Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa sì gba Israẹli ní ọjọ́ náà, ìjà náà sì rékọjá sí Beti-Afeni.

  2. Nígbà náà ni ẹnìkan sì wí fún Saulu pé, “Wò ó, àwọn ènìyàn tí ń dẹ́ṣẹ̀ sí Olúwa nípa jíjẹ ẹran tí ó ní ẹ̀jẹ̀ lára.” Ó sì wí pé, “Ẹ̀ṣẹ̀ yín ti pọ̀jù, yí òkúta ńlá sí ibi nísinsin yìí.”

  3. Nígbà náà ni ó wí pé, “Ẹ jáde lọ sáàrín àwọn ènìyàn náà kí ẹ sì wí fún wọn pé, ‘Kí olúkúlùkù wọn mú màlúù àti àgùntàn tirẹ̀ tọ̀ mí wá, kí wọ́n sì pa wọ́n níhìn-ín, kí wọ́n sì jẹ́. Ẹ má ṣe ṣẹ̀ sí Olúwa, kí ẹ má ṣe jẹ ẹran tòun-tẹ̀jẹ̀.’ ” Bẹ́ẹ̀ ní olúkúlùkù mú màlúù tirẹ̀ wá ní alẹ́ ọjọ́ náà, wọ́n sì pa wọ́n níbẹ̀.

  4. Nígbà náà Saulu kọ́ pẹpẹ kan fún Olúwa; èyí sì jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ tí ó kọ́kọ́ ṣe èyí.

  5. Saulu sì wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a sọ̀kalẹ̀ tọ Filistini lọ ní òru, kí a bá wọn jà títí di ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀, kí a má ṣì ṣe dá ẹnìkankan sí nínú wọn.” Wọ́n sì wí pé, “Ṣe ohun tí ó bá dára ní ojú rẹ̀.” Ṣùgbọ́n àlùfáà wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a ṣe ìwádìí lọ́wọ́ Ọlọ́run níhìn-ín.”

  6. Nígbà náà ni Saulu béèrè lọ́dọ̀ Ọlọ́run pé, “Ṣé kí n sọ̀kalẹ̀ tọ àwọn Filistini lọ bí? Ǹjẹ́ ìwọ yóò fi wọ́n lé Israẹli lọ́wọ́ bí?” Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò dá a lóhùn ní ọjọ́ náà.

  7. Bí Olúwa tí ó gba Israẹli là ti wà, bí ó bá ṣe pé a rí í lára Jonatani ọmọ mi, ó ní láti kú.” Ṣùgbọ́n ẹnìkankan nínú wọn kò sọ ọ̀rọ̀ kan.

  8. Nígbà náà ni Saulu gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run Israẹli pé, “Fún mi ní ìdáhùn tí ó tọ́.” A sì mú Jonatani àti Saulu nípa ìbò dídì, àwọn ènìyàn náà sì yege.

  9. Saulu sì wí pé, “Kí Ọlọ́run kí ó ṣe bẹ́ẹ̀ àti jù bẹ́ẹ̀ lọ sí mi, nítorí pé ìwọ Jonatani yóò sá à kú dandan.”

  10. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn wí fún Saulu pé, “Ǹjẹ́ ó yẹ kí Jonatani kú, ẹni tí ó ti mú ìgbàlà ńlá yìí wá fún Israẹli? Kí a má rí í! Bí Olúwa ti wà, ọ̀kan nínú irun orí rẹ̀ kì yóò bọ́ sílẹ̀, nítorí tí ó ṣe èyí pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́.” Báyìí ni àwọn ènìyàn gba Jonatani sílẹ̀, kò sì kú.

  11. Samuẹli wí fún Saulu pé, “Èmi ni Olúwa rán láti fi àmì òróró yàn ọ́ ní ọba lórí àwọn ènìyàn rẹ̀ Israẹli; fetísílẹ̀ láti gbọ́ iṣẹ́ tí Olúwa rán mi sí ọ́.

