Fò sí àkóónú

circa 6 BC – AD 30

The Life of Jesus

The eternal Son of God enters history: born in Bethlehem, baptized in the Jordan, crucified at Golgotha, raised on the third day.

3,779 ẹsẹ · 4 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Luku 7:25nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n kín ni ẹ̀yin jáde lọ wò? Ọkùnrin tí a wọ̀ ní aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́? Wò ó, àwọn tí á wọ̀ ní aṣọ ògo, tí wọ́n sì ń jayé, ń bẹ ní ààfin ọba!

  2. Luku 7:26nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n kí ni ẹ̀yin jáde lọ wò? Wòlíì? Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ó sì ju wòlíì lọ!

  3. Luku 7:27nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Èyí yìí ni ẹni tí a ti kọ̀wé nítorí rẹ̀ pé: “ ‘Wò ó, èmi yóò rán oníṣẹ́ mi síwájú rẹ; ẹni tí yóò tún ọ̀nà rẹ ṣe níwájú rẹ.’

  4. Luku 7:28nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Mo wí fún yín nínú àwọn tí a bí nínú obìnrin, kò sí wòlíì tí ó pọ̀ ju Johanu Onítẹ̀bọmi lọ, ṣùgbọ́n ẹni tí ó kéré jùlọ ní ìjọba Ọlọ́run, ó pọ̀jù ú lọ.”

  5. Luku 7:29nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    (Gbogbo àwọn ènìyàn tí ó gbọ́ àti àwọn agbowó òde, wọ́n dá Ọlọ́run láre, nítorí tí a fi ìtẹ̀bọmi Johanu tẹ̀ wọn bọ mi.

  6. Luku 7:30nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n àwọn Farisi àti àwọn amòfin kọ ète Ọlọ́run fún ara wọn, a kò bamitiisi wọn lọ́dọ̀ rẹ̀.)

  7. Luku 7:31nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Jesu sì wí pé, “Kí ni èmi ìbá fi àwọn ènìyàn ìran yìí wé? Kí ni wọ́n sì jọ?

  8. Luku 7:32nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Wọ́n dàbí àwọn ọmọ kékeré tí ó jókòó ní ibi ọjà, tí wọ́n sì ń kọ sí ara wọn, tí wọ́n sì ń wí pé, “ ‘Àwa fọn fèrè fún yín, ẹ̀yin kò jó, àwa sì ṣọ̀fọ̀ fún yín, ẹ̀yin kò sọkún!’

  9. Luku 7:33nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí Johanu Onítẹ̀bọmi wá, kò jẹ àkàrà, bẹ́ẹ̀ ni kò sì mu ọtí wáìnì, ẹ̀yin sì wí pé, ‘Ó ní ẹ̀mí èṣù?’

  10. Luku 7:34nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Ọmọ ènìyàn dé, ó ń jẹ, ó sì ń mu, ẹ̀yin sì wí pé, ‘Wò ó, ọ̀jẹun, àti ọ̀mùtí, ọ̀rẹ́ àwọn agbowó òde àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀!’

  11. Luku 7:35nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n ọgbọ́n ni a dá láre nípasẹ̀ ọmọ rẹ.”

  12. Luku 7:36nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Farisi kan sì rọ̀ ọ́ kí ó wá bá òun jẹun, ó sì wọ ilé Farisi náà lọ ó sì jókòó láti jẹun.

  13. Luku 7:37nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Sì kíyèsi i, obìnrin kan wà ní ìlú náà, ẹni tí i ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀, nígbà tí ó mọ̀ pé Jesu jókòó, ó ń jẹun ní ilé Farisi, ó mú ṣágo kékeré alabasita òróró ìkunra wá,

  14. Luku 7:38nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì dúró tì í lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀ lẹ́yìn, ó ń sọkún, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí i fi omijé wẹ̀ ẹ́ ní ẹsẹ̀, ó sì ń fi irun orí rẹ nù ún nù, ó sì ń fi ẹnu kò ó ní ẹsẹ̀, ó sì ń fi òróró kùn wọ́n.

  15. Luku 7:39nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí Farisi tí ó pè é sì rí i, ó wí nínú ara rẹ̀ pé, “Ọkùnrin yìí ìbá ṣe wòlíì, ìbá mọ ẹni àti irú ẹni tí obìnrin yìí jẹ́ tí ń fi ọwọ́ kàn an, nítorí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni.”

  16. Luku 7:40nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Jesu sì dáhùn, ó wí fún un pé, “Simoni, Mo ní ohun kan sọ fún ọ.” Ó sì dáhùn pé, “Olùkọ́ máa wí.”

  17. Luku 7:41nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    “Ayánilówó kan wà tí ó ní ajigbèsè méjì