- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Or Lots, the Feast of Purim
Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì
Ní ọdún kejìlá ọba Ahaswerusi, ní oṣù kìn-ín-ní, èyí ni oṣù Nisani, wọ́n da puri (èyí tí í ṣe, ìbò) ní iwájú Hamani láti yan ọjọ́ kan àti oṣù, ìbò náà sì wáyé ní oṣù kejìlá, oṣù Addari.
Nígbà náà ni Hamani sọ fún ọba Ahaswerusi pé, “Àwọn ènìyàn kan wà tí wọ́n fọ́nká tí wọ́n sì túká ní ara àwọn ènìyàn ní gbogbo àgbáyé ìjọba rẹ̀ tí ìṣe wọn yàtọ̀ sí ti gbogbo àwọn tókù tí wọn kò sì pa òfin ọba mọ́; èyí kì í ṣe ìfẹ́ ọba láti gbà fún wọn bẹ́ẹ̀.
Tí ó bá tẹ́ ọba lọ́rùn, kí a gbé òfin kan jáde tí yóò pa wọ́n run, èmi yóò sì fi ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) tálẹ́ǹtì fàdákà sínú ìṣúra ọba fún àwọn ọkùnrin tí wọn o ṣe iṣẹ́ náà.”
Nítorí náà, ọba sì bọ́ òrùka èdìdì tí ó wà ní ìka rẹ̀, ó sì fi fún Hamani ọmọ Hammedata, ará Agagi, ọ̀tá àwọn Júù.
Ọba sọ fún Hamani pé, “Pa owó náà mọ́, kí o sì ṣe ohun tí ó wù ọ́ fún àwọn ènìyàn náà.”
Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹtàlá oṣù kìn-ín-ní àkọ́kọ́, wọ́n pe àwọn akọ̀wé ọba jọ. Wọ́n kọ ọ́ ní ìlànà bí ìgbèríko kọ̀ọ̀kan ṣe ń kọ̀wé, ó kọ̀wé sí àwọn ènìyàn kọ̀ọ̀kan ní èdè wọn gbogbo èyí tí Hamani ti pàṣẹ sí àwọn akọ̀wé ọba, sí baálẹ̀ ìgbèríko kọ̀ọ̀kan àti àwọn ọlọ́lá àwọn onírúurú ènìyàn. A kọ èyí ní orúkọ ọba Ahaswerusi fúnra rẹ̀ ó sì fi òrùka ọba ṣe èdìdì i rẹ̀.
A sì fi ìwé náà ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn ìgbèríko ọba pẹ̀lú àṣẹ láti parun, láti pa gbogbo àwọn Júù èwe àti àgbà, obìnrin àti àwọn ọmọ wẹ́wẹ́—ní ọjọ́ kan kí wọn sì parẹ́, ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kejìlá, oṣù Addari kí a sì kó àwọn ohun ìní wọn.
Kí ẹ mú àdàkọ ìwé náà kí a tẹ̀ ẹ́ jáde bí òfin ní gbogbo ìgbèríko kí ó sì di mí mọ̀ fún àwọn ènìyàn ìlú nítorí kí wọ́n le múra fún ọjọ́ náà.
Àwọn ìránṣẹ́ náà sì jáde, wọ́n tẹ̀síwájú nípa àṣẹ ọba, ìkéde náà sì jáde ní ilé ìṣọ́ ti Susa. Ọba àti Hamani jókòó wọ́n ń mu, ṣùgbọ́n ìlú Susa wà nínú ìdààmú.
Èyí ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù Addari, wọ́n sì sinmi ní ọjọ́ kẹrìnlá, wọ́n sì ṣe ọjọ́ náà ní ọjọ́ àsè àti ayọ̀.
Àwọn Júù tí ó wà ní Susa, kó ara wọn jọ ní ọjọ́ kẹtàlá àti ọjọ́ kẹrìnlá, nígbà tí ó sì di ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún wọ́n sinmi wọ́n sì ṣe ọjọ́ náà ní ọjọ́ àsè àti ayọ̀.
Nítorí náà ni àwọn Júù tí wọ́n ń gbé ní ìletò ṣe pa ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Addari mọ́ gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ ayọ̀ àti ọjọ́ àsè, ọjọ́ tí wọ́n ń fún ara wọn ní ẹ̀bùn.
Nítorí Hamani ọmọ Hammedata, ará Agagi, ọ̀tá gbogbo àwọn Júù, ti gbèrò sí àwọn Júù láti pa wọ́n run, ó sì ti di puri (èyí tí í ṣe ìbò) fún ìsọdahoro àti ìparun wọn.
Ṣùgbọ́n nígbà tí Esteri sọ nípa ìṣọ̀tẹ̀ náà fún ọba, ó kọ̀wé àṣẹ kan jáde pé kí ète búburú tí Hamani ti pa sí àwọn Júù kí ó padà sí orí òun fúnra rẹ̀, àti pé kí a gbé òun àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ kọ́ sórí igi.
(Nítorí náà a pe àwọn ọjọ́ wọ̀nyí ní Purimu, láti ara ọ̀rọ̀ puri). Nítorí ohun gbogbo tí a kọ sínú ìwé yìí àti nítorí ohun tí wọ́n ti rí àti ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí wọn,
Bẹ́ẹ̀ ni Esteri ayaba, ọmọbìnrin Abihaili, pẹ̀lú Mordekai ará a Júù, kọ̀wé pẹ̀lú àṣẹ láti fi ìdí ìwé kejì nípa Purimu yìí múlẹ̀.
Mordekai sì kọ ìwé ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn Júù, sí ìgbèríko mẹ́tàdínláàádóje (127) ní ilẹ̀ ọba Ahaswerusi ní ọ̀rọ̀ àlàáfíà àti òtítọ́.
Láti fi ìdí àwọn ọjọ́ ọ Purimu yìí múlẹ̀ ní àkókò tí wọ́n yàn, gẹ́gẹ́ bí Mordekai ará Juda, àti Esteri ayaba ti pa á láṣẹ fún wọn, àti bí wọ́n ṣe fi lélẹ̀ fún ara wọn àti irú àwọn ọmọ wọn ní ìbámu pẹ̀lú àkókò àwẹ̀ àti ẹkún wọn.
Àṣẹ Esteri sì fi ìdí ìlànà Purimu wọ̀nyí múlẹ̀, a sì kọ ọ́ sínú ìwé àkọsílẹ̀.