Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Armies: Enumeration of Israel's military forces

13 ẹsẹ · 77 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Enumeration of Israel's military forces

  1. “Ka gbogbo àgbájọ ènìyàn Israẹli nípa ẹbí wọn, àti nípa ìdílé baba wọn, to orúkọ wọn olúkúlùkù ọkùnrin ní ọ̀kọ̀ọ̀kan.

  2. Ìwọ àti Aaroni ni kí ẹ kà gbogbo ọmọkùnrin Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn láti ọmọ ogún ọdún sókè, àwọn tí ó tó lọ sójú ogun.

  3. Dafidi sì ka àwọn ènìyàn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì mú wọn jẹ balógun ẹgbẹẹgbẹ̀rún, àti balógun ọ̀rọ̀ọ̀rún lórí wọn.

  4. Dafidi sì fi ìdámẹ́ta àwọn ènìyàn náà lé Joabu lọ́wọ́, ó sì rán wọn lọ, àti ìdámẹ́ta lé Abiṣai ọmọ Seruiah àbúrò Joabu lọ́wọ́ àti ìdámẹ́ta lè Ittai ará Gitti lọ́wọ́, ọba sì wí fún àwọn ènìyàn náà pé, “Nítòótọ́ èmi tìkára mi yóò sì bá yín lọ pẹ̀lú.”

  5. Ìbínú Olúwa sì ru sí Israẹli, ó sì ti Dafidi sí wọn, pé, “Lọ ka iye Israẹli àti Juda!”

  6. Ọba sì wí fún Joabu olórí ogun, tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Lọ ní ìsinsin yìí sí gbogbo ẹ̀yà Israẹli láti Dani títí dé Beerṣeba, kí ẹ sì ka iye àwọn ènìyàn, kí èmi lè mọ iye àwọn ènìyàn náà!”

  7. Joabu sì wí fún ọba pé, “Kí Olúwa Ọlọ́run rẹ fi kún iye àwọn ènìyàn náà, iyekíye tí ó wù kí wọn jẹ́, ní ọ̀rọ̀ọ̀rún, ojú olúwa mi ọba yóò sì rí i, ṣùgbọ́n èétiṣe tí olúwa mi ọba fi fẹ́ nǹkan yìí?”

  8. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ọba borí ti Joabu, àti ti àwọn olórí ogun. Joabu àti àwọn olórí ogun sì jáde lọ kúrò níwájú ọba, láti lọ ka àwọn ènìyàn Israẹli.

  9. Wọ́n sì kọjá odò Jordani, wọ́n sì pàgọ́ ní Aroeri, ní ìhà apá ọ̀tún ìlú tí ó wà láàrín àfonífojì Gadi, àti sí ìhà Jaseri.

  10. Wọ́n sì wá sí Gileadi, àti sí ilé Tatimi Hodṣi; wọ́n sì wá sí Dani Jaani àti yíkákiri sí Sidoni.

  11. Wọ́n sì wá sí ìlú olódi Tire, àti sí gbogbo ìlú àwọn Hifi, àti ti àwọn ará Kenaani, wọ́n sì jáde lọ síhà gúúsù ti Juda, àní sí Beerṣeba.

  12. Wọ́n sì la gbogbo ilẹ̀ náà já, wọ́n sì wá sí Jerusalẹmu ní òpin oṣù kẹsànán àti ogúnjọ́.

  13. Joabu sì fi iye tí àwọn ènìyàn náà jásí lé ọba lọ́wọ́. Ó sì jẹ́ ogójì ọ̀kẹ́ (800,000) ọkùnrin alágbára ní Israẹli, àwọn onídà, àwọn ọkùnrin Juda sì jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (500,000) ènìyàn.