Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Children

257 ẹsẹ · 102 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Lẹ́yìn náà, ó gbé ọwọ́ lé wọn, ó sì kúrò níbẹ̀.

  2. Ó si wí fún wọn: “Ẹ̀yin sá à mọ̀ bí ẹ ti ń gbé òfin Ọlọ́run jù sẹ́yìn kí ẹ lè mú òfin tiyín ṣẹ.

  3. Mose fún un yín ní òfin yìí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run pé, ‘Bọ̀wọ̀ fún baba òun ìyá rẹ.’ Ó tún sọ pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀ aburú sí baba tàbí ìyá rẹ̀ ní láti kú ni.’

  4. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wá sọ pé ó dára bákan náà fún ọkùnrin kan bí kò bá tilẹ̀ pèsè fún àìní àwọn òbí rẹ̀, ṣùgbọ́n kí o sọ fún wọn pé, ‘Ẹ má ṣe bínú baba tàbí ìyá mi, n kò lè ràn yín lọ́wọ́ nísinsin yìí,’ nítorí tí mo ti fi ẹ̀bùn tí ǹ bá fi fún un yín fún Ọlọ́run.

  5. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò si jẹ́ kí ó ṣe ohunkóhun fún baba tàbí ìyá rẹ̀ mọ́.

  6. Ẹ̀yin ń fi òfin àtọwọ́dọ́wọ́ tiyín tí ẹ fi lélẹ̀, sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run di asán àti ọ̀pọ̀ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin ń ṣe.”

  7. “Ó sì wí fún un pé, nítorí ọ̀rọ̀ yìí, máa lọ, ẹ̀mí àìmọ́ náà ti jáde kúrò lára ọmọbìnrin rẹ.”

  8. Nígbà tí ó padà dé ilé, ó bá ọmọbìnrin rẹ̀ ní ìdùbúlẹ̀ jẹ́jẹ́ lórí ibùsùn, ẹ̀mí àìmọ́ náà ti fi í sílẹ̀.

  9. “Jesu sì wí fún un pé, ‘Bí ìwọ bá le gbàgbọ́: ohun gbogbo ni ó ṣe é ṣe fún ẹni tí ó bá gbàgbọ́.’ ”

  10. Lójúkan náà baba ọmọ náà kígbe ní ohùn rara, ó sì wí pé, “Olúwa, mo gbàgbọ́, ran àìgbàgbọ́ mi lọ́wọ́.”

  11. Nígbà tí Jesu rí i pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ń péjọ sọ́dọ̀ wọn, ó bá ẹ̀mí àìmọ́ náà wí pé, “Ìwọ ẹ̀mí àìmọ́, adití àti odi, mo pàṣẹ fún ọ, kí ó jáde kúrò lára ọmọ yìí, kí ó má ṣe padà sí ibẹ̀ mọ́.”

  12. Òun sì kígbe ńlá, ó sì nà án tàntàn, ó sì jáde kúrò lára rẹ̀, ọmọ náà sì dàbí ẹni tí ó kú tó bẹ́ẹ̀ tí ọ̀pọ̀ ènìyàn ké wí pé, “Hé è, ọmọ náà ti kú.”

  13. Ṣùgbọ́n Jesu fà á lọ́wọ́, ó sì ràn án lọ́wọ́ láti dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ̀. Ó dìde dúró.

  14. Ó sì mú ọmọ kékeré kan, ó fi sáàárín wọn, nígbà tí ó sì gbé e sí apá rẹ̀, ó wí fún wọn pé,

  15. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ́wọ́gbà ọmọ kékeré bí èyí ní orúkọ mi, òun gbà mí. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbà mi, ó gba Baba mi, tí ó rán mi.”

  16. Lẹ́yìn èyí, àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí í gbé àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ tọ Jesu wá kí ó lè súre fún wọn. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kígbe mọ́ àwọn tí ń gbé àwọn ọmọdé wọ̀nyí bọ̀ pé wọn kò gbọdọ̀ yọ Jesu lẹ́nu rárá.

  17. Ṣùgbọ́n nígbà tí Jesu rí ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀, inú rẹ̀ kò dùn sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Nítorí náà, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọdé kékeré wá sọ́dọ̀ mi. Ẹ má ṣe dá wọn lẹ́kun nítorí pé irú wọn ni ìjọba Ọlọ́run.

  18. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ẹnikẹ́ni tí kò bá gba ìjọba Ọlọ́run bí ọmọ kékeré, kì yóò le è wọ inú rẹ̀.”

  19. Nígbà náà, Jesu gbé àwọn ọmọ náà lé ọwọ́ rẹ̀, ó gbé ọwọ́ lé orí wọn. Ó sì súre fún wọn.

  20. Jesu sì wí pé, “Kí ni èmi ìbá fi àwọn ènìyàn ìran yìí wé? Kí ni wọ́n sì jọ?

  21. Wọ́n dàbí àwọn ọmọ kékeré tí ó jókòó ní ibi ọjà, tí wọ́n sì ń kọ sí ara wọn, tí wọ́n sì ń wí pé, “ ‘Àwa fọn fèrè fún yín, ẹ̀yin kò jó, àwa sì ṣọ̀fọ̀ fún yín, ẹ̀yin kò sọkún!’

  22. nítorí ó ní ọmọbìnrin kan ṣoṣo, ọmọ ìwọ̀n ọdún méjìlá, ti ó ń kú lọ. Bí ó sì ti ń lọ àwọn ènìyàn ko fun ni ààyè.

  23. Obìnrin kan tí ó sì ní ìsun ẹ̀jẹ̀ láti ìgbà ọdún méjìlá, tí ó ná ohun gbogbo tí ó ní fún àwọn oníṣègùn, tí kò sì sí ẹnìkan tí ó lè mú un láradá,

  24. Ó wá sí ẹ̀yìn rẹ̀, ó fi ọwọ́ tọ́ ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀; lọ́gán ni ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sì ti gbẹ.

  25. Jesu sì wí pé, “Ta ni ó fi ọwọ́ kàn mí?” Nígbà tí gbogbo wọn sẹ́ Peteru àti àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ sọ pé, “Olùkọ́, àwọn ènìyàn ko ní ààyè, wọ́n sì ń kọlù ọ́, ìwọ sì wí pé, Ta ni ó fi ọwọ́ kàn mi?”