Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa All Christians Should Be As Missionaries

198 ẹsẹ · 66 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nípa èyí, wọ́n yóò lè máa kọ́ àwọn ọ̀dọ́bìnrin láti nífẹ̀ẹ́ àwọn ọkọ wọn àti àwọn ọmọ wọn,

  2. láti jẹ́ ẹni ìwọ̀ntúnwọ̀nsì àti ọlọ́kàn mímọ́, kí wọ́n máa ṣe ojúṣe wọn nínú ilé, wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ onínúrere, kí wọ́n sì máa tẹríba fún àwọn ọkọ wọ́n, kí ẹnikẹ́ni máa ba à sọ̀rọ̀-òdì sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

  3. Èmi Paulu, ẹni tí a fi sẹ́wọ̀n nítorí pé ó ń wàásù ìyìnrere Jesu Kristi àti Timotiu arákùnrin wa, Sí Filemoni ọ̀rẹ́ wa ọ̀wọ́n àti alábáṣiṣẹ́ wa,

  4. sí Affia arábìnrin wa, sí Arkippu ẹni tó jẹ́ jagunjagun fún àgbélébùú náà àti sí ìjọ àwọn Kristiani tí ó ń pàdé nínú ilé rẹ:

  5. Oore-ọ̀fẹ́ fún un yín àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa àti Jesu Kristi.

  6. Èmi máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nígbà tí mo bá rántí rẹ nínú àdúrà mi,

  7. nítorí mo ń gbọ́ nípa ìgbàgbọ́ rẹ nínú Jesu Olúwa àti nípa ìfẹ́ rẹ sí àwọn ènìyàn mímọ́.

  8. Èmi ń gbàdúrà pé, bí ìwọ ti ń ṣe alábápín nínú ìgbàgbọ́ rẹ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, pé kí ìgbàgbọ́ náà lè mú ọkàn wọn dúró gbọingbọin, gẹ́gẹ́ bí wọn ti rí àwọn ọ̀rọ̀ ohun rere tí ó ń bẹ nínú ayé rẹ, èyí tí ó ti ọ̀dọ̀ Kristi wá.

  9. Ṣùgbọ́n ẹ máa gba ara yín ní ìyànjú ní ojoojúmọ́, níwọ̀n ìgbà tí a bá ń pè ní “Òní,” kí a má ba à sé ọkàn ẹnikẹ́ni nínú yín le nípa ẹ̀tàn ẹ̀ṣẹ̀.

  10. kí a ma máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀, gẹ́gẹ́ bi àṣà àwọn ẹlòmíràn; ṣùgbọ́n kí a máa gba ara ẹni níyànjú pẹ̀lúpẹ̀lú bí ẹ̀yin ti rí i pé ọjọ́ náà ń súnmọ́ etílé.

  11. Nítorí ẹ̀yin bá àwọn tí ó wà nínú ìdè kẹ́dùn, ẹ sì fi ayọ̀ gba ìkólọ ẹrù yin, nítorí ẹ̀yin mọ nínú ara yin pé, ẹ ni ọrọ̀ tí ó wà títí, tí ó sì dára jù bẹ́ẹ̀ lọ.

  12. Ẹ máa gbàdúrà fún wa, nítorí àwa gbàgbọ́ pé àwa ni ẹ̀rí ọkàn rere, a sì ń fẹ́ láti máa hùwà títọ́ nínú ohun gbogbo.

  13. Ìsìn mímọ́ àti aláìléèérí níwájú Ọlọ́run àti Baba ni èyí, láti máa bojútó àwọn aláìní baba àti àwọn opó nínú ìpọ́njú wọn, àti láti pa ara rẹ̀ mọ́ láìlábàwọ́n kúrò nínú ayé.

  14. Ẹ jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ yín fún ara yín, kí ẹ sì máa gbàdúrà fún ara yín, kí a lè mú yín láradá. Iṣẹ́ tí àdúrà olódodo ń ṣe ní agbára púpọ̀.

  15. Ará, bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá ṣìnà kúrò nínú òtítọ́, tí ẹni kan sì yí i padà;

  16. jẹ́ kí ó mọ̀ pé, ẹni tí ó bá yí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan padà kúrò nínú ìṣìnà rẹ̀, yóò gba ọkàn kan là kúrò lọ́wọ́ ikú, yóò sì bo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.

  17. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ni ìran tí a yàn olú àlùfáà, Orílẹ̀-èdè mímọ́, ènìyàn ọ̀tọ̀ ki ẹ̀yin lè fi ọláńlá ẹni tí ó pè yín jáde kúrò nínú òkùnkùn sínú ìmọ́lẹ̀ ìyanu rẹ̀ hàn.

  18. Kí ìwà yín láàrín àwọn aláìkọlà dára; pé, bí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ yín bí olùṣe búburú, nípa iṣẹ́ rere yín tí wọn ó máa kíyèsi, kí wọ́n lè máa yin Ọlọ́run lógo lọ́jọ́ ti òun ba bẹ̀ wá wò.

  19. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ẹ̀yin aya, ẹ máa tẹríba fún àwọn ọkọ yín; pé, bí ẹnikẹ́ni ba tilẹ̀ ń ṣe àìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ náà, kí a lè jèrè wọn láì sọ̀rọ̀ nípa ìwà àwọn aya wọn.

  20. Ṣùgbọ́n ẹ bọ̀wọ̀ fún Kristi bí Olúwa ní ọkàn yín: kí ẹ sì múra tan nígbà gbogbo láti dá olúkúlùkù lóhùn tí ń béèrè ìrètí tí o ń bẹ nínú yín, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ọkàn tútù àti ìbẹ̀rù.

  21. Bí olúkúlùkù ti rí ẹ̀bùn gbà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ máa ṣe ìpín fún ni rẹ̀ láàrín ara yín, bí ìríjú rere tí onírúurú oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run.

  22. Bí ẹnikẹ́ni ba ń sọ̀rọ̀, kí o máa sọ bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, bí ẹnikẹ́ni bá ń ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́, kí ó ṣe é bí agbára tí Ọlọ́run fi fún un, kí a lè máa yin Ọlọ́run lógo ní ohun gbogbo nípa Jesu Kristi, ẹni tí ògo àti ìjọba wà fún láé àti láéláé. Àmín.

  23. Tí wọn ń jẹ́rìí sí ìfẹ́ rẹ̀ níwájú ìjọ, bí ìwọ bá ń pèsè fún wọn ní ọ̀nà àjò wọn gẹ́gẹ́ bí ó tí yẹ nínú Ọlọ́run.