Fò sí àkóónú

circa 1446–1406 BC

The Wilderness Years

Forty years of wandering in the desert test Israel's faith and prepare a new generation to enter the promised land.

2,247 ẹsẹ · 2 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Numeri 16:11nǹkan bí 1471 ṣáájú Kristi

    Olúwa ni ìwọ àti gbogbo ẹlẹgbẹ́ rẹ takò. Ta a ni Aaroni jẹ́ tí ẹ̀yin ó fi kùn sí i?”

  2. Numeri 16:12nǹkan bí 1471 ṣáájú Kristi

    Mose sì ránṣẹ́ sí Datani àti Abiramu àwọn ọmọ Eliabu. Ṣùgbọ́n wọ́n wí pé, “Àwa kò ní í wá!

  3. Numeri 16:13nǹkan bí 1471 ṣáájú Kristi

    Kò ha tó gẹ́ẹ́ pé o ti mú wa jáde láti ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin láti pa wá sínú aginjù yìí? O tún wá fẹ́ sọ ara rẹ di olúwa lé wa lórí bí?

  4. Numeri 16:14nǹkan bí 1471 ṣáájú Kristi

    Síbẹ̀síbẹ̀ ìwọ kò sì tí ì mú wa dé ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin, bẹ́ẹ̀ ni o kò sì pín ilẹ̀ ìní àti ọgbà àjàrà. Ìwọ ha fẹ́ sọ wá di ẹrú bí? Rárá o, àwa kì yóò gòkè wá!”

  5. Numeri 16:15nǹkan bí 1471 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni Mose bínú gidigidi, ó sì sọ fún Olúwa pé, “Má ṣe gba ọrẹ wọn, èmi kò gba kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ lọ́wọ́ wọn, bẹ́ẹ̀ ni n kò sì pa ẹnikẹ́ni nínú wọn lára!”

  6. Numeri 16:16nǹkan bí 1471 ṣáájú Kristi

    Mose sọ fún Kora pé, “Ìwọ àti ọmọ lẹ́yìn rẹ gbọdọ̀ fi ara hàn níwájú Olúwa lọ́la—gbogbo yín, ìwọ, àwọn ọmọ lẹ́yìn rẹ àti Aaroni.

  7. Numeri 16:17nǹkan bí 1471 ṣáájú Kristi

    Kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín mú àwo tùràrí, kí ó sì fi tùràrí sínú rẹ̀, kí gbogbo rẹ̀ jẹ́ àádọ́ta lé nígba (250) àwo tùràrí kí ẹ sì ko wá síwájú Olúwa. Ìwọ àti Aaroni yóò mú àwo tùràrí wá pẹ̀lú.”

  8. Numeri 16:18nǹkan bí 1471 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni oníkálùkù wọn mú àwo tùràrí, wọ́n fi iná àti tùràrí sí i nínú, wọ́n sì dúró sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, àwọn pẹ̀lú Mose àti Aaroni.

  9. Numeri 16:19nǹkan bí 1471 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí Kora kó gbogbo àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ jọ sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, ògo Olúwa sì farahan gbogbo ìjọ ènìyàn.

  10. Numeri 16:20nǹkan bí 1471 ṣáájú Kristi

    Olúwa sì sọ fún Mose àti Aaroni pé,

  11. Numeri 16:21nǹkan bí 1471 ṣáájú Kristi

    “Ẹ ya ara yín sọ́tọ̀ kúrò láàrín ìjọ wọ̀nyí, kí ń ba à le pa wọ́n run lẹ́ẹ̀kan náà.”

  12. Numeri 16:22nǹkan bí 1471 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n Mose àti Aaroni dojúbolẹ̀ wọ́n sì kígbe sókè pé, “Ọlọ́run, Ọlọ́run ẹ̀mí gbogbo ènìyàn, Ìwọ ó wa bínú sí gbogbo ìjọ ènìyàn nígbà tó jẹ́ pé ẹnìkan ló ṣẹ̀?”

