Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Tapestry

47 ẹsẹ · 5 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ní ìhà ìlà-oòrùn, sí ibi tí oòrùn tí ń jáde, àgbàlá náà yóò jẹ́ mita mẹ́tàlélógún ní fífẹ̀.

  2. Aṣọ títa ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ní gíga ní yóò wà ní ìhà ẹnu-ọ̀nà, pẹ̀lú òpó mẹ́ta àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́ta,

  3. àti aṣọ títa ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ní gíga yóò wá ní ìhà kejì, pẹ̀lú òpó mẹ́ta àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́ta.

  4. “Àti fún ẹnu-ọ̀nà àgbàlá náà, pèsè aṣọ títa, mita mẹ́sàn-án ní gíga, ti aláró, elése àlùkò, ti òdòdó, àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn wíwẹ́ tí a fi iṣẹ́ abẹ́rẹ́ ṣe, pẹ̀lú òpó mẹ́rin àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́rin.

  5. Gbogbo òpó ti ó wà ní àyíká àgbàlá náà ni a ó fi fàdákà ṣo pọ̀ àti ìkọ́, àti ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ.

  6. Gbogbo àwọn ọlọ́gbọ́n ọkùnrin láàrín àwọn òṣìṣẹ́ ni wọ́n ṣe iṣẹ́ náà pẹ̀lú aṣọ títa mẹ́wàá ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára, tí aṣọ aláró, ti elése àlùkò àti ti òdòdó, pẹ̀lú àwọn kérúbù ṣe iṣẹ́ sí wọn nípa ọgbọ́n iṣẹ́ ọnà.

  7. Gbogbo aṣọ títa náà ni kí ó jẹ́ ìwọ̀n kan náà: ìgbọ̀nwọ́ méjìdínlọ́gbọ̀n (28) ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin ni fífẹ̀.

  8. Aṣọ títa márùn-ún ni kí a so papọ̀ mọ́ ara wọn, àti aṣọ títa márùn-ún ni kí a so papọ̀ mọ́ ara wọn.

  9. Ìwọ yóò ṣì ṣe ajábó aṣọ aláró sí aṣọ títa kan láti ìṣẹ́tí rẹ̀ wá níbi ìsopọ̀, àti bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ìwọ yóò ṣe ni etí ìkangun aṣọ títa kejì, ni ibi ìsopọ̀ kejì.

  10. Àádọ́ta ajábó ní ó pa lára aṣọ títa kan, àti àádọ́ta ajábó ni ó sì lò pa ní etí aṣọ títa tí ó wà ní ìsolù kejì, ajábó náà sì wà ní ọ̀kánkán ara wọn.

  11. Ó sì ṣe àádọ́ta ìkọ́ wúrà, ó sì lò ìkọ́ wọ̀n-ọn-nì láti fi aṣọ títa kan kọ́ èkejì, bẹ́ẹ̀ ó sì di odidi àgọ́ kan.

  12. Ìwọ ó sì ṣe aṣọ títa irun ewúrẹ́ láti fi ṣe ìbò sórí àgọ́ náà—aṣọ títa mọ́kànlá ni ìwọ ó ṣe é.

  13. Gbogbo aṣọ títa mọ́kọ̀ọ̀kànlá náà jẹ́ ìwọ̀n kan náà, ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin ní fífẹ̀.

  14. Ó so aṣọ títa márùn-ún pọ̀ mọ́ ara wọn se ọ̀kan, ó sì tún so mẹ́fà tókù mọ́ ara wọn se ọ̀kan.

  15. Ó sì pa àádọ́ta ajábó sí ìṣẹ́tí ìkangun aṣọ títa ní apá kan, wọ́n sì tún pa ajábó mìíràn sí ìṣẹ́tí ìkangun aṣọ títa ní apá kejì.

  16. Wọ́n ṣe àádọ́ta ìkọ́ idẹ láti so àgọ́ náà pọ̀ kí o lè jẹ́ ọ̀kan.

  17. Ó sì lu wúrà náà di ewé fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́, ó sì tún gé e láti fi ṣe iṣẹ́ sí aṣọ aláró, ti elése àlùkò, ti òdòdó, àti sínú ọ̀gbọ̀ dáradára, iṣẹ́ ọlọ́nà.

  18. Ó sì wó ibùgbé àwọn ọkùnrin alágbèrè ojúbọ òrìṣà lulẹ̀. Tí ó wà nínú ilé Olúwa àti ibi tí àwọn obìnrin tí ń ṣe iṣẹ́ aṣọ híhun fún òrìṣà Aṣerah.

  19. Ọgbà náà ní aṣọ fèrèsé funfun àti aláwọ̀ òféfèé. Àwọn okùn tí a fi aṣọ aláwọ̀ funfun àti aláwọ̀ elése àlùkò rán ni a fi ta á mọ́ òrùka fàdákà lára àwọn òpó mabu. Àwọn ibùsùn tí a fi wúrà àti fàdákà ṣe wà níbi pèpéle òkúta tí a fi ń tẹ́lẹ̀ ilé tí ó jẹ́ mabu, píálì àti òkúta olówó iyebíye mìíràn.

  20. Mo ti tẹ́ ibùsùn mi pẹ̀lú aṣọ aláràbarà láti ilẹ̀ Ejibiti.

  21. Ó ṣe aṣọ títẹ́ fún ibùsùn rẹ̀; ẹ̀wù dáradára àti elése àlùkò ni aṣọ rẹ̀.

  22. Èmi dúdú mo sì ní ẹwà. Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu dúdú bí àgọ́ ìlú Kedari, bí aṣọ títa ti Solomoni.