Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Oppression

86 ẹsẹ · 8 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí. “Ní ìgbà àkọ́kọ́ àwọn ènìyàn mi sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ejibiti láti gbé; láìpẹ́ ni Asiria pọ́n wọn lójú.

  2. “Ǹjẹ́ irú àwẹ̀ tí mo ti yàn kọ́ ni èyí: láti já gbogbo ẹ̀wọ̀n àìṣòdodo àti láti tú gbogbo okùn àjàgà, láti tú gbogbo àwọn ti à ń ni lára sílẹ̀ àti láti fọ́ gbogbo àjàgà?

  3. Ilé Dafidi èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa sọ: “ ‘Ṣe ìdájọ́ tí ó tọ́ ní àràárọ̀; yọ ọ́ kúrò lọ́wọ́ ẹni tí ó ń ni í lára ẹni tí a ti jà lólè bí bẹ́ẹ̀ kọ́ ìbínú mi yóò jáde síta, yóò sì jó bí iná. Nítorí ibi tí a ti ṣe yóò sì jó láìsí ẹni tí yóò pa á.

  4. “Ṣùgbọ́n ojú rẹ àti ọkàn rẹ wà lára èrè àìṣòótọ́ láti ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ìnilára àti ìlọ́nilọ́wọ́gbà.”

  5. Síbẹ̀, Olùràpadà wọn, Alágbára, Olúwa Ọlọ́run Alágbára ni orúkọ rẹ̀. Yóò sì gbe ìjà wọn jà, kí ó ba à lè mú wọn wá sinmi ní ilẹ̀ náà; ṣùgbọ́n kò sí ìsinmi fún àwọn tí ó ń gbé Babeli.

  6. Nínú rẹ wọn ti hùwà sí baba àti ìyá pẹ̀lú ìfojú tínrín; nínú rẹ wọn ti ni àwọn àlejò lára, wọn sì hùwàkiwà sí aláìní baba àti opó.

  7. Àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà, tí lo ìwà ìninilára, wọn sì já olè, wọn sì ni àwọn tálákà àti aláìní lára; nítòótọ́, wọn tí ní àlejò lára láìnídìí. Kò sì ṣí ìdájọ́ òdodo.

  8. “ ‘Èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Ẹ̀yin ti rìn jìnnà tó, ẹ̀yin ọmọ-aládé tí Israẹli! Ẹ fi ìwà ipá àti ìrẹ́jẹ yín sílẹ̀ kí ẹ̀yin sì ṣe èyí tí ó tọ́ àti èyí tí ó yẹ. Ẹ dáwọ́ gbígbà ní ọwọ́ àwọn ènìyàn mi dúró, ni Olúwa Ọlọ́run wí.

  9. Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ẹ̀yin màlúù Baṣani lórí òkè Samaria, ẹ̀yin obìnrin tí ó ń ni tálákà lára, tí ó ń tẹ aláìní mọ́lẹ̀, tí ó wí fún ọkọ rẹ̀, “Gbé wá kí a sì mu!”

  10. Ìwọ ń tẹ tálákà mọ́lẹ̀ o ń fi ipá gba ọkà lọ́wọ́ wọn. Nítorí náà, ìwọ ti fi òkúta tí a gbẹ́ kọ́lé ṣùgbọ́n ẹ kò sì ní gbé inú wọn, Nítòótọ́ ìwọ ti gbin ọgbà àjàrà tí ó lẹ́wà. Ìwọ kò ní mu wáìnì inú wọn.

  11. Nítorí mo mọ iye àìṣedéédéé rẹ mo sì mọ bí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ tí tóbi tó. Ìwọ ni olódodo lára, ìwọ sì ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ o sì ń fi òtítọ́ du tálákà ní ilé ẹjọ́.

  12. Ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yin tí ń tẹ aláìní lórí ba, tí ẹ sì ń sọ tálákà di ilẹ̀.