  13. Numeri 16:23nǹkan bí 1471 ṣáájú Kristi

    Olúwa tún sọ fún Mose pé,

  14. Numeri 16:24nǹkan bí 1471 ṣáájú Kristi

    “Sọ fún ìjọ ènìyàn pé, ‘Kí wọ́n jìnnà sí àgọ́ Kora, Datani àti Abiramu.’ ”

  15. Numeri 16:25nǹkan bí 1471 ṣáájú Kristi

    Mose sì dìde lọ bá Datani àti Abiramu àwọn àgbàgbà Israẹli sì tẹ̀lé.

  16. Numeri 16:26nǹkan bí 1471 ṣáájú Kristi

    Ó sì kìlọ̀ fún ìjọ ènìyàn pé, “Ẹ kúrò ní àgọ́ àwọn ènìyàn búburú yìí! Ẹ má ṣe fọwọ́ kan ohun kan tí í ṣe tiwọn kí ẹ má ba à parun nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”

  17. Numeri 16:27nǹkan bí 1471 ṣáájú Kristi

    Àwọn ènìyàn sì sún kúrò ní àgọ́ Kora, Datani àti Abiramu. Datani àti Abiramu jáde, àwọn ìyàwó wọn àti àwọn ọmọ wọn sì dúró sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ wọn.

  18. Numeri 16:28nǹkan bí 1471 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni Mose wí pé, “Báyìí ni ẹ ó ṣe mọ̀ pé Olúwa ló rán mi láti ṣe gbogbo iṣẹ́ wọ̀nyí àti pé kì í ṣe ìfẹ́ inú mi ni àwọn ohun tí mò ń ṣe.

  19. Numeri 16:29nǹkan bí 1471 ṣáájú Kristi

    Bí àwọn ènìyàn yìí bá kú bí gbogbo ènìyàn ti ń kú, bí ìrírí wọn kò bá sì yàtọ̀ sí ti àwọn ènìyàn yòókù, a jẹ́ pé kì í ṣe Olúwa ló rán mi.

  20. Numeri 16:30nǹkan bí 1471 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n bí Olúwa bá ṣe ohun tuntun, tí ilẹ̀ sì la ẹnu, tó gbé wọn mì, àwọn pẹ̀lú gbogbo ohun tí wọ́n ní, tí wọ́n sì wọ inú ibojì wọn lọ láààyè, nígbà náà ni ẹ̀yin ó mọ̀ pé àwọn ènìyàn yìí ti kẹ́gàn Olúwa.”

  21. Numeri 16:31nǹkan bí 1471 ṣáájú Kristi

    Bí ó sì ṣe parí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ilẹ̀ pín sí méjì nísàlẹ̀ wọn,

  22. Numeri 16:32nǹkan bí 1471 ṣáájú Kristi

    ilẹ̀ sì lanu ó sì gbé wọn mì pẹ̀lú gbogbo ará ilé wọn àti àwọn ènìyàn Kora àti gbogbo ohun tí wọ́n ní.

  23. Numeri 16:33nǹkan bí 1471 ṣáájú Kristi

    Gbogbo wọn sì sọ̀kalẹ̀ sínú ibojì wọn láààyè pẹ̀lú ohun gbogbo tí wọ́n ní, ilẹ̀ sì padé mọ́ wọn, wọ́n sì ṣègbé kúrò láàrín ìjọ ènìyàn.

  24. Numeri 16:34nǹkan bí 1471 ṣáájú Kristi

    Gbogbo ènìyàn Israẹli tí ó yí wọn ká sì sálọ tí àwọn yòókù gbọ́ igbe wọn, wọ́n wí pé, “Ilẹ̀ yóò gbé àwa náà mì pẹ̀lú.”

  25. Numeri 16:35nǹkan bí 1471 ṣáájú Kristi

    Iná sì jáde láti ọ̀dọ̀ Olúwa ó sì run àádọ́ta lé nígba (250) ọkùnrin tí wọ́n mú tùràrí wá.