Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Vision: Of Joshua, of the captain of the Lord's host
Àwọn ẹsẹ nípa Of Joshua, of the captain of the Lord's host
Nígbà tí Joṣua súnmọ́ Jeriko, ó wo òkè ó sì rí ọkùnrin kan tí ó dúró ní iwájú rẹ̀ pẹ̀lú idà ní ọwọ́ rẹ̀. Joṣua sì tọ̀ ọ́ lọ, ó sì bi í pé, “Ǹjẹ́ ìwọ wà fún wa tàbí fún ọ̀tá a wa?”
“Kì í ṣe fún èyíkéyìí ó fèsì, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí olórí ogun Olúwa ni mo wá nísinsin yìí.” Nígbà náà ni Joṣua sì wólẹ̀ ní iwájú u rẹ̀ ní ìbẹ̀rù, ó sì bi í léèrè, “Kí ni Olúwa ní í sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀?”
Olórí ogun Olúwa sì dá a lóhùn pé, “Bọ́ sálúbàtà rẹ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ, nítorí pé ibi tí ìwọ dúró sí yìí, ilẹ̀ mímọ́ ni.” Joṣua sì ṣe bẹ́ẹ̀.