Fò sí àkóónú

Esther

46 ẹsẹ · 1 ọmọ ẹbí

A tún mọ̀ ọ́n sí: Hadassah

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Esther

  1. Esteri sì dáhùn, “Ẹ̀bẹ̀ mi àti ìbéèrè mi ni èyí.

  2. Hamani tún fi kún un pé, “Kì í ṣe èyí nìkan. Èmi nìkan ni ayaba Esteri pè láti sin ọba wá sí ibi àsè tí ó sè. Bákan náà, ó sì tún ti pè mí pẹ̀lú ọba ní ọ̀la.

  3. Bí wọ́n ṣe ń bá a sọ̀rọ̀, àwọn ìwẹ̀fà ọba wọlé, wọ́n sì kán Hamani lójú láti lọ sí ibi àsè tí Esteri ti pèsè.

  4. Ọba àti Hamani sì lọ sí àpèjẹ pẹ̀lú Esteri ayaba,

  5. bí wọ́n sì ṣe ń mu wáìnì ní ọjọ́ kejì yìí, ọba sì tún béèrè pé, “Esteri ayaba, kí ni ẹ̀bẹ̀ rẹ? A ó sì fi fún ọ. Kí ni ìbéèrè rẹ? Bí ó tilẹ̀ jẹ́ ìdajì ìjọba à mi, n ó fi fún ọ.”

  6. Nígbà náà ni ayaba Esteri dáhùn, “Bí èmi bá rí ojúrere rẹ, ìwọ ọba, bí ó bá sì tẹ́ ọláńlá à rẹ lọ́rùn, fún mi ní ẹ̀mí mi, èyí ni ẹ̀bẹ̀ mi. Kí o sì pa àwọn ènìyàn mi mọ́—èyí ni ìbéèrè mi.

  7. Ọba Ahaswerusi bi Esteri ayaba léèrè pé, “Ta a ni ẹni náà? Níbo ni ẹni náà wà tí kò bẹ̀rù láti ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀?”

  8. Esteri sọ wí pé, “Alátakò àti ọ̀tá náà ni Hamani aláìníláárí yìí.” Nígbà náà ni Hamani wárìrì níwájú ọba àti ayaba.

  9. Ọba sì dìde pẹ̀lú ìbínú, ó fi wáìnì sílẹ̀ ó sì jáde lọ sí àgbàlá ààfin. Ṣùgbọ́n nígbà tí Hamani, ti rí i dájú pé ọba ti pinnu láti pa òun, ó dúró lẹ́yìn láti bẹ Esteri ayaba nítorí ẹ̀mí rẹ̀.

  10. Bí ọba ṣe padà dé láti àgbàlá ààfin wá sí gbọ̀ngàn àsè náà, Hamani ṣubú sórí àga tí Esteri ayaba fẹ̀yìn tì. Ọba sì pariwo pé, “Yóò ha tún tẹ́ ayaba níbí yìí, nínú ilé, ní ojú mi bí?” Ní kété tí ọba sọ ọ̀rọ̀ yìí jáde, wọ́n da aṣọ bo Hamani lójú.

  11. Ní ọjọ́ kan náà ni ọba Ahaswerusi fún Esteri ayaba ní ilé e Hamani, ọ̀tá àwọn Júù. Mordekai sì wá síwájú ọba, nítorí Esteri ti sọ bí ó ṣe jẹ́ sí ọba.

  12. Ọba sì bọ́ òrùka dídán an rẹ̀, èyí tí ó ti gbà lọ́wọ́ Hamani ó sì fi fún Mordekai, Esteri sì yàn án gẹ́gẹ́ bí olórí ilé e Hamani.

  13. Esteri sì tún bẹ ọba lórí ìkúnlẹ̀, pẹ̀lú omijé lójú. Ó bẹ̀ ẹ́ kí ó fi òpin sí ètò búburú Hamani ará Agagi, èyí tí ó ti pète fún àwọn Júù.

  14. Nígbà náà ni ọba na ọ̀pá aládé wúrà sí Esteri ó sì dìde, ó dúró níwájú rẹ̀.

  15. Ọba Ahaswerusi dá Esteri ayaba àti Mordekai ará a Júù náà lóhùn pé, “Nítorí Hamani kọlu àwọn ará a Júù, èmi ti fi ilé e rẹ̀ fún Esteri, wọ́n sì ti ṣo ó kọ́ sórí igi.

  16. Ọba sì sọ fún Esteri ayaba pé, “Àwọn Júù ti pa ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) ọkùnrin àti àwọn ọmọkùnrin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí i ṣe ọmọ Hamani ní ilé ìṣọ́ Susa run. Kí ni wọ́n ṣe ní gbogbo ìgbèríko ọba tókù? Báyìí kí ni ẹ̀bẹ̀ rẹ? A ó fi fún ọ. Kí ni ìbéèrè rẹ? A ó sì tún fi fún ọ.”

  17. Esteri sì dáhùn pé, “Bí ó bá tẹ́ ọba lọ́rùn, fún àwọn Júù tí ó wà ní Susa ní àṣẹ láti ṣe gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe ní òní kí wọn ṣe bákan náà ní ọ̀la, kí a sì so àwọn ọmọkùnrin Hamani mẹ́wẹ̀ẹ̀wá náà rọ̀ sórí igi.”

  18. Ṣùgbọ́n nígbà tí Esteri sọ nípa ìṣọ̀tẹ̀ náà fún ọba, ó kọ̀wé àṣẹ kan jáde pé kí ète búburú tí Hamani ti pa sí àwọn Júù kí ó padà sí orí òun fúnra rẹ̀, àti pé kí a gbé òun àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ kọ́ sórí igi.

  19. Bẹ́ẹ̀ ni Esteri ayaba, ọmọbìnrin Abihaili, pẹ̀lú Mordekai ará a Júù, kọ̀wé pẹ̀lú àṣẹ láti fi ìdí ìwé kejì nípa Purimu yìí múlẹ̀.

  20. Láti fi ìdí àwọn ọjọ́ ọ Purimu yìí múlẹ̀ ní àkókò tí wọ́n yàn, gẹ́gẹ́ bí Mordekai ará Juda, àti Esteri ayaba ti pa á láṣẹ fún wọn, àti bí wọ́n ṣe fi lélẹ̀ fún ara wọn àti irú àwọn ọmọ wọn ní ìbámu pẹ̀lú àkókò àwẹ̀ àti ẹkún wọn.

  21. Àṣẹ Esteri sì fi ìdí ìlànà Purimu wọ̀nyí múlẹ̀, a sì kọ ọ́ sínú ìwé àkọsílẹ̀.