Fò sí àkóónú

David

968 ẹsẹ · 40 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan David

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí èmi ti yan Jerusalẹmu, kí orúkọ mi le è wà níbẹ̀, èmi sì ti yan Dafidi láti jẹ ọba lórí Israẹli ènìyàn mi.’

  2. “Baba mi Dafidi ti ní-in lọ́kàn láti kọ́ tẹmpili fún orúkọ Olúwa, àní Ọlọ́run Israẹli.

  3. Ṣùgbọ́n Olúwa sọ fún Dafidi baba mi pé, ‘Nítorí tí ó wà ní ọkàn rẹ láti kọ́ tẹmpili yìí fún orúkọ mi, ìwọ ṣe ohun dáradára láti ní èyí ní ọkàn rẹ̀.

  4. “Olúwa sì ti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Èmi ti dìde ní ipò Dafidi baba mi, a sì gbé mi ka ìtẹ́ Israẹli, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti ṣe ìlérí, èmi sì ti kọ́ tẹmpili fún orúkọ Olúwa, Ọlọ́run Israẹli.

  5. Ìwọ tí o pa ìlérí tí o ṣe pẹ̀lú ìránṣẹ́ rẹ Dafidi baba mi mọ́; nítorí ìwọ ti fi ẹnu rẹ ṣe ìlérí àti pé ìwọ ti fi ọwọ́ rẹ mú un ṣẹ; bí ó ti rí lónìí yìí.

  6. “Nísinsin yìí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, pa ìlérí tí ó ti ṣe mọ́ fún ìránṣẹ́ rẹ Dafidi baba mi nígbà tí o wí pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ fẹ́ kù láti ní ọkùnrin láti jókòó níwájú mi lórí ìtẹ́ Israẹli, kìkì bí àwọn ọmọ rẹ tí wọ́n bá kíyèsi ara nínú gbogbo ohun tí wọ́n ṣe láti rìn níwájú mi gẹ́gẹ́ bí òfin mi gẹ́gẹ́ bí o sì ti ṣe.’

  7. Nísinsin yìí, Olúwa Ọlọ́run Israẹli, jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ tí o ti ṣèlérí fún ìránṣẹ́ rẹ Dafidi kí ó wá sí ìmúṣẹ.

  8. Olúwa Ọlọ́run mi, má ṣe kọ̀ ẹni àmì òróró rẹ.

  9. Àwọn àlùfáà dúró ní ààyè wọn, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Lefi ti ṣe pẹ̀lú ohun èlò orin Olúwa, tí ọba Dafidi ti ṣe fún ìyìn Olúwa àti tí á lò nígbà tí ó dúpẹ́, wí pé, “Àánú rẹ̀ sì dúró láéláé,” níwájú àwọn ọmọ Lefi, àwọn àlùfáà sì fọn ìpè, gbogbo àwọn ọmọ Israẹli sì dúró.

  10. Ní ọjọ́ kẹtàlélógún tí oṣù keje, ó sì rán àwọn ènìyàn padà sí ilé wọn, pẹ̀lú ayọ̀ àti ìdùnnú nínú wọn fún ohun rere tí Olúwa ti ṣe fún Dafidi àti Solomoni, àti fún àwọn ènìyàn Israẹli.

  11. “Ní ti bí ìwọ bá rìn níwájú mi gẹ́gẹ́ bí Dafidi baba rẹ ti ṣe, tí o sì ṣe gbogbo ohun tí mo paláṣẹ, tí ìwọ sì ṣe àkíyèsí àṣẹ mi láti ọ̀run,

  12. Èmi yóò fi ìdí ìtẹ́ ìjọba rẹ múlẹ̀, gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe pẹ̀lú Dafidi baba rẹ nígbà tí mo bá a dá májẹ̀mú wí pé, ìwọ kò ní fẹ́ ẹnìkan kù láti ṣe alákòóso lórí Israẹli.

  13. Solomoni gbé ọmọbìnrin Farao sókè láti ìlú Dafidi lọ sí ibi tí ó ti kọ́ fún un, nítorí ó wí pé, “Aya mi kò gbọdọ̀ gbé nínú ilé Dafidi ọba Israẹli nítorí ibi tí àpótí ẹ̀rí Olúwa bá tí wọ̀, ibi mímọ́ ni.”

  14. Ní pípamọ́ pẹ̀lú ìlànà baba rẹ̀ Dafidi, ó sì yan ipa àwọn àlùfáà fún iṣẹ́ wọn àti àwọn ọmọ Lefi láti jẹ́ adarí láti máa yin àti láti máa ṣe ìránṣẹ́ àwọn àlùfáà gẹ́gẹ́ bí ìlànà ojoojúmọ́. Ó sì tún yàn àwọn olùṣọ́nà nípa pípín sí olúkúlùkù ẹnu-ọ̀nà, nítorí èyí ni Dafidi ènìyàn Ọlọ́run ti paláṣẹ.

  15. Solomoni sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín ní ìlú Dafidi baba rẹ̀, Rehoboamu, ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

  16. Nígbà tí gbogbo Israẹli rí i wí pé ọba kọ̀ láti gbọ́ tiwọn, wọ́n sì dá ọba lóhùn wí pé, “Ìpín kí ní a ní nínú Dafidi, ìní wo ni a ní nínú ọmọ Jese? Ẹ lọ sí àgọ́ yín, ẹ̀yin Israẹli! Bojútó ilé rẹ, ìwọ Dafidi!” Bẹ́ẹ̀ ní gbogbo àwọn ọmọ Israẹli lọ sí ilé wọn.

  17. Bẹ́ẹ̀ ni Israẹli sì wà ní ìṣọ̀tẹ̀ lórí ilé Dafidi títí fi di òní yìí.

  18. Ó fún ìjọba Juda ní agbára, ó sì ti Rehoboamu ọmọ Solomoni lẹ́yìn fún ọdún mẹ́ta nítorí ọdún mẹ́ta ni wọ́n fi rìn ní ọ̀nà ti Dafidi àti Solomoni ní àkókò yí.

  19. Rehoboamu fẹ́ Mahalati tí ó jẹ́ ọmọbìnrin ti ọmọkùnrin Dafidi Jerimoti bi àti ti Abihaili, ọmọbìnrin ti ọmọkùnrin Jese Eliabu bí.

  20. Rehoboamu sun pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ a sin ín sínú ìlú ńlá ti Dafidi. Abijah ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.

  21. Ṣé ẹ̀yin kò mọ̀ pé Olúwa Ọlọ́run Israẹli ti fún Dafidi àti àwọn àtẹ̀lé rẹ̀ ni oyè ọba títí láé nípasẹ̀ májẹ̀mú iyọ̀?

  22. Síbẹ̀ Jeroboamu ọmọ Nebati, oníṣẹ́ Solomoni ọmọ Dafidi, ṣọ̀tẹ̀ sí ọ̀gá rẹ̀.

  23. “Nísinsin yìí, ìwọ ṣètò láti kọ́ ìjọba Olúwa, tí ó wà lọ́wọ́ àwọn àtẹ̀lé Dafidi. Ìwọ jẹ́ ọmọ-ogun tí ó gbilẹ̀, ìwọ sì ní pẹ̀lú rẹ ẹgbọrọ màlúù wúrà ti Jeroboamu dà láti fi ṣe Ọlọ́run yín.

  24. Abijah sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín ní ìlú Dafidi. Asa ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. Ní àwọn ọjọ́ rẹ̀, orílẹ̀-èdè wà ní àlàáfíà fún ọdún mẹ́wàá.

  25. wọ́n sì sin ín sínú isà òkú tí ó ti gbẹ́ jáde fún ara rẹ̀ ní ìlú Dafidi. Wọ́n sì tẹ sí orí àkéte tí ó fi òórùn dídùn kún, àti onírúurú tùràrí tí a fi ọgbọ́n pèsè, wọ́n sì da iná ńlá nítorí rẹ̀.