  12. Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, ‘Èmi yóò jẹ àwọn Amaleki ní yà fún ohun tí wọ́n ti ṣe sí Israẹli nígbà tí wọn dè wọn lọ́nà nígbà tí wọn ń bọ̀ láti Ejibiti.

  13. Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Samuẹli wá pé,

  14. “Èmi káàánú gidigidi pé mo fi Saulu jẹ ọba, nítorí pé ó ti yípadà kúrò lẹ́yìn mi, kò sì pa ọ̀rọ̀ mi mọ́.” Inú Samuẹli sì bàjẹ́ gidigidi, ó sì ké pe Olúwa ní gbogbo òru náà.

  15. Nígbà tí Samuẹli sì dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, Saulu sì wí fún un pé, “Olúwa bùkún fún ọ, mo ti ṣe ohun tí Olúwa pàṣẹ.”

  16. Saulu sì dáhùn pé, “Àwọn ọmọ-ogun ní o mú wọn láti Amaleki wá, wọ́n dá àwọn àgùntàn, àti màlúù tí ó dára jùlọ sí láti fi rú ẹbọ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ, ṣùgbọ́n a pa àwọn tókù run pátápátá.”

  17. Samuẹli sí wí fún Saulu pé, “Dákẹ́ ná, jẹ́ kí èmi kí ó sọ ohun tí Olúwa wí fún mi ní alẹ́ àná fún ọ.” Saulu sì wí pé, “Sọ fún mi.”

  18. Samuẹli sì wí pé, “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ fi ìgbà kan kéré lójú ara rẹ, ǹjẹ́ ìwọ kò ha di olórí ẹ̀yà Israẹli? Olúwa fi àmì òróró yàn ọ́ ní ọba lórí Israẹli.

  19. Olúwa sì rán ọ níṣẹ́ wí pé, ‘Lọ, kí o sì pa àwọn ènìyàn búburú ará Amaleki run pátápátá; gbóguntì wọ́n títí ìwọ yóò fi run wọ́n.’

  20. Èéṣe tí ìwọ kò fi gbọ́ ti Olúwa? Èéṣe tí ìwọ fi sáré sí ìkógun tí o sì ṣe búburú níwájú Olúwa?”

  21. Saulu sì wí fún Samuẹli pé, “Ṣùgbọ́n èmi ti ṣe ìgbọ́ràn sí Olúwa, èmi sì ti lọ ní ọ̀nà tí Olúwa rán mi. Mo sì ti pa àwọn ará Amaleki run pátápátá, mo sì ti mú Agagi ọba wọn padà wá.

  22. Àwọn ọmọ-ogun ti mú àgùntàn àti màlúù lára ìkógun èyí tí ó dára láti fi fún Olúwa láti fi rú ẹbọ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ ní Gilgali.”

  23. Ṣùgbọ́n Samuẹli dáhùn pé, “Olúwa ha ní inú dídùn sí ẹbọ sísun àti ẹbọ ju kí a gba ohùn Olúwa gbọ́? Ìgbọ́ràn sàn ju ẹbọ lọ, ìfetísílẹ̀ sì sàn ju ọ̀rá àgbò lọ.

  24. Nítorí pé ìṣọ̀tẹ̀ dàbí ẹ̀ṣẹ̀ àfọ̀ṣẹ, àti ìgbéraga bí ẹ̀ṣẹ̀ ìbọ̀rìṣà. Nítorí tí ìwọ ti kọ ọ̀rọ̀ Olúwa, Òun sì ti kọ̀ ọ́ ní ọba.”

  25. Nígbà náà ni Saulu wí fún Samuẹli pé, “Èmi ti ṣẹ̀. Mo ti rú òfin Olúwa àti ọ̀rọ̀ rẹ̀. Èmi sì bẹ̀rù àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ni èmi sì gba ohùn wọn gbọ́.