- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 1446–1406 BC
The Wilderness Years
Forty years of wandering in the desert test Israel's faith and prepare a new generation to enter the promised land.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Deuteronomi 15:11nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
A kò lè fẹ́ tálákà kù ní ilẹ̀ náà ní ìgbà gbogbo, mo pàṣẹ fún un yín láti lawọ́ sí àwọn arákùnrin yín, sí àwọn tálákà àti sí àwọn aláìní, ní ilẹ̀ ẹ yín.
- Deuteronomi 15:12nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Bí Heberu ara yín kan, yálà ọkùnrin tàbí obìnrin bá ta ara rẹ̀ fún ọ, tí ó sì sìn ọ́ fún ọdún mẹ́fà. Ní ọdún keje, jẹ́ kí ó di òmìnira.
- Deuteronomi 15:13nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Nígbà tí ó bá dá a sílẹ̀ má ṣe jẹ́ kí ó lọ lọ́wọ́ òfo.
- Deuteronomi 15:14nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Fi tọkàntọkàn fún un láti inú agbo ewúrẹ́ rẹ, ilẹ̀ ìpakà rẹ, àti ibi ìfúntí rẹ. Fún un gẹ́gẹ́ bí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti bùkún fún ọ tó.
- Deuteronomi 15:15nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Ẹ rántí pé ẹ ti fi ìgbà kan jẹ́ ẹrú ní Ejibiti, Olúwa Ọlọ́run yín sì rà yín padà, ìdí nìyí tí mo fi pa àṣẹ yìí fún un yín lónìí.
- Deuteronomi 15:16nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n bí ìránṣẹ́ rẹ bá sọ fún ọ pé, “Èmi kò fẹ́ fi ọ́ sílẹ̀,” nítorí pé ó fẹ́ràn ìwọ àti ìdílé rẹ, tí ó sì tẹ́ ọ lọ́rùn,
- Deuteronomi 15:17nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
kí ìwọ kí ó mú ìlu kan lu etí rẹ̀ mọ́ ara ìlẹ̀kùn, yóò sì di ẹrú rẹ láéláé. Bẹ́ẹ̀ náà ni kí o ṣe sí ìránṣẹ́ ẹrúbìnrin rẹ.
- Deuteronomi 15:18nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Má ṣe kà á sí ohun ìnira láti dá ẹrú rẹ sílẹ̀, nítorí ìsìnrú rẹ̀ fún ọ, ní ọdún mẹ́fà náà tó ìlọ́po méjì iṣẹ́ alágbàṣe, Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò bùkún fún ọ nínú gbogbo ìdáwọ́lé rẹ.
- Deuteronomi 15:19nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Gbogbo àkọ́bí tí o jẹ́ akọ nínú agbo màlúù rẹ ni kí o yà sọ́tọ̀ fún Olúwa, àti nínú agbo ewúrẹ́ bákan náà. Ẹ má ṣe fi àkọ́bí màlúù yín ṣiṣẹ́ rárá. Má ṣe rẹ́ irun àkọ́bí àgùntàn rẹ pẹ̀lú.
- Deuteronomi 15:20nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Ní ọdọọdún ni kí ìwọ àti ìdílé rẹ máa jẹ ẹ́ níwájú Olúwa Ọlọ́run yín níbi tí Òun yóò yàn.
- Deuteronomi 15:21nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Bí ẹran ọ̀sìn kan bá ní àbùkù: bóyá ó yarọ, tàbí fọ́jú, tàbí tí ó ní èyíkéyìí àbùkù tó burú. Ẹ kò gbọdọ̀ fi rú ẹbọ sí Olúwa Ọlọ́run yín.
- Deuteronomi 15:22nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Ẹ jẹ ẹ́ ní ìlú u yín. Àti ẹni tí a kà sí mímọ́ àti aláìmọ́ ni ó lè jẹ ẹ́ bí ìgbà tí a ń jẹ èsúró tàbí àgbọ̀nrín.
- Deuteronomi 15:23nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀, ẹ dà á síta bí omi.
- Deuteronomi 16:1nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Ẹ kíyèsi oṣù Abibu, kí ẹ sì máa ṣe àjọ̀dún ìrékọjá ti Olúwa Ọlọ́run yín, nítorí pé ní oṣù Abibu yìí ni ó mú un yín jáde ní Ejibiti lóru.
- Deuteronomi 16:2nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Ẹ fi ẹran kan rú ẹbọ bí ìrékọjá sí Olúwa Ọlọ́run yín láti inú ọ̀wọ́ ẹran tàbí agbo màlúù yín ní ibi tí Olúwa Ọlọ́run yín yóò yàn bí ibùgbé fún orúkọ rẹ̀.
- Deuteronomi 16:3nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Ẹ má ṣe jẹ ẹ́ pẹ̀lú u àkàrà tí a fi ìwúkàrà ṣe, ṣùgbọ́n ọjọ́ méje ni kí ẹ fi jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà, àkàrà ìpọ́njú, nítorí pé pẹ̀lú ìkánjú ni ẹ kúrò ní Ejibiti: kí ẹ bá à lè rántí ìgbà tí ẹ kúrò ní Ejibiti ní gbogbo ọjọ́ ayé yín.
- Deuteronomi 16:4nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Kí a má sì ṣe rí àkàrà wíwú ní ọ̀dọ̀ rẹ nínú ilẹ̀ rẹ ní ijọ́ méje. Kí ìwọ má ṣe jẹ́ kí nǹkan kan ṣẹ́kù nínú ẹran tí ìwọ ó fi rú ẹbọ ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kìn-ín-ní di àárọ̀ ọjọ́ kejì.
- Deuteronomi 16:5nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe ìrékọjá náà ní ìlúkílùú kankan, tí Olúwa Ọlọ́run yín fi fún un yín
- Deuteronomi 16:6nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
bí kò ṣe ibi tí yóò yàn gẹ́gẹ́ bí ibùgbé fún orúkọ rẹ̀, níbẹ̀ ni ki ẹ ti ṣe ìrúbọ ìrékọjá náà ní ìrọ̀lẹ́ nígbà tí oòrùn bá ń wọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìrántí ìgbà tí ẹ kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti.
- Deuteronomi 16:7nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Ẹ sun ún kí ẹ sì jẹ ẹ́ ní ibi tí Olúwa Ọlọ́run yín yóò yàn. Ní àárọ̀, kí ẹ padà sí àgọ́ ọ yín.
- Deuteronomi 16:8nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Ọjọ́ mẹ́fà ní kí ẹ fi jẹ àkàrà aláìwú, ní ọjọ́ keje, ẹ pe àjọ kan fún Olúwa Ọlọ́run yín, kí ẹ má sì ṣe iṣẹ́ kankan.
- Deuteronomi 16:9nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Ka ọ̀sẹ̀ méje láti ìgbà tí ẹ bá ti bẹ̀rẹ̀ sí fi dòjé ṣe ìkórè ọkà.
- Deuteronomi 16:10nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni kí ẹ ṣe àjọ ọ̀sẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run yín, nípa pípèsè ọrẹ àtinúwá, gẹ́gẹ́ bí ìbùkún tí Olúwa Ọlọ́run yín fún un yín.
- Deuteronomi 16:11nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú Olúwa Ọlọ́run yín ní ibi tí yóò yàn ní ibùgbé fún orúkọ rẹ̀: ẹ̀yin, àwọn ọmọ yín ọkùnrin àti àwọn ọmọ yín obìnrin, àwọn ẹrú yín ọkùnrin àti àwọn ẹrú yín obìnrin, àwọn Lefi tí ó wà ní ìlú yín, àti àwọn àjèjì, àwọn aláìní baba, àti àwọn opó tí ń gbé àárín yín.
- Deuteronomi 16:12nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi
Ẹ rántí pé, ẹ ti jẹ́ ẹrú ní Ejibiti rí, nítorí náà ẹ tẹ̀lé àwọn ìlànà wọ̀nyí dáradára.