Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Seekers

165 ẹsẹ · 1 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Àwọn òtòṣì yóò rí, wọn yóò sì yọ̀: ẹ̀yin yóò wá Ọlọ́run, ọkàn yín yóò sì wà láààyè!

  2. Ṣùgbọ́n kí àwọn tí ó ń wá ọ ó máa yọ̀ kí inú wọn kí ó sì máa dùn nípa rẹ, kí àwọn tí ó ń fẹ́ ìgbàlà rẹ máa wí pé, “Jẹ́ kí a gbé Ọlọ́run ga!”

  3. Ṣùgbọ́n mo jẹ́ òtòṣì àti aláìní; wa kánkán sí ọ̀dọ̀ mi, Ọlọ́run. Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ àti olùdáǹdè mi; Olúwa, má ṣe dúró pẹ́.

  4. Fún adarí orin. Fún Jedutuni. Ti Asafu. Saamu. Mó kígbe sí Ọlọ́run fún ìrànlọ́wọ́; mo kígbe sí Ọlọ́run láti gbọ́ tèmi.

  5. Nígbà tí mo wà nínú ìpọ́njú, mo wá Olúwa; ní òru ni mo na ọwọ́ mi jáde ní àìkáárẹ̀ ọkàn mí sì kọ̀ láti tù ú nínú.

  6. Èmi rántí rẹ, Ọlọ́run, mo sì kẹ́dùn; mo ṣe àròyé, ẹ̀mí mi sì rẹ̀wẹ̀sì. Sela.

  7. Ìwọ kò fẹ́ kí èmi fi ojú ba oorun, mo dààmú tó bẹ́ẹ̀ tí ń kò le sọ̀rọ̀.

  8. Mo ronú nípa ọjọ́ ìgbàanì; ọdún pípẹ́ sẹ́yìn;

  9. mo rántí orin mi ní òru. Èmi ń bá àyà mi sọ̀rọ̀, ọkàn mi sì ń ṣe àwárí jọjọ.

  10. “Olúwa yóò ha kọ̀ títí láé? Ki yóò ha ṣe ojúrere rẹ̀ mọ́?

  11. Ṣe ìfẹ́ rẹ̀ àti àánú rẹ̀ ti kú lọ láéláé? Ìlérí rẹ̀ ha kùnà títí ayé?

  12. Ọlọ́run ha gbàgbé láti máa ṣàánú? Ní ìbínú rẹ̀, ó ha sé ojúrere rẹ̀ mọ́?” Sela.

  13. Nígbàkígbà tí Ọlọ́run bá pa wọ́n, wọn yóò wá a kiri; wọn yóò fi ìtara yípadà sí i.

  14. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ, ẹni tí ó mú un yín jáde láti Ejibiti. Ẹ la ẹnu yín gbòòrò, èmi yóò sì kún un.

  15. Fi ìtìjú kún ojú wọn, kí àwọn ènìyàn bá à lè ṣe àfẹ́rí orúkọ rẹ àti kí o fi ìjì líle rẹ dẹ́rùbà, ìwọ Olúwa.

  16. Ọkàn mi ń ṣàfẹ́rí nítòótọ́ ó tilẹ̀ pòǹgbẹ fún àgbàlá Olúwa àyà mi àti ara mi ń kọrin ayọ̀ sí Ọlọ́run alààyè.

  17. Wá Olúwa àti ipá rẹ̀; wa ojú rẹ̀ nígbà gbogbo.

  18. Ìbùkún ni fún àwọn ẹni tí ń pa òfin rẹ̀ mọ́ tí wọn sì ń wá a pẹ̀lú gbogbo ọkàn wọn.

  19. Èmi wá ọ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi má ṣe jẹ́ kí èmi yapa kúrò nínú àṣẹ rẹ.

  20. Èmi dúró de Olúwa, ọkàn mi dúró, àti nínú ọ̀rọ̀ rẹ ni èmi ń ṣe ìrètí.

  21. Ọkàn mi dúró de Olúwa, ju àwọn tí ń ṣọ́nà òwúrọ̀ lọ, àní ju àwọn tí ń ṣọ́nà òwúrọ̀ lọ.

  22. Èmi na ọwọ́ mi jáde sí ọ: òǹgbẹ rẹ gbẹ ọkàn mi bí i ìyàngbẹ ilẹ̀. Sela.

  23. Olúwa wà ní tòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é, sí gbogbo ẹni tí ń ké pè é ní òtítọ́.

  24. Ó mú ìfẹ́ àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ṣẹ; ó gbọ́ igbe wọn, ó sì gbà wọ́n.

  25. àní, bí ìwọ bá ké tọ ìmọ̀ lẹ́yìn, tí ìwọ sì gbé ohùn rẹ sókè fún òye