  13. Tí ẹ ń wí pé, “Nígbà wo ni oṣù tuntun yóò parí kí àwa bá à lè ta ọkà kí ọjọ́ ìsinmi kí ó lè dópin kí àwa bá à le ta jéró?” Kí a sì dín ìwọ̀n wa kù kí a gbéraga lórí iye tí a ó tà á kí a sì fi òsùwọ̀n èké yàn wọ́n jẹ,

  14. kí àwa lè fi fàdákà ra àwọn tálákà, kí a sì fi bàtà ẹsẹ̀ méjèèjì ra aláìní, kí a sì ta jéró tí a kó mọ́ ilẹ̀.

  15. Ègbé ni fún àwọn tí ń gbèrò àìṣedéédéé tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ ibi lórí ibùsùn wọn! Nígbà tí ojúmọ́ bá mọ́, wọn yóò gbé e jáde nítorí ó wà ní agbára wọn láti ṣe é.

  16. Wọ́n sì ń ṣe ojúkòkòrò oko, wọ́n sì fi agbára wọn gbà wọ́n, àti àwọn ilé, wọ́n sì gbà wọ́n. Wọ́n sì ni ènìyàn àti ilẹ̀ rẹ̀ lára àní ènìyàn àti ohun ìní rẹ̀.

  17. Nítorí náà, Olúwa wí pé: “Èmi ń gbèrò ibi sí àwọn ìdílé wọ̀nyí, nínú èyí tí wọn kì yóò le è gba ara wọn là. Ìwọ kì yóò sì lè máa rìn ní ìgbéraga mọ́, nítorí yóò jẹ́ àkókò ibi.

  18. Bẹ́ẹ̀ ni pẹ̀lú, nítorí tí ọtí wáìnì ni ẹ̀tàn, agbéraga ènìyàn òun, kò sì ní sinmi ẹni tí ó sọ ìwọra rẹ di gbígbòòrò bí isà òkú, ó sì dàbí ikú, a kò sì le tẹ́ ẹ lọ́rùn, ó kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọ sí ọ̀dọ̀ ó sì gba gbogbo ènìyàn jọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀.

  19. “Gbogbo àwọn wọ̀nyí kì yóò máa pa òwe sí i tí wọn yóò sì máa kọ orin òwe sí i wí pé, “ ‘Ègbé ni fún ẹni tí ń mu ohun tí kì í ṣe tirẹ̀ pọ̀ sí i! Tí ó sì sọ ara rẹ̀ di ọlọ́rọ̀ nípasẹ̀ ìlọ́nilọ́wọ́gbà! Eléyìí yóò ha ti pẹ́ tó?’

  20. Ǹjẹ́ ẹni ti ó yọ ọ́ lẹ́nu, kí yóò ha dìde ní òjijì? Àti àwọn tí ó wàhálà rẹ kì yóò jí, kí wọn ó sì dẹ́rùbà ọ́? Nígbà náà ni ìwọ yóò wa dí ìkógun fún wọn.

  21. Nítorí ìwọ ti kó Orílẹ̀-èdè púpọ̀, àwọn ènìyàn tókù yóò sì kó ọ nítorí ìwọ tí ta ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀; nítorí ẹ̀jẹ̀, ìwọ tí pa ilẹ̀ àti ìlú ńlá run àti gbogbo ènìyàn to ń gbé inú rẹ̀.

  22. “Ègbé ni fún ẹni tí ń jẹ èrè ìjẹkújẹ sí ilé rẹ̀, tí o sí gbé ìtẹ́ rẹ̀ lórí ibi gíga, kí a ba le gbà á sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ibi!

  23. Ìwọ ti gbìmọ̀ ìtìjú sí ilé rẹ nípa kíké ènìyàn púpọ̀ kúrò; ìwọ sì ti pàdánù ẹ̀mí rẹ.

  24. Nítorí tí òkúta yóò kígbe jáde láti inú ògiri wá, àti ìtí igi láti inú igi rírẹ́ wá yóò sì dá a lóhùn.

  25. Má sì ṣe ni opó lára tàbí aláìní baba, àlejò, tàbí tálákà; kí ẹnikẹ́ni nínú yín má ṣe gbèrò ibi ní ọkàn sí arákùnrin rẹ̀.’