Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Rocks

98 ẹsẹ · 54 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. “Tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin tí ó ń lépa òdodo àti ẹ̀yin tí ń wá Olúwa. Wo àpáta, nínú èyí tí a ti gé yín jáde àti ihò òkúta níbi tí a ti gbẹ́ yín jáde;

  2. Ẹ gbinájẹ fún ìṣekúṣe láàrín igi óákù àti lábẹ́ gbogbo igi tí ń gbilẹ̀; ẹ fi àwọn ọmọ yín rú ẹbọ nínú kòtò jíjìn àti lábẹ́ àwọn pàlàpálá òkúta.

  3. Olúwa, ojú rẹ kò ha wà lára òtítọ́? Ìwọ lù wọ́n, kò dùn wọ́n; ìwọ bá wọn wí, wọ́n kọ̀ láti yípadà. Wọ́n mú ojú wọn le ju òkúta lọ, wọ́n sì kọ̀ láti yípadà.

  4. “Ṣùgbọ́n báyìí, Èmi yóò ránṣẹ́ sí àwọn apẹja púpọ̀,” ni Olúwa wí. “Wọn ó sì dẹ wọ́n lẹ́yìn èyí yìí èmi yóò ránṣẹ́ sí àwọn ọdẹ púpọ̀, wọn yóò dẹ wọ́n lórí gbogbo òkè ńlá àti òkè gíga, àti ní gbogbo pálapàla àpáta.

  5. “Ọ̀rọ̀ mi kò ha a dàbí iná?” ni Olúwa wí, “àti bí òòlù irin tí ń fọ́ àpáta túútúú?

  6. Kúrò ní àwọn ìlú rẹ, kí o sì máa gbé láàrín àwọn òkúta, ẹ̀yin tí ó ti ń gbé inú ìlú Moabu. Ẹ dàbí i àdàbà tí ó kọ́ ìtẹ́ rẹ̀ sí ẹnu ihò.

  7. Ìpayà tí ìwọ ti fà sínú ìgbéraga ọkàn rẹ sì ti tàn ọ́ jẹ; ìwọ tí ń gbé ní pàlàpálá àpáta, tí o jókòó lórí ìtẹ́ gíga síbẹ̀ o kọ́ ìtẹ́ rẹ ga gẹ́gẹ́ bí ẹyẹ idì; láti ibẹ̀ ni èmi yóò ti mú ọ sọ̀kalẹ̀ wá,” ni Olúwa wí.

  8. Wọn yóò wó odi tire lulẹ̀, wọn yóò sì wo ilé ìṣọ́ rẹ̀ lulẹ̀, Èmi yóò sì ha erùpẹ̀ rẹ̀ kúrò, Èmi yóò sì sọ ọ́ di orí àpáta.

  9. Èmi yóò sọ ọ di àpáta lásán, ìwọ yóò sì di ibi tí a ń sá àwọ̀n ẹja sí. A kì yóò sì tún ọ mọ nítorí Èmi Olúwa ti sọ ọ̀rọ̀ ní Olúwa Olódùmarè wí.

  10. Ǹjẹ́ ẹṣin a máa sáré lórí àpáta bí? Ǹjẹ́ ènìyàn a máa fi akọ màlúù kọ ilẹ̀ níbẹ̀? Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti yí òtítọ́ padà sí májèlé ẹ sì ti sọ èso òdodo di ìkorò.

  11. Ta ni ó lé dúró níwájú ìbínú rẹ̀? Ta ni ó lé faradà gbígbóná ìbínú rẹ̀? Ìbínú rẹ̀ tú jáde bí iná; àwọn àpáta sì fọ́ túútúú níwájú rẹ̀.

  12. “Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ tèmi wọ̀nyí, tí ó bá sì ṣe wọn, èmi ó fiwé ọlọ́gbọ́n ènìyàn kan, ti ó kọ́ ilé rẹ̀ sí orí àpáta.

  13. Òjò sì rọ̀, ìkún omi sì dé, afẹ́fẹ́ sì fẹ́, wọ́n sí bì lu ilé náà; síbẹ̀síbẹ̀ náà kò sì wó, nítorí tí a fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ lórí àpáta.

  14. Èmi wí fún ọ, ìwọ ni Peteru àti pé orí àpáta yìí ni èmi yóò kọ́ ìjọ mi lé, àti ẹnu-ọ̀nà ipò òkú kì yóò lè borí rẹ̀.

  15. Lójúkan náà aṣọ ìkélé tẹmpili fàya, láti òkè dé ìsàlẹ̀. Ilẹ̀ sì mì tìtì. Àwọn àpáta sì sán.

  16. Ó sì tẹ́ ẹ sínú ibojì òkúta tí ó gbẹ́ nínú àpáta fúnra rẹ̀. Ó sì yí òkúta ńlá dí ẹnu-ọ̀nà ibojì náà, ó sì lọ.

  17. Òmíràn sì bọ́ sórí àpáta; bí ó sì ti hù jáde, ó gbẹ nítorí tí kò ní omi.

  18. Nígbà tí oòrùn àti ìràwọ̀ kò si hàn lọ́jọ́ púpọ̀, tí ìjì náà kò sì mọ níwọ̀n fún wa, àbá àti là kò sí fún wa mọ́.

  19. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Kíyèsi, mo gbé òkúta ìkọ̀sẹ̀ kalẹ̀ ní Sioni àti àpáta tí ó mú wọn ṣubú, ẹnikẹ́ni ti ó bá sì gbà a gbọ́, ojú kì yóò tì í.”

  20. Wọ́n mu nínú omi tí Kristi fi fún wọn. Wọ́n mu omi ẹ̀mí láti inú àpáta tí ó ń tẹ̀lé wọn, àpáta náà ni Kristi. Ó wà pẹ̀lú wọn nínú aginjù náà, òun ni àpáta tí ń fi omi ẹ̀mí tu ọkàn lára.

  21. Nítorí nínú Ìwé Mímọ́, ó wí pe: “Kíyèsi i, mo fi pàtàkì òkúta igun ilé àṣàyàn, iyebíye, lélẹ̀ ni Sioni: ẹni tí ó bá sì gbà á gbọ́ ojú kì yóò tì í.”

  22. àti pẹ̀lú, “Òkúta ìdìgbòlù, àti àpáta ìkọ̀sẹ̀.” Nítorí wọ́n kọsẹ̀ nípa ṣíṣe àìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ náà, sínú èyí tí a gbé yàn wọ́n sí pẹ̀lú.

  23. Àwọn ọba ayé àti àwọn ọlọ́lá àti àwọn olórí ogun, àti àwọn ọlọ́rọ̀ àti àwọn alágbára, àti olúkúlùkù ẹrú, àti olúkúlùkù òmìnira, sì fi ara wọn pamọ́ nínú ihò ilẹ̀, àti nínú àpáta orí òkè;