Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa All Christians Should Be As Missionaries: Philemon

6 ẹsẹ · 66 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Philemon

  1. Èmi Paulu, ẹni tí a fi sẹ́wọ̀n nítorí pé ó ń wàásù ìyìnrere Jesu Kristi àti Timotiu arákùnrin wa, Sí Filemoni ọ̀rẹ́ wa ọ̀wọ́n àti alábáṣiṣẹ́ wa,

  2. sí Affia arábìnrin wa, sí Arkippu ẹni tó jẹ́ jagunjagun fún àgbélébùú náà àti sí ìjọ àwọn Kristiani tí ó ń pàdé nínú ilé rẹ:

  3. Oore-ọ̀fẹ́ fún un yín àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa àti Jesu Kristi.

  4. Èmi máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nígbà tí mo bá rántí rẹ nínú àdúrà mi,

  5. nítorí mo ń gbọ́ nípa ìgbàgbọ́ rẹ nínú Jesu Olúwa àti nípa ìfẹ́ rẹ sí àwọn ènìyàn mímọ́.

  6. Èmi ń gbàdúrà pé, bí ìwọ ti ń ṣe alábápín nínú ìgbàgbọ́ rẹ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, pé kí ìgbàgbọ́ náà lè mú ọkàn wọn dúró gbọingbọin, gẹ́gẹ́ bí wọn ti rí àwọn ọ̀rọ̀ ohun rere tí ó ń bẹ nínú ayé rẹ, èyí tí ó ti ọ̀dọ̀ Kristi wá.