Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Armies: Who were exempt from service in

9 ẹsẹ · 77 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Who were exempt from service in

  1. A kò ka àwọn ìdílé ẹ̀yà Lefi mọ́ àwọn ìyókù.

  2. Nítorí Olúwa ti sọ fún Mose pé,

  3. “Ìwọ kò gbọdọ̀ ka ẹ̀yà Lefi, tàbí kí o kà wọ́n mọ́ àwọn ọmọ Israẹli.

  4. Dípò èyí yan àwọn ọmọ Lefi láti jẹ́ alábojútó àgọ́ ẹ̀rí, lórí gbogbo ohun èlò àti ohun gbogbo tó jẹ́ ti àgọ́ ẹ̀rí. Àwọn ni yóò máa gbé àgọ́ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, wọn ó máa mójútó o, kí wọn ó sì máa pàgọ́ yí i ká.

  5. Àwọn olórí ogun yóò sì wí fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó kọ́ ilé tuntun tí kò sì tì ì yà á sọ́tọ̀? Jẹ́ kí ó lọ ilé, tàbí ó lè kú sójú ogun kí ẹlòmíràn sì gbà á.

  6. Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni tí ó gbin ọgbà àjàrà kan tí kò sì tí ì bẹ̀rẹ̀ sí ń gbádùn rẹ̀? Jẹ́ kí ó lọ ilé, tàbí kí ó kú sójú ogun kí ẹlòmíràn sì gbádùn rẹ̀.

  7. Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni tí ó wá ògo obìnrin kan tí kò ì tí ì fẹ́ ẹ? Jẹ́ kí ó lọ ilé, tàbí kí ó kú sójú ogun kí ẹlòmíràn sì fẹ́ ẹ.”

  8. Nígbà náà ni olórí yóò tún fi kún un pé, “Ǹjẹ́ ọkùnrin kankan ń bẹ̀rù tàbí páyà? Jẹ́ kí ó lọ ilé nítorí kí arákùnrin rẹ̀ má ba à wá tún dáyà fò ó.”

  9. Nígbà tí olórí ogun bá ti dákẹ́ ọ̀rọ̀ sísọ sí àwọn ènìyàn, wọn yóò yan olórí ogun lórí i rẹ̀.