circa 6 BC – AD 30
The Life of Jesus
The eternal Son of God enters history: born in Bethlehem, baptized in the Jordan, crucified at Golgotha, raised on the third day.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Luku 7:50nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi
Ó sì dáhùn wí fún obìnrin náà pé, “Ìgbàgbọ́ rẹ gbà ọ́ là, máa lọ ní àlàáfíà.”
- Luku 8:1nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi
Ó sì ṣe lẹ́yìn náà, tí ó ń lá gbogbo ìlú àti ìletò kọjá lọ, ó ń wàásù, ó ń ròyìn ayọ̀ ìjọba Ọlọ́run. Àwọn méjìlá sì ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀,
- Luku 8:2nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi
àti àwọn obìnrin kan, tí a ti mú láradá kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹ̀mí búburú àti nínú àìlera wọn, Maria tí a ń pè ní Magdalene, lára ẹni tí ẹ̀mí èṣù méje ti jáde kúrò.
- Luku 8:3nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi
Àti Joanna aya Kusa tí í ṣe ìríjú Herodu, àti Susana, àti àwọn púpọ̀ mìíràn, tí wọ́n ń ṣe ìránṣẹ́ fún un nínú ohun ìní wọn.
- Luku 8:4nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi
Nígbà tí ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn péjọpọ̀, àwọn ènìyàn láti ìlú gbogbo sì tọ̀ ọ́ wá, ó fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀ pé,
- Luku 8:5nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi
“Afúnrúgbìn kan jáde lọ láti fún irúgbìn rẹ̀: bí ó sì ti ń fúnrúgbìn, díẹ̀ bọ́ sí ẹ̀bá ọ̀nà, a sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ṣà á jẹ.
- Luku 8:6nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi
Òmíràn sì bọ́ sórí àpáta; bí ó sì ti hù jáde, ó gbẹ nítorí tí kò ní omi.
- Luku 8:7nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi
Òmíràn sì bọ́ sínú ẹ̀gún; ẹ̀gún sì dàgbà pẹ̀lú rẹ̀ sókè, ó sì fún un pa.
- Luku 8:8nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi
Òmíràn sì bọ́ sí ilẹ̀ rere, ó sì hù sókè, ó sì so èso ọ̀rọ̀ọ̀rún ju èyí ti a gbin lọ.” Nígbà tí ó sì wí nǹkan wọ̀nyí tán, ó pariwo sókè pé, “Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́, kí ó gbọ́!”
- Luku 8:9nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi
Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì bi í léèrè, pé, “Kí ni a lè mọ òwe yìí sí?”
- Luku 8:10nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi
Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ni a fi fún láti mọ ohun ìjìnlẹ̀ ìjọba Ọlọ́run; ṣùgbọ́n fún àwọn ẹlòmíràn wọn yóò jẹ́ òwe, pé ní rí rí, “ ‘kí wọn má ba à rí, àti ní gbígbọ́ kí ó má lè yé wọn.’
- Luku 8:11nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi
“Ǹjẹ́ òwe náà ni èyí: irúgbìn ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
- Luku 8:12nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi
Àwọn ti ẹ̀bá ọ̀nà ni àwọn tí ó gbọ́ nígbà náà ni èṣù wá ó sì mú ọ̀rọ̀ náà kúrò ní ọkàn wọn, kí wọn má ba à gbàgbọ́, kí a sì gbà wọ́n là.
- Luku 8:13nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi
Àwọn ti orí àpáta ni àwọn, tí wọ́n gbọ́, wọ́n fi ayọ̀ gba ọ̀rọ̀ náà, àwọn wọ̀nyí kò sì ní gbòǹgbò, wọ́n á gbàgbọ́ fún sá à díẹ̀; nígbà ìdánwò, wọn á padà sẹ́yìn.
- Luku 8:14nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi
Àwọn tí ó bọ́ sínú ẹ̀gún ni àwọn, tí wọ́n gbọ́ tán, wọ́n ti n lọ, wọn a sì fi ìtọ́jú àti ọrọ̀ àti ìrora ayé fún un pa, wọn kò sì lè so èso àsogbó.
- Luku 8:15nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n ti ilẹ̀ rere ni àwọn tí wọ́n fi ọkàn òtítọ́ àti rere gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, wọ́n dìímú ṣinṣin, wọ́n sì fi sùúrù so èso.
- Luku 8:16nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi
“Kò sí ẹnikẹ́ni, nígbà tí ó bá tán fìtílà tan, tí yóò fi ohun èlò bò ó mọ́lẹ̀, tàbí tí yóò gbé e sábẹ́ àkéte; bí kò ṣe kí ó gbé e ka orí ọ̀pá fìtílà, kí àwọn tí ń wọ ilé lè rí ìmọ́lẹ̀.
- Luku 8:17nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi
Nítorí kò sí ohun tí ó fi ara sin, tí a kì yóò fihàn, tàbí ohun tí a fi pamọ́, ti a kì yóò sì mọ̀ kí ó sì yọ sí gbangba.
- Luku 8:18nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi
Ǹjẹ́ kí ẹ̀yin máa kíyèsára bí ẹ̀yin ti ń gbọ́: nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá ní, lọ́wọ́ rẹ̀ ni a ó sì gba èyí tí ó ṣe bí òun ní.”
- Luku 8:19nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi
Nígbà náà ní ìyá rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọn kò sì lè súnmọ́ ọn nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn.
- Luku 8:20nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi
Wọ́n sì wí fún un pé, “Ìyá rẹ àti àwọn arákùnrin rẹ dúró lóde, wọn fẹ́ rí ọ.”
- Luku 8:21nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi
Ó sì dáhùn wí fún wọn pé, “Ìyá mi àti àwọn arákùnrin mi ni àwọn wọ̀nyí tí wọ́n ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń ṣe é.”
- Luku 8:22nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi
Ní ọjọ́ kan, ó sì wọ ọkọ̀ ojú omi kan lọ òun pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. O sì wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí a rékọjá lọ sí ìhà kejì adágún.” Wọ́n sì ṣíkọ̀ láti lọ.
- Luku 8:23nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi
Bí wọ́n sì ti ń lọ, ó sùn; ìjì ńlá sì dé, ó ń fẹ́ lójú adágún; omi si wọ inú ọkọ, wọ́n sì wà nínú ewu.
- Luku 8:24nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi
Wọ́n sì tọ̀ ọ́ wá wọ́n sì jí i, wí pé, “Olùkọ́, Olùkọ́, àwa yóò ṣègbé!” Nígbà náà ni ó dìde, ó sì bá ìjì líle àti ríru omi wí; wọ́n sì dúró, ìdákẹ́rọ́rọ́ sì dé.