Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Armies: Clouds

8 ẹsẹ · 77 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Clouds

  1. Ìwọ àti ọ̀wọ́ ogun rẹ àti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè pẹ̀lú rẹ yóò gòkè, ẹ̀yin yóò tẹ̀síwájú bí ìjì; ìwọ yóò dàbí ìkùùkuu tí ó bo ilẹ̀ mọ́lẹ̀.

  2. “ ‘Èyí ni Olúwa Olódùmarè wí: Ní ọjọ́ náà èrò kan yóò wá sọ́kàn rẹ, ìwọ yóò sì pète ìlànà búburú.

  3. Ìwọ yóò wí pé, “Èmi yóò gbé ogun ti ilẹ̀ àwọn tí a kò fi odi yíká, Èmi yóò gbé ogun ti àwọn ènìyàn àlàáfíà tí a kò funra sí gbogbo wọn ń gbé ní àìsí odi, ní àìsí ẹnu-ọ̀nà òde àti àsígbè-irin.

  4. Èmi yóò mú ohun ọdẹ, èmi yóò sì kó ìkógun, èmi yóò sì yí ọwọ́ mi padà sí ibi ìwólulẹ̀ ti a ti tún kọ́, àwọn ènìyàn tí a kójọpọ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè, tí ó ní ọrọ̀ nínú ẹran ọ̀sìn àti ẹrú, tí ó ń gbé ní àárín gbùngbùn ilẹ̀ náà.”

  5. Ṣeba, Dedani àti àwọn oníṣòwò Tarṣiṣi àti gbogbo àwọn ọmọ kìnnìún wọn, yóò sọ fún un yín pé, “Ṣé ẹ̀yin wá fún ìkógun? Ṣé ẹ̀yin ti kó àwọn ogun yín jọ pọ̀ fún ìkógun, láti kó fàdákà àti wúrà lọ, láti kó ẹran ọ̀sìn àti ẹrú àti láti gba ọ̀pọ̀ ìkógun?” ’ ”

  6. “Nítorí náà, ọmọ ènìyàn, sọtẹ́lẹ̀ kí ó sì sọ fún Gogu: ‘Èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Ní ọjọ́ náà, nígbà tí àwọn ènìyàn mi Israẹli ń gbé ní àìléwu, ìwọ kì yóò ha ṣe àkíyèsí rẹ̀?

  7. Ìwọ yóò wá láti ààyè rẹ ní jìnnàjìnnà àríwá, ìwọ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè pẹ̀lú rẹ, gbogbo wọn yóò sì gun ẹṣin ẹgbẹ́ ńlá, jagunjagun alágbára.

  8. Ìwọ yóò tẹ̀síwájú ní ìlòdì sí àwọn Israẹli ènìyàn mi gẹ́gẹ́ bí ìkùùkuu tí ó bo ilẹ̀. Ni àwọn ọjọ́ tí ń bọ̀, ìwọ Gogu, èmi yóò mú ọ wá ní ìlòdì sí ilẹ̀ mi, kí àwọn orílẹ̀-èdè lè mọ̀ mi nígbà tí mo bá fi ara hàn ni mímọ́ láti ọ̀dọ̀ rẹ ní ojú wọn.