Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Vanity

88 ẹsẹ · 60 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. A fi gbogbo nǹkan wọ̀nyí hàn yín kí ẹ bá a lè gbà pé Olúwa ni Ọlọ́run. Kò sì sí ẹlòmíràn lẹ́yìn rẹ̀.

  2. Wọ́n kọ̀ ìlànà rẹ̀ àti májẹ̀mú tí ó ti ṣe pẹ̀lú baba wọn àti ìkìlọ̀ tí ó ti fi fún wọn. Wọ́n tẹ̀lé òrìṣà aláìníláárí, àwọn fún rara wọn sì jẹ́ aláìníláárí. Wọ́n tẹ̀lé orílẹ̀-èdè tí ó yí wọn ká bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olúwa ti kìlọ̀ fún wọn pé, “Má ṣe ṣe gẹ́gẹ́ bí wọn tí ń ṣe,” wọ́n sì ṣe ohun tí Olúwa ti kà léèwọ̀ fún wọn láti ṣe.

  3. O sú mi, èmi kò le wà títí: jọ̀wọ́ mi jẹ́, nítorí pé asán ni ọjọ́ mi.

  4. Òun sá à mọ ẹlẹ́tàn ènìyàn; àti pé ṣé bí òun bá rí ohun búburú, ṣé òun kì i fi iyè sí i?

  5. Ṣùgbọ́n òmùgọ̀ ènìyàn ki yóò di ọlọ́gbọ́n bi ko ti rọrùn fún ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó láti bí ènìyàn.

  6. Kí òun kí ó má ṣe gbẹ́kẹ̀lé asán, kí ó má sì ṣe tan ara rẹ̀ jẹ. Nítorí pé asán ní yóò jásí èrè rẹ̀.

  7. Kí ni Olódùmarè tí àwa ó fi máa sìn in? Èrè kí ni a ó sì jẹ bí àwa ba gbàdúrà sí i?

  8. Èéṣe tí àwọn orílẹ̀-èdè fi ń dìtẹ̀, àti tí àwọn ènìyàn ń ṣe rìkíṣí asán?

  9. Báwo ni yóò ṣe pẹ́ tó, ẹ̀yin ọmọ ènìyàn, tí ẹ ó ṣe sọ ògo mi di ìtìjú? Báwo ni yóò ṣe pẹ́ tó, tí ẹ̀yin yóò ṣe fẹ́ràn ìtànjẹ àti tí ẹ̀yin yóò fi máa wá ọlọ́run èké?

  10. Ẹnu rẹ̀ kún fún ègún àti irọ́ àti ìtànjẹ; wàhálà àti ohun búburú wà lábẹ́ ahọ́n rẹ̀.

  11. Olúkúlùkù ń parọ́ fún aládùúgbò rẹ̀; ètè èké wọn ń sọ ẹ̀tàn.

  12. Ẹni tí ó ní ọwọ́ mímọ́ àti àyà funfun, ẹni tí kò gbé ọkàn rẹ̀ sókè sí asán tí kò sì búra èké.

  13. Èmi kò jókòó pẹ̀lú aláìṣòótọ́, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò bá àwọn àgàbàgebè wọlé.

  14. Èmi ti kórìíra àwọn ẹni tí ń fiyèsí òrìṣà tí kò níye lórí; ṣùgbọ́n èmi gbẹ́kẹ̀lé Olúwa.

  15. Wọ́n gbìmọ̀ ìwà ìkà nígbà tí wọ́n wà lórí ibùsùn wọn: wọ́n gba ọ̀nà tí kò dára wọn kò sì kọ ọ̀nà ibi sílẹ̀.

  16. Ìwọ ti ṣe ayé mi bí ìbú àtẹ́lẹwọ́, ọjọ́ orí mi sì dàbí asán ní iwájú rẹ. Dájúdájú olúkúlùkù ènìyàn nínú ìjókòó rere rẹ̀ jásí asán pátápátá. Sela.

  17. “Nítòótọ́ ni olúkúlùkù ń rìn kiri bí òjìji. Nítòótọ́ ni wọ́n ń yọ ara wọn lẹ́nu lórí asán; wọ́n ń kó ọrọ̀ jọ, wọn kò sì mọ ẹni tí yóò ko lọ.

  18. Ìwọ fi ìbáwí kìlọ̀ fún ènìyàn nítorí ẹ̀ṣẹ̀, ìwọ a mú ẹwà rẹ parun bí kòkòrò aṣọ; nítòótọ́ asán ni ènìyàn gbogbo.

  19. Nígbàkígbà tí ẹnìkan bá wá wò mí, wọn ń sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn, nígbà tí àyà rẹ̀ bá kó ẹ̀ṣẹ̀ jọ sí ara rẹ̀; nígbà tí ó bá jáde lọ yóò sì máa tàn án kálẹ̀.

  20. Fún wa ní ìrànlọ́wọ́ lórí àwọn ọ̀tá, nítorí asán ni ìrànlọ́wọ́ ènìyàn.

  21. Nítòótọ́, asán ni àwọn ọmọ ènìyàn, èké sì ni àwọn olóyè, wọ́n gòkè nínú ìwọ̀n, lápapọ̀ wọ́n jẹ́ èémí.

  22. O fi òpin sí ayé wọn nínú asán àti ọdún wọn nínú ìpayà.

  23. Olúwa mọ èrò inú ènìyàn; ó mọ̀ pé asán ni wọ́n.

  24. Yí ojú mi padà kúrò láti máa wo ohun asán: pa ọ̀nà mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.

  25. Èmi kórìíra àwọn ọlọ́kàn méjì, ṣùgbọ́n èmi fẹ́ òfin rẹ.