Fò sí àkóónú

circa 1446–1406 BC

The Wilderness Years

Forty years of wandering in the desert test Israel's faith and prepare a new generation to enter the promised land.

2,247 ẹsẹ · 2 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Deuteronomi 17:16nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Síwájú sí i, ọba náà kò gbọdọ̀ kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹṣin jọ fún ara rẹ̀, tàbí kí ó rán àwọn ènìyàn náà padà sí Ejibiti láti wá àwọn ẹṣin sí i, nítorí pé Olúwa ti sọ fún un yín pé, “Ẹ kò gbọdọ̀ tún padà lọ ní ọ̀nà náà mọ́.”

  2. Deuteronomi 17:17nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Kò gbọdọ̀ kó aya jọ, kí ọkàn rẹ̀ má bá a yapa kúrò. Kò gbọdọ̀ kó fàdákà àti wúrà jọ fún ara rẹ̀ lọ́pọ̀lọ́pọ̀.

  3. Deuteronomi 17:18nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí ó bá jókòó lórí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀, kí ó ṣe àdàkọ àwọn òfin wọ̀nyí sí inú ìwé fún ara rẹ̀, láti inú ti àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Lefi.

  4. Deuteronomi 17:19nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Èyí yóò sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀, òun ó sì máa kà nínú rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, kí ó lè máa kọ́ àti bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, láti máa tẹ̀lé gbogbo ọ̀rọ̀ inú òfin yìí àti àwọn ìlànà rẹ̀ tọkàntọkàn.

  5. Deuteronomi 17:20nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Kí ó má ba à lérò pé òun sàn ju àwọn arákùnrin rẹ̀ yòókù lọ, kí ó sì ti ipa bẹ́ẹ̀ yípadà kúrò nínú òfin wọ̀nyí sí ọ̀tún tàbí sí òsì. Bẹ́ẹ̀ ni òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò jẹ ọba pẹ́ títí ní Israẹli.

  6. Deuteronomi 18:1nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Lefi, àní gbogbo ẹ̀yà Lefi, wọn kì yóò ní ìpín tàbí ogún láàrín Israẹli, wọn yóò máa jẹ nínú ọrẹ ẹbọ tí a fi iná ṣe sí Olúwa, nítorí òun ni ogún un tiwọn.

  7. Deuteronomi 18:2nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Wọn kì yóò ní ìní láàrín àwọn arákùnrin wọn; Olúwa ni yóò jẹ́ ìní i tiwọn, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìlérí fún wọn.

  8. Deuteronomi 18:3nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Gbogbo èyí ni yóò jẹ́ ìpín àwọn àlùfáà láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tí ó fi akọ màlúù tàbí àgùntàn rú ẹbọ; wọn yóò fi èjìká àti ẹ̀rẹ̀kẹ́ méjèèjì àti gbogbo inú fún àlùfáà.

  9. Deuteronomi 18:4nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Àkọ́so irúgbìn ọkà rẹ, ti wáìnì àti ti òróró rẹ, àti àkọ́rẹ́ irun àgùntàn rẹ ni ìwọ yóò fi fún wọn.

  10. Deuteronomi 18:5nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti yàn wọ́n àti àwọn ọmọ wọn láti inú gbogbo ẹ̀yà láti dúró àti láti ṣe ìránṣẹ́ ní orúkọ Olúwa títí láé.

  11. Deuteronomi 18:6nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Tí ọmọ Lefi kan bá sì wá láti ibikíbi nínú àwọn ìlú u yín ní Israẹli, níbi tí ó ń gbé ṣe àtìpó, tí ó sì wá gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀ sí ibi tí Olúwa yóò yàn.

  12. Deuteronomi 18:7nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni ó lè máa ṣe ìránṣẹ́ ní orúkọ Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Lefi arákùnrin rẹ̀ ti ń dúró ṣe iṣẹ́ ìsìn níwájú Olúwa níbẹ̀.

  13. Deuteronomi 18:8nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Wọn yóò ní ìpín kan láti jẹ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti gba owó nípa títa ogún baba rẹ̀.

  14. Deuteronomi 18:9nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí o bá wọ ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò fi fún ọ, ìwọ kò gbọdọ̀ kọ́ láti tẹ̀lé àwọn ọ̀nà ìríra àwọn orílẹ̀-èdè náà tí ó wà níbẹ̀.

  15. Deuteronomi 18:10nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Má ṣe jẹ́ kí a rí ẹnikẹ́ni láàrín yín tí ó fi ọmọ rẹ̀ ọkùnrin tàbí ọmọ rẹ̀ obìnrin la iná já (fi ọmọ rẹ rú ẹbọ) kí ẹnikẹ́ni má ṣe lọ fọ àfọ̀ṣẹ, tàbí ṣẹ́ oṣó, tàbí túmọ̀ àwọn àmì nǹkan tí ń bọ̀, tàbí àjẹ́,

  16. Deuteronomi 18:11nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    tàbí afògèdè, tàbí jẹ́ a bá iwin gbìmọ̀ tàbí oṣó tàbí abókùúsọ̀rọ̀.

  17. Deuteronomi 18:12nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Ẹnikẹ́ni tó bá ṣe nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ìríra sí Olúwa, àti nítorí àwọn ìwà ìríra wọ̀nyí ni Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò fi lé àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí jáde kúrò níwájú rẹ.

  18. Deuteronomi 18:13nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    O ní láti jẹ́ aláìlẹ́gàn níwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ.

  19. Deuteronomi 18:14nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Àwọn orílẹ̀-èdè tí ìwọ yóò gba ilẹ̀ tí wọ́n ń gbé, wọ́n fetí sí tí àwọn tí ó ń ṣe oṣó tàbí ṣe àfọ̀ṣẹ. Ṣùgbọ́n, ní ti ìwọ, Olúwa Ọlọ́run rẹ kò fi ààyè gbà ọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀.

  20. Deuteronomi 18:15nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò gbé wòlíì kan dìde gẹ́gẹ́ bí èmi láàrín àwọn arákùnrin rẹ. Tìrẹ ni kí o gbọ́.

  21. Deuteronomi 18:16nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Nítorí èyí ni ohun tí ìwọ béèrè lọ́wọ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ ní Horebu ní ọjọ́ àjọ, nígbà tí ìwọ wí pé, “Kí àwa má ṣe gbọ́ ohùn Olúwa Ọlọ́run wa tàbí rí iná ńlá yìí mọ́. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ àwa yóò kú.”

  22. Deuteronomi 18:17nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Olúwa sì wí fún mi pé, “Ohun tí wọ́n sọ dára.

  23. Deuteronomi 18:18nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Èmi yóò gbé wòlíì kan dìde fún wọn láàrín àwọn arákùnrin wọn bí ìwọ, Èmi yóò fi ọ̀rọ̀ mi sí i ní ẹnu, yóò sì sọ fún wọn gbogbo ohun tí mo ti paláṣẹ fún un.

  24. Deuteronomi 18:19nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Ẹnikẹ́ni tí kò bá sì tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ mi tí wòlíì náà yóò sọ ní orúkọ mi, èmi fúnra à mi yóò sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.

  25. Deuteronomi 18:20nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n bí wòlíì kan bá kùgbù sọ ọ̀rọ̀ kan tí èmi kò paláṣẹ fún un láti sọ ní orúkọ mi tàbí wòlíì tí ó sọ̀rọ̀ ní orúkọ ọlọ́run mìíràn, irú wòlíì bẹ́ẹ̀ ní láti kú.”