Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Rehoboam: Ten tribes, under leadership of Jeroboam, successfully revolt from

17 ẹsẹ · 7 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Ten tribes, under leadership of Jeroboam, successfully revolt from

  1. Nígbà tí gbogbo Israẹli rí i pé ọba kọ̀ láti gbọ́ ti àwọn, wọ́n sì dá ọba lóhùn pé, “Ìpín wo ni àwa ní nínú Dafidi, ìní wo ni àwa ní nínú ọmọ Jese? Padà sí àgọ́ rẹ, ìwọ Israẹli! Bojútó ilé ara rẹ, ìwọ Dafidi!” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ará Israẹli padà sí ilé wọn.

  2. Ṣùgbọ́n fún ti àwọn ọmọ Israẹli tí ń gbé nínú ìlú Juda, Rehoboamu jẹ ọba lórí wọn síbẹ̀.

  3. Ọba Rehoboamu rán Adoniramu jáde, ẹni tí ó wà ní ìkáwọ́ iṣẹ́ onírúurú, ṣùgbọ́n gbogbo Israẹli sọ ọ́ ní òkúta pa. Ọba Rehoboamu, gbìyànjú láti dé inú kẹ̀kẹ́ rẹ̀ ó sì sálọ sí Jerusalẹmu.

  4. Bẹ́ẹ̀ ni Israẹli ṣọ̀tẹ̀ sí ilé Dafidi títí di òní yìí.

  5. Nígbà tí gbogbo Israẹli sì gbọ́ pé Jeroboamu ti padà dé, wọ́n ránṣẹ́, wọ́n sì pè é wá sí àjọ, wọ́n sì fi jẹ ọba lórí gbogbo Israẹli. Kò sí ẹnìkan tí ó tọ ilé Dafidi lẹ́yìn bí kò ṣe kìkì ẹ̀yà Juda nìkan.

  6. Nígbà tí Rehoboamu sì dé sí Jerusalẹmu, ó kó gbogbo ilé Juda jọ, àti ẹ̀yà Benjamini; ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án (180,000) ènìyàn tí a yàn, tí wọ́n ń ṣe ológun, láti bá ilé Israẹli jà àti láti mú ìjọba náà padà bọ̀ sọ́dọ̀ Rehoboamu, ọmọ Solomoni.

  7. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ Ṣemaiah ènìyàn Ọlọ́run wá wí pé,

  8. “Sọ fún Rehoboamu, ọmọ Solomoni, ọba Juda àti fún gbogbo ilé Juda àti ti Benjamini, àti fún àwọn ènìyàn tókù wí pé,

  9. ‘Báyìí ni Olúwa wí, “Ẹ má ṣe gòkè lọ láti bá àwọn arákùnrin yín jà, àwọn ènìyàn Israẹli. Kì olúkúlùkù yín padà sí ilé rẹ̀, nítorí nǹkan yìí láti ọ̀dọ̀ mi wá ni.” ’ ” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, wọ́n sì tún padà sí ilé wọn, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa.

  10. Nígbà tí gbogbo Israẹli rí i wí pé ọba kọ̀ láti gbọ́ tiwọn, wọ́n sì dá ọba lóhùn wí pé, “Ìpín kí ní a ní nínú Dafidi, ìní wo ni a ní nínú ọmọ Jese? Ẹ lọ sí àgọ́ yín, ẹ̀yin Israẹli! Bojútó ilé rẹ, ìwọ Dafidi!” Bẹ́ẹ̀ ní gbogbo àwọn ọmọ Israẹli lọ sí ilé wọn.

  11. Ṣùgbọ́n ní ti àwọn ọmọ Israẹli tí ń gbé ní ìlú Juda, Rehoboamu ń jẹ ọba lórí wọn.

  12. Ọba Rehoboamu rán Adoniramu jáde, ẹni tí ó wà ní ìkáwọ́ iṣẹ́ onírúurú, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Israẹli sọ ọ́ ní òkúta pa. Ọba Rehoboamu, gbìyànjú láti dé inú kẹ̀kẹ́ rẹ̀ ó sì sálọ sí Jerusalẹmu.

  13. Bẹ́ẹ̀ ni Israẹli sì wà ní ìṣọ̀tẹ̀ lórí ilé Dafidi títí fi di òní yìí.

  14. Nígbà tí Rehoboamu dé Jerusalẹmu, ó kó ilé Juda àti Benjamini jọ, ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án (180,000) ènìyàn tí a yàn, tí wọ́n jẹ́ ológun, láti bá Israẹli jà kí ó lè mú ìjọba náà padà bọ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀.

  15. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Ṣemaiah ènìyàn Ọlọ́run wá wí pé,

  16. “Wí fún Rehoboamu ọmọ Solomoni ọba Juda, sí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ní Juda àti Benjamini,

  17. ‘Èyí ní ohun tí Olúwa wí. Ẹ má ṣe gòkè lọ láti lọ jà pẹ̀lú arákùnrin yín, ẹ lọ sílé, gbogbo yín, nítorí ti ìṣe mi nìyí.’ ” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tẹ̀lé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n sì padà sẹ́yìn láti yan lọ dojúkọ Jeroboamu.