Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Scriptures: Read publicly to ALL

6 ẹsẹ · 108 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Read publicly to ALL

  1. Nígbà tí gbogbo Israẹli bá wá láti fi ara hàn níwájú Olúwa Ọlọ́run wa ní ibi tí yóò yàn, ìwọ yóò ka òfin yìí níwájú wọn sí etí ìgbọ́ wọn.

  2. Pe àwọn ènìyàn jọ àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin àti àwọn àjèjì tí ń gbé àwọn ìlú u yín kí wọn lè fetí sí i kí wọn sì lè kọ́ láti bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run rẹ kí wọn sì rọra tẹ̀lé gbogbo ọ̀rọ̀ òfin yìí.

  3. Àwọn ọmọ wọn tí wọn kò mọ òfin yìí, gbọdọ̀ gbọ́ kí wọn sì kọ́ láti bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run rẹ níwọ̀n ìgbà tí o tí ń gbé ní ilẹ̀ tí ò ń kọjá la Jordani lọ láti ni.”

  4. Ó kà á sókè láti òwúrọ̀ títí di ọ̀sán bí ó ti kọjú sí ìta ní iwájú ibodè omi ní ojú u gbogbo ọkùnrin, obìnrin àti àwọn ènìyàn tókù tí òye le è yé tí wọ́n wà níbẹ̀. Gbogbo ènìyàn sì fetísílẹ̀ sí ìwé òfin náà pẹ̀lú ìfarabalẹ̀.

  5. Nítorí náà, ìwọ lọ sí ilé Olúwa ní ọjọ́ àwẹ̀, kí o sì kà nínú ìwé kíká náà ọ̀rọ̀ Olúwa tí ìwọ ti ẹnu mi kọ; ìwọ ó sì kà á ní etí gbogbo Juda, tí wọ́n jáde wá láti ìlú wọn.

  6. Lẹ́yìn kíka ìwé òfin àti ìwé àwọn wòlíì, àwọn olórí Sinagọgu ránṣẹ́ sí wọn, pé, “Ará, bí ẹ̀yin bá ni ọ̀rọ̀ ìyànjú kan fún àwọn ènìyàn, ẹ sọ ọ́!”