Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Commandments

394 ẹsẹ · 3 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Kí àwọn díákónì jẹ́ ọkọ obìnrin kan, kí wọn káwọ́ àwọn ọmọ àti ilé ara wọn dáradára.

  2. Nítorí àwọn tí ó lo ipò díákónì dáradára ra ipò rere fún ara wọn, àti ìgboyà púpọ̀ nínú ìgbàgbọ́ tí ń bẹ nínú Kristi Jesu.

  3. Nísinsin yìí, èmi ń tẹnumọ́ ọ́ pé ní ìgbà ìkẹyìn àwọn mìíràn yóò kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọn yóò máa fiyèsí àwọn ẹ̀mí tí ń tannijẹ, àti ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù.

  4. Nípa àgàbàgebè àwọn tí ń ṣèké, àwọn tí ọkàn tìkára wọn dàbí èyí tí a fi irin gbígbóná jó.

  5. Àwọn tí ń dánilẹ́kun láti gbéyàwó tiwọn si ń pàṣẹ láti ka èèwọ̀ oúnjẹ ti Ọlọ́run ti dá fún ìtẹ́wọ́gbà pẹ̀lú ọpẹ́ àwọn onígbàgbọ́ àti àwọn ti ó mọ òtítọ́.

  6. Nítorí gbogbo ohun ti Ọlọ́run dá ni ó dára, kò sí ọkàn tí ó yẹ kí a kọ̀, bí a bá fi ọpẹ́ gbà á.

  7. Nítorí tí a fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti àdúrà yà sí mímọ́.

  8. Bí ìwọ bá ń rán àwọn ará létí nǹkan wọ̀nyí, ìwọ ó jẹ́ ìránṣẹ́ rere ti Kristi Jesu, tí a fi ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ àti ẹ̀kọ́ rere bọ́, èyí ti ìwọ ti ń tẹ̀lé.

  9. Ṣùgbọ́n kọ ọ̀rọ̀ asán àti ìtàn àwọn àgbà obìnrin, sì máa tọ́ ara rẹ sí ìwà-bí-Ọlọ́run.

  10. Má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni gan ìgbà èwe rẹ; ṣùgbọ́n kì ìwọ jẹ́ àpẹẹrẹ fún àwọn tí ó gbàgbọ́, nínú ọ̀rọ̀, nínú ìwà híhù, nínú ìfẹ́, nínú ẹ̀mí, nínú ìgbàgbọ́, nínú ìwà mímọ́.

  11. Títí èmi ó fi dé, máa fiyèsí kíkàwé àti ìgbaniníyànjú àti ìkọ́ni.

  12. Má ṣe àìnání ẹ̀bùn tí ń bẹ lára rẹ, èyí tí a fi fún ọ nípa ìsọtẹ́lẹ̀ pẹ̀lú ìgbọ́wọ́lé àwọn alàgbà.

  13. Máa fiyèsí nǹkan wọ̀nyí; fi ara rẹ fún wọn pátápátá; kí ìlọsíwájú rẹ lè hàn gbangba fún gbogbo ènìyàn.

  14. Máa ṣe ìtọ́jú ará rẹ àti ẹ̀kọ́ rẹ; máa dúró láìyẹsẹ̀ nínú nǹkan wọ̀nyí; nítorí ní ṣíṣe èyí, ìwọ ó gba ara rẹ àti tí àwọn ti ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ là.

  15. Má ṣe bá àgbàlagbà ọkùnrin wí, ṣùgbọ́n kí ó máa gbà á níyànjú bí i baba; àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin bí arákùnrin.

  16. Àwọn àgbàlagbà obìnrin bí ìyá; àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin bí arábìnrin nínú ìwà mímọ́.

  17. Bọ̀wọ̀ fún àwọn opó ti í ṣe opó nítòótọ́.

  18. Ṣùgbọ́n bí opó kan bá ni ọmọ tàbí ọmọ ọmọ, jẹ́ kí wọn kọ́kọ́ kọ́ bí a ti ń ṣe ìtọ́jú ilé àwọn tìkára wọn, kí wọn sì san oore àwọn òbí wọn padà; nítorí pé èyí ni ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà níwájú Ọlọ́run.

  19. Ǹjẹ́ ẹni ti í ṣe opó nítòótọ́, ti ó ṣe òun nìkan, a máa gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run, a sì máa dúró nínú ẹ̀bẹ̀ àti nínú àdúrà lọ́sàn àti lóru.

  20. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá fi ara rẹ fún ayé jíjẹ, ó kú nígbà tí ó wà láààyè.

  21. Nǹkan wọ̀nyí ni kí wọn máa paláṣẹ, kí wọn lè wà láìlẹ́gàn.

  22. Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni kò bá pèsè fún àwọn tirẹ̀, pàápàá fún àwọn ará ilé rẹ̀, ó ti sẹ́ ìgbàgbọ́, ó burú ju aláìgbàgbọ́ lọ.

  23. Kọ orúkọ ẹni tí kò bá dín ni ọgọ́ta ọdún sílẹ̀ bí opó, lẹ́yìn ti ó ti jẹ́ aya ọkọ kan.

  24. Ẹni ti a jẹ́rìí rẹ̀ fún iṣẹ́ rere; bí ẹni ti ó ti tọ́ ọmọ dàgbà, ti ó ń ṣe ìtọ́jú àlejò, tí ó sì ń wẹ ẹsẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́, tí ó ti ran àwọn olùpọ́njú lọ́wọ́, tí ó sì ń lépa iṣẹ́ rere gbogbo.

  25. Ṣùgbọ́n ma ṣe kọ orúkọ àwọn opó tí kò dàgbà; nítorí pé nígbà tiwọn bá ti ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ lòdì sí Kristi, wọn á tún fẹ́ láti gbéyàwó.