Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Vision: Of the Israelites, of the manifestation of the glory of God

6 ẹsẹ · 17 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Of the Israelites, of the manifestation of the glory of God

  1. Wọ́n sì rí Ọlọ́run Israẹli. Ní abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀ ni ohun kan bí i pèpéle ti a fi òkúta safire ṣe wà. Èyí ti ó mọ́ nigínnigín bí àwọ̀ sánmọ̀ fúnra rẹ̀.

  2. Ni ojú àwọn ọmọ Israẹli ògo Olúwa náà dàbí iná ajónirun ni orí òkè.

  3. Nítorí ẹ̀yin kò wá òkè tí a lè fi ọwọ́ kàn, àti ti iná ti ń jó, àti ti ìṣúdudu àti òkùnkùn, àti ìjì.

  4. Àti ìró ìpè, àti ohùn ọ̀rọ̀, èyí tí àwọn tí o gbọ́ bẹ̀bẹ̀ pé, kí a má ṣe sọ ọ̀rọ̀ sí i fún wọn mọ́,

  5. nítorí pé wọn kò lè gba ohun tí ó paláṣẹ, “Bí o tilẹ̀ jẹ ẹranko ni ó fi ara kan òkè náà, a ó sọ ọ́ ni òkúta.”

  6. Ìran náà sì lẹ́rù to bẹ́ẹ̀ tí Mose wí pé, “Ẹ̀rù ba mi gidigidi mo sì wárìrì.”