láti fi Samuẹli sílẹ̀, Ọlọ́run yí ọkàn Saulu padà àti pé gbogbo àmì wọ̀nyí sì wá sí ìmúṣẹ ní ọjọ́ náà.

  11. Nígbà tí wọ́n dé òkè Gibeah náà, àwọn wòlíì tí ó ń tò ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ pàdé rẹ̀, Ẹ̀mí Ọlọ́run bà lé e nínú agbára, ó sì darapọ̀ bá wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀.

  12. Samuẹli pé àwọn ọmọ Israẹli jọ sí iwájú Olúwa ní Mispa.

  13. Ó sì wí fún wọn pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli sọ, ‘Èmi mú Israẹli jáde wá láti Ejibiti, Èmi sì gbà yín kúrò lọ́wọ́ agbára Ejibiti àti gbogbo ìjọba tí ó ń pọ́n ọn yín lójú.’

  14. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti kọ Ọlọ́run yín, tí ó gbà yín kúrò nínú gbogbo wàhálà àti ìpọ́njú yín. Ẹ̀yin sì ti sọ pé, ‘Rárá, yan ọba kan fún wa.’ Báyìí, ẹ kó ara yín jọ níwájú Olúwa ní ẹ̀yà àti ìdílé yín.”

  15. bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ìwádìí lọ́wọ́ Olúwa pé, “Ṣé ọkùnrin náà ti wá sí bí ni?” Olúwa sì sọ pé, “Bẹ́ẹ̀ ni ó ti fi ara rẹ̀ pamọ́ láàrín àwọn ẹrù.”

  16. Samuẹli sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn pé, “Ṣé ẹ ti ri ọkùnrin tí Olúwa ti yàn? Kò sí ẹnìkan bí i rẹ̀ láàrín gbogbo àwọn ènìyàn.” Nígbà náà àwọn ènìyàn kígbe pé, “Kí ẹ̀mí ọba kí ó gùn!”

  17. Samuẹli ṣàlàyé fún àwọn ènìyàn àwọn ìlànà ìjọba. Ó kọ wọ́n sínú ìwé, ó sì fi lélẹ̀ níwájú Olúwa. Lẹ́yìn náà, Samuẹli tú àwọn ènìyàn ká olúkúlùkù sí ilé e rẹ̀.

  18. Saulu náà padà sí ilé e rẹ̀ ní Gibeah. Àwọn akọni ọkùnrin tí Ọlọ́run ti fi ọwọ́ tọ́ ọkàn wọ́n sì sìn ín.

  19. Nígbà tí Saulu sì gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn, Ẹ̀mí Ọlọ́run sì bà lé e pẹ̀lú agbára, inú rẹ̀ sì ru sókè.

  20. Ó sì mú màlúù méjì, ó gé wọn sí wẹ́wẹ́, ó sì rán ẹyẹẹyọ sí gbogbo Israẹli nípa ọwọ́ àwọn ìránṣẹ́ náà, ó ní i ẹ kéde pé, “Èyí ni a ó ṣe sí màlúù ẹnikẹ́ni tí kò bá tọ Saulu àti Samuẹli lẹ́yìn.” Nígbà náà ni ìbẹ̀rù Olúwa sì mú àwọn ènìyàn, wọ́n sì jáde bí ènìyàn kan ṣoṣo.

  21. Ṣùgbọ́n Saulu wí pé, “A kì yóò pa ẹnikẹ́ni lónìí, nítorí lónìí yìí ni Olúwa ṣiṣẹ́ ìgbàlà ní Israẹli.”

  22. Nítorí náà gbogbo ènìyàn lọ sí Gilgali, wọn sí fi Saulu jẹ ọba ní iwájú Olúwa. Níbẹ̀, ni wọn ti rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀ ní iwájú Olúwa, Saulu àti gbogbo Israẹli ṣe àjọyọ̀ ńlá.

  23. Èmi dúró níhìn-ín yìí, ẹ jẹ́rìí sí mi níwájú Olúwa àti níwájú ẹni àmì òróró rẹ̀. Màlúù ta ni mo gbà rí? Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ta ni mo gbà rí? Ta ni mo rẹ́ jẹ rí? Ọwọ́ ta ni mo ti gba owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ kan rí láti fi bo ara mi lójú? Bí mo bá ti ṣe nǹkan kan nínú ohun wọ̀nyí, èmi yóò sì san án padà fún yín.”

  24. Samuẹli sì wí fún wọn pé, “Olúwa ni ẹlẹ́rìí sí i yín, àti ẹni àmì òróró rẹ̀ ni ẹlẹ́rìí lónìí pé, ẹ̀yin kò rí ohunkóhun lọ́wọ́ mi.” Wọ́n sì sọ wí pé, “Òun ni ẹlẹ́rìí.”

  25. Nígbà náà ni Samuẹli wí fún àwọn ènìyàn náà pé, “Olúwa ni ó yan Mose àti Aaroni àti ti ó mú àwọn baba ńlá yín gòkè wá láti Ejibiti.