Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Rocks

98 ẹsẹ · 54 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli si gbéra láti jáde kúrò láti aginjù Sini wọ́n ń lọ láti ibi kan de ibi kan gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ. Wọ́n pàgọ́ sí Refidimu, ṣùgbọ́n kò sí omi fún àwọn ènìyàn láti mú.

  2. Àwọn ènìyàn sì sọ̀ fún Mose, wọ́n wí pé, “Fún wa ni omi mu.” Mose dá wọn lóhùn wí pé, “Èéṣe ti ẹ̀yin fi ń bá mi jà? Èéṣe ti ẹ̀yin fi ń dán Olúwa wò?”

  3. Ṣùgbọ́n òǹgbẹ ń gbẹ àwọn ènìyàn, wọ́n sì ń kùn sí Mose, wọ́n wí pé, “Èéṣe tí ìwọ fi mú wa jáde kúrò ní Ejibiti láti mú kí òǹgbẹ pa àwa, àwọn ọmọ wa àti ohun ọ̀sìn wa ku fún òǹgbẹ.”

  4. Nígbà náà ni Mose gbé ohùn rẹ̀ sókè sí Olúwa pé, “Kí ni kí èmi kí ó ṣe fún àwọn ènìyàn yìí? Wọ́n múra tan láti sọ mi ni òkúta.”

  5. Olúwa sì dá Mose lóhùn pé, “Máa lọ síwájú àwọn ènìyàn, mú nínú àwọn àgbàgbà Israẹli pẹ̀lú rẹ, mú ọ̀pá tí ìwọ fi lu odò Naili lọ́wọ́ kí ó sì máa lọ.

  6. Èmi yóò dúró ni ibẹ̀ dè ọ ni orí àpáta ni Horebu. Ìwọ ó sì lu àpáta, omi yóò sì jáde nínú rẹ̀ fún àwọn ènìyàn láti mu.” Mose sì ṣe bẹ́ẹ̀ ni iwájú àwọn àgbàgbà Israẹli.

  7. Olúwa sì wí pé, “Ibìkan wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀dọ̀ mi, níbi tí o ti lè dúró lórí àpáta.

  8. Nígbà tí ògo mi bá kọjá, Èmi yóò gbé ọ sínú pàlàpálá àpáta, Èmi yóò sì bò ọ́ pẹ̀lú ọwọ́ mi títí Èmi yóò fi rékọjá.

  9. Ní oṣù kìn-ín-ní, gbogbo àgbájọ ọmọ Israẹli gúnlẹ̀ sí pápá Sini, wọ́n sì dúró ní Kadeṣi. Níbẹ̀ ni Miriamu kú, wọ́n sì sin ín.

  10. Omi kò sí fún ìjọ ènìyàn, àwọn ènìyàn sì kó ara wọn jọ pọ̀ sí Mose àti Aaroni,

  11. wọ́n bá Mose jà wọ́n sì wí pé, “Ìbá kúkú sàn kí a kú nígbà tí àwọn arákùnrin ti kú níwájú Olúwa!

  12. Kí ni ó dé tí o sì kó gbogbo ìjọ ènìyàn Olúwa wá sí aginjù yìí, kí àwa àti àwọn ẹran ọ̀sìn wa bá à kú síbí?

  13. Kí ni ó dé tí o fi mú wa gòkè kúrò ní Ejibiti wá sí ibi búburú yìí? Ibi tí kò ní oúnjẹ tàbí igi ọ̀pọ̀tọ́, èso àjàrà tàbí pomegiranate. Bẹ́ẹ̀ ni kò sí omi tí a ó mu níhìn-ín!”

  14. Mose àti Aaroni kúrò ní ibi àpéjọ, wọ́n sì lọ dojúbolẹ̀ sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, ògo Olúwa sì farahàn wọ́n.

  15. Olúwa sọ fún Mose pé,

  16. “Mú ọ̀pá, náà kí o sì pe ìjọ àwọn ènìyàn jọ, ìwọ àti Aaroni arákùnrin rẹ, kí ẹ sọ̀rọ̀ sí àpáta náà ní ojú wọn, yóò sì tú omi rẹ̀ jáde, ìwọ ó sì fún ìjọ àti ẹran wọn mu.”

  17. Báyìí ni Mose mú ọ̀pá láti iwájú Olúwa wá, gẹ́gẹ́ bí ó ti pàṣẹ fún un.

  18. Òun àti Aaroni pe àwọn ènìyàn jọ sí ojú kan níwájú àpáta, Mose sì sọ fún wọn, “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọlọ̀tẹ̀, àwa kì yóò lè mú omi jáde láti inú àpáta yìí wá bí?”

  19. Nígbà náà ni Mose gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè ó sì fi ọ̀pá ọwọ́ rẹ̀ lu àpáta lẹ́ẹ̀méjì. Omi sì tú jáde, gbogbo ìjọ ènìyàn àti àwọn ẹran ọ̀sìn wọn sì mu.

  20. Láti ṣóńṣó ibi gíga orí àpáta ni mo ti rí wọn, láti orí ibi gíga ni mo ti ń wò wọ́n. Mo rí àwọn ènìyàn tí ń gbé lọ́tọ̀ wọn kò sì ka ará wọn kún ara àwọn orílẹ̀-èdè.

  21. Òun ni ó mú un yín la aginjù ẹlẹ́rù ńlá já, ilẹ̀ tí kò sí omi tí ó sì kún fún òǹgbẹ, pẹ̀lú àwọn ejò olóró ńlá ńlá àti àkéekèe. Ó mú omi jáde fún un yín láti inú àpáta.

  22. Ó mú gun ibi gíga ayé ó sì fi èso oko bọ́ ọ. Ó sì jẹ́ kí ó mú oyin láti inú àpáta wá, àti òróró láti inú akọ òkúta wá.

  23. Jeṣuruni sanra tán ó sì tàpá; ìwọ sanra tán, ìwọ ki tan, ọ̀rá sì bò ọ́ tán. O kọ Ọlọ́run tí ó dá ọ o sì kọ àpáta ìgbàlà rẹ.

  24. Ìwọ kò rántí àpáta, tí ó bí ọ; o sì gbàgbé Ọlọ́run tí ó dá ọ.

  25. Nítorí pé àpáta wọn kò dàbí àpáta wa, àní àwọn ọ̀tá wa tìkára wọn ń ṣe onídàájọ́.