Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Oath

85 ẹsẹ · 2 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nítorí náà ni mo kéde ìbúra nínú ìbínú mi, ‘Wọn kì yóò wọ ibi ìsinmi mi.’ ”

  2. májẹ̀mú tí ó dá pẹ̀lú Abrahamu, ìbúra tí ó ṣe pẹ̀lú fún Isaaki.

  3. Olúwa ti búra nítòótọ́ fún Dafidi, Òun kì yóò yípadà kúrò nínú rẹ̀, nínú irú-ọmọ inú rẹ ni èmi ó gbé kalẹ̀ sí orí ìtẹ́ rẹ.

  4. Mo sọ wí pé, pa òfin ọba mọ́, nítorí pé, ìwọ ti ṣe ìbúra níwájú Ọlọ́run.

  5. Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti búra, “Gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣètò, bẹ́ẹ̀ ni yóò rí, àti bí mo ti pinnu, bẹ́ẹ̀ ni yóò sì dúró.

  6. Nípa èmi tìkára mi ni mo ti búra, ẹnu mi ni ó ti sọ ọ́ pẹ̀lú gbogbo ipá mi, ọ̀rọ̀ náà tí a kì yóò lè parẹ́. Níwájú mi ni gbogbo orúnkún yóò wólẹ̀; nípa mi ni gbogbo ahọ́n yóò búra.

  7. “Tẹ́tí sí èyí, ìwọ ilé e Jakọbu, ìwọ tí a ń pè pẹ̀lú orúkọ Israẹli tí o sì wá láti ẹ̀ka Juda, ìwọ tí ò ń búra ní orúkọ Olúwa tí o sì ń pe Ọlọ́run Israẹli ṣùgbọ́n kì í ṣe ní òtítọ́ àti òdodo,

  8. Tí ó bá jẹ́ lóòtítọ́ àti òdodo ni ìwọ búra. Nítòótọ́ bí Olúwa ti wà láààyè, nígbà náà ni orílẹ̀-èdè yóò di alábùkún fún nípasẹ̀ rẹ, àti nínú rẹ̀ ni wọn yóò ṣògo.”

  9. Bí wọ́n tilẹ̀ wí pé, ‘Bí Olúwa ti ń bẹ,’ síbẹ̀ wọ́n búra èké.”

  10. “Kí ni ṣe tí èmi ó ṣe dáríjì ọ́? Àwọn ọmọ rẹ ti kọ̀ mí sílẹ̀ àti pé wọ́n ti fi ọlọ́run tí kì í ṣe Ọlọ́run búra. Mo pèsè fún gbogbo àìní wọn, síbẹ̀ wọ́n tún ń ṣe panṣágà wọ́n sì kórajọ sí ilé àwọn alágbèrè.

  11. Ẹ wò ó, ẹ ń gba ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn tí kò níláárí gbọ́.

  12. “ ‘Ẹ̀yin yóò ha jalè, kí ẹ pànìyàn, kí ẹ ṣe panṣágà, kí ẹ búra èké, kí ẹ sun tùràrí sí Baali, kí ẹ sì tọ ọlọ́run mìíràn tí ẹ̀yin kò mọ̀ lọ?

  13. Nígbà náà ni Èmi ó sì mú ìlérí tí mo búra fún àwọn baba ńlá yín ṣẹ; láti fún wọn ní ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti fún oyin,’ ilẹ̀ tí ẹ ní lónìí.” Mo sì dáhùn wí pé, “Àmín, Olúwa.”

  14. Bí wọ́n bá sì kọ ìwà àwọn ènìyàn mi, tí wọ́n sì fi orúkọ mi búra wí pé, ‘Níwọ̀n bí Olúwa ń bẹ láààyè,’ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti kọ́ àwọn ènìyàn mi láti fi Baali búra, nígbà náà ni a ó gbé wọn ró láàrín àwọn ènìyàn mi.

  15. Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá tẹ̀lé àṣẹ wọ̀nyí, mo búra fúnra mi pé ààfin yìí yóò di ìparun ni Olúwa wí.’ ”

  16. Èmi fi ara mi búra ni Olúwa wí, wí pé, “Bosra yóò ba ayé ara rẹ̀ jẹ́. Yóò di ẹni ẹ̀gàn, ẹni èpè àti ẹni ègún, àti gbogbo ìlú rẹ̀ yóò di ìbàjẹ́ títí láé.”

  17. Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti búra fún ara rẹ̀, Èmi yóò fún ọ ní ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ eṣú, wọn yóò yọ ayọ̀, ìṣẹ́gun lórí rẹ.

  18. Gbogbo Israẹli ti ṣẹ̀ sí òfin rẹ, wọ́n ti yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ, wọ́n kọ̀ láti ṣe ìgbọ́ràn sí ọ. “Nígbà náà ni ègún àti ìdájọ́ tí a kọ sílẹ̀ pẹ̀lú ìbúra nínú òfin Mose ìránṣẹ́ Ọlọ́run dà sórí i wa, nítorí tí àwa ti sẹ̀ sí ọ.

  19. Ọkùnrin tí ó wọ aṣọ àlà, ẹni tí ó wà lórí omi odò, gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti ọwọ́ òsì rẹ̀, mo gbọ́ tí ó fi ẹni tí ó wà títí láé búra, ó sọ wí pé, “Yóò ṣe ní àkókò kan, àkókò méjì àti ààbọ̀. Nígbà tí agbára àwọn ẹni mímọ́ yóò ti fọ́ tán pátápátá, gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò sì parí.”

  20. “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o ṣe àgbèrè ìwọ Israẹli, ìdájọ́ yìí wà fún un yín. Ẹ má ṣe jẹ́ kí Juda di ẹlẹ́bi. “Ẹ má ṣe lọ sí Gilgali. Ẹ má sì ṣe gòkè lọ sí Beti-Afeni ẹ má sì búra pé, ‘Bí Olúwa ti wà láààyè nítòótọ́!’

  21. “Ẹ̀yin ti gbọ́ bí a ti wí fún àwọn ará ìgbàanì pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ búra èké bí kò ṣe pé kí ìwọ kí ó mú ìbúra rẹ̀ fún Olúwa ṣẹ.’

  22. Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín, ẹ má ṣe búra rárá: ìbá à ṣe fífi ọ̀run búra, nítorí ìtẹ́ Ọlọ́run ni.

  23. Tàbí fi ayé búra, nítorí àpótí ìtìsẹ̀ Ọlọ́run ni; tàbí Jerusalẹmu, nítorí olórí ìlú ọba ńlá ni.

  24. Má ṣe fi orí rẹ búra, nítorí ìwọ kò lè sọ irun ẹyọ kan di funfun tàbí di dúdú.

  25. Ẹ jẹ́ kí bẹ́ẹ̀ ni yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni àti bẹ́ẹ̀ kọ́ yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ kọ́, ohunkóhun tí ó ba ju ìwọ̀nyí lọ, wá láti ọ̀dọ̀ ẹni ibi.