Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Vision: Peter, James, and John, of the transfiguration of Jesus and the appearance of Moses and Elijah
Àwọn ẹsẹ nípa Peter, James, and John, of the transfiguration of Jesus and the appearance of Moses and Elijah
Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́fà, Jesu mú Peteru, Jakọbu àti Johanu arákùnrin rẹ̀, ó mú wọn lọ sí orí òkè gíga kan tí ó dádúró.
Níbẹ̀ ara rẹ̀ yí padà níwájú wọn. Ojú rẹ̀ sì ràn bí oòrùn, aṣọ rẹ̀ sì funfun bí ìmọ́lẹ̀.
Lójijì, Mose àti Elijah fi ara hàn, wọ́n sì ń bá Jesu sọ̀rọ̀.
Peteru sọ fún Jesu pé, “Olúwa, jẹ́ kí a kúkú máa gbé níhìn-ín yìí. Bí ìwọ bá fẹ́, èmi yóò pa àgọ́ mẹ́ta, ọ̀kan fún ọ, ọ̀kan fún Mose, àti ọ̀kan fún Elijah.”
Bí Peteru ti sọ̀rọ̀ tán, àwọsánmọ̀ dídán síji bò wọ́n, láti inú rẹ̀ ohùn kan wí pé, “Èyí ni àyànfẹ́ ọmọ mi, ẹni ti inú mi dùn sí gidigidi. Ẹ máa gbọ́ tirẹ̀!”
Bí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ti gbọ́ èyí, wọ́n dojúbolẹ̀. Ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi.
Ṣùgbọ́n Jesu sì tọ̀ wọ́n wá. Ó fi ọwọ́ kàn wọ́n, ó wí pé, “Ẹ dìde, ẹ má ṣe bẹ̀rù.”
Nígbà tí wọ́n sì gbé ojú wọn sókè, tí wọ́n sì wò ó, Jesu nìkan ni wọn rí.
Bí wọ́n sì ti ń sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, Jesu pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ kò gbọdọ̀ sọ fún ẹnikẹ́ni ohun tí ẹ rí, títí Ọmọ Ènìyàn yóò fi jí dìde kúrò nínú òkú.”
Ó sì ṣe bí ìwọ̀n ọjọ́ mẹ́jọ lẹ́yìn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó mú Peteru àti Johanu àti Jakọbu, ó gun orí òkè lọ láti lọ gbàdúrà.
Bí ó sì ti ń gbàdúrà, àwọ̀ ojú rẹ̀ yípadà, aṣọ rẹ̀ sì funfun gbòò,
Sì kíyèsi i, àwọn ọkùnrin méjì, Mose àti Elijah, wọ́n ń bá a sọ̀rọ̀,
tí wọ́n fi ara hàn nínú ògo, wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ ikú rẹ̀, tí òun yóò ṣe parí ní Jerusalẹmu.
Ṣùgbọ́n ojú Peteru àti ti àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ wúwo fún oorun. Nígbà tí wọ́n sì tají, wọ́n rí ògo rẹ̀, àti ti àwọn ọkùnrin méjèèjì tí ó bá a dúró.
Ó sì ṣe, nígbà tí wọ́n lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, Peteru wí fún Jesu pé, “Olùkọ́, ó dára fún wa kí a máa gbé ìhín yìí, jẹ́ kí àwa pa àgọ́ mẹ́ta, ọ̀kan fún ìwọ, àti ọ̀kan fún Mose, àti ọ̀kan fún Elijah.” (Kò mọ èyí tí òun ń wí.)
Bí ó ti ń sọ báyìí, ìkùùkuu kan wá, ó síji bò wọ́n: ẹ̀rù sì bà wọ́n nígbà tí wọ́n ń wọ inú ìkùùkuu lọ.
Ohùn kan sì ti inú ìkùùkuu wá wí pé, “Èyí yìí ni àyànfẹ́ ọmọ mi: ẹ máa gbọ́ tirẹ̀.”
Nígbà tí ohùn náà sì dákẹ́, Jesu nìkan ṣoṣo ni a rí. Wọ́n sì pa á mọ́, wọn kò sì sọ ohunkóhun tí wọ́n rí fún ẹnikẹ́ni ní ọjọ́ wọ̀nyí.