Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa All Christians Should Be As Missionaries: In talking of God and his works
Àwọn ẹsẹ nípa In talking of God and his works
Ahọ́n mi yóò sọ ti òdodo rẹ ní gbogbo ọjọ́, fún àwọn tí ó fẹ́ pa mí lára, a sì dójúti àwọn tí ń wá ìdààmú mi.
Èmi ṣàṣàrò lórí iṣẹ́ rẹ gbogbo, pẹ̀lú, ènìyàn sì máa sọ̀rọ̀ gbogbo iṣẹ́ agbára rẹ.
Jẹ́ kí n mọ ẹ̀kọ́ ìlànà rẹ: nígbà náà ni èmi yóò ṣe àṣàrò iṣẹ́ ìyanu rẹ.
Wọn yóò sọ ògo ìjọba rẹ wọn yóò sì sọ̀rọ̀ agbára rẹ,
kí gbogbo ènìyàn le mọ iṣẹ́ agbára rẹ̀ àti ọláńlá ìjọba rẹ tí ó lógo.