Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Vanity

88 ẹsẹ · 60 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Asán ni fún ẹ̀yin ti ẹ dìde ní kùtùkùtù láti pẹ́ dùbúlẹ̀, láti jẹ oúnjẹ làálàá; bẹ́ẹ̀ ni ó ń fi ìre fún olùfẹ́ rẹ̀ lójú ọ̀run.

  2. Ènìyàn rí bí èmi; ọjọ́ rẹ̀ rí bí òjìji tí ń kọjá lọ.

  3. Ìṣúra tí a kójọ nípa ìwà búburú kò ní èrè, ṣùgbọ́n òdodo a máa gbani lọ́wọ́ ikú.

  4. Ẹni tí ó bá dá oko yóò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ, ṣùgbọ́n ẹni tí ń lépa òjìji lásán làsàn kò gbọ́n.

  5. Owó tí a fi ọ̀nà èrú kójọ yóò ṣí lọ, ṣùgbọ́n ẹni tí ń kó owó jọ díẹ̀díẹ̀ yóò pọ̀ sí i.

  6. Ìṣúra tí a kójọ nípasẹ̀ ahọ́n tí ń parọ́ jẹ́ ìrì lásán àti ìkẹ́kùn ikú.

  7. Ẹni tí ó bá fúnrúgbìn ẹ̀ṣẹ̀, yóò ká asán: ọ̀pá ìbínú rẹ̀ yóò kùnà.

  8. Ẹni tí ó bá ro ilẹ̀ rẹ̀ yóò ní oúnjẹ lọ́pọ̀lọ́pọ̀ ṣùgbọ́n ẹni tí ń lé ohun asán yóò kún fún òsì.

  9. Mú èké ṣíṣe àti irọ́ jìnnà sí mi; má ṣe fún mi ní òsì tàbí ọrọ̀, ṣùgbọ́n fún mi ní oúnjẹ òòjọ́ mi nìkan.

  10. Ojú dáradára a máa tan ni, ẹwà sì jẹ́ asán nítorí obìnrin tí ó bẹ̀rù Olúwa yẹ kí ó gba oríyìn.

  11. “Asán inú asán!” Oníwàásù náà wí pé, “Asán inú asán! Gbogbo rẹ̀ asán ni.”

  12. Mo rò nínú ọkàn mi, “Wá nísinsin yìí, èmi yóò sì dán ọ wò pẹ̀lú ìgbádùn láti ṣe àwárí ohun tí ó dára.” Ṣùgbọ́n eléyìí náà jásí asán.

  13. Mo tiraka láti dun ara mi nínú pẹ̀lú ọtí wáìnì, àti láti fi ọwọ́ lé òmùgọ̀—ọkàn mi sì ń tọ́ mi pẹ̀lú ọgbọ́n. Mo fẹ́ wo ohun tí ó yẹ ní ṣíṣe fún ènìyàn ní abẹ́ ọ̀run ní ìwọ̀nba ọjọ́ ayé rẹ̀.

  14. Mo ṣe àwọn iṣẹ́ ńlá ńlá. Mo kọ́ ilé púpọ̀ fún ara mi, mo sì gbin ọgbà àjàrà púpọ̀.

  15. Mo ṣe ọgbà àti àgbàlá, mo sì gbin onírúurú igi eléso sí inú wọn.

  16. Mo gbẹ́ adágún láti máa bu omi rin àwọn igi tí ó ń hù jáde nínú ọgbà.

  17. Mo ra àwọn ẹrú ọkùnrin àti àwọn ẹrú obìnrin, mo sì tún ní àwọn ẹrú mìíràn tí a bí sí ilé mi. Mo sì tún ní ẹran ọ̀sìn ju ẹnikẹ́ni ní Jerusalẹmu lọ.

  18. Mo kó fàdákà àti wúrà jọ fún ara mi àti àwọn ohun ìṣúra ti ọba àti ìgbèríko. Mo ní àwọn akọrin ọkùnrin àti obìnrin, àti dídùn inú ọmọ ènìyàn, aya àti obìnrin púpọ̀.

  19. Mo di ẹni ńlá ju ẹnikẹ́ni tí ó wà ní Jerusalẹmu ṣáájú mi. Nínú gbogbo èyí, ọgbọ́n mi kò fi mí sílẹ̀.

  20. Èmi kò jẹ́ kí ojú mi ṣe aláìrí ohun tí ó bá ń fẹ́. N kò sì jẹ́ kí ọkàn mi ó ṣe aláìní ìgbádùn. Ọkàn mi yọ̀ nínú gbogbo iṣẹ́ mi, èyí sì ni èrè fún gbogbo wàhálà mi.

  21. Síbẹ̀, nígbà tí mo wo gbogbo ohun tí ọwọ́ mi ti ṣe àti ohun tí mo ti ṣe wàhálà láti ní: gbogbo rẹ̀, asán ni. Ó dàbí ẹni gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́, kò sí èrè kan ní abẹ́ oòrùn; ọgbọ́n àti òmùgọ̀, asán ni.

  22. Nígbà náà ni mo rò nínú ọkàn wí pé, “Irú ìpín tí òmùgọ̀ ní yóò bá èmi náà pẹ̀lú kí wá ni ohun tí mo jẹ ní èrè nípa ọgbọ́n?” Mo sọ nínú ọkàn mi wí pé, “Asán ni eléyìí pẹ̀lú.”

  23. Nítorí pé ènìyàn le è ṣe iṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú ọgbọ́n, òye àti ìmọ̀ ní abẹ́ oòrùn, tí ó sì ti kọ́ ṣe iṣẹ́ fúnra rẹ̀. Asán ni eléyìí pẹ̀lú àti àdánù ńlá.

  24. Fún ẹni tí ó bá tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn ni Ọlọ́run yóò fún ní ọgbọ́n, ìmọ̀ àti ìdùnnú, ṣùgbọ́n fún ẹni dẹ́ṣẹ̀, Ó fún un ní iṣẹ́ láti ṣà àti láti kó ohun ìní pamọ́ kí ó sì fi fún ẹni tí ó tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn. Eléyìí pẹ̀lú, asán ni, ó dàbí ẹni gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́.

  25. Mo sì tún mọ̀ pẹ̀lú, ìdí tí ènìyàn fi ń ṣiṣẹ́ tagbára tagbára láti ṣe àṣeyọrí, nítorí pé wọn ń jowú àwọn aládùúgbò wọn ni. Ṣùgbọ́n, asán ni, ó dàbí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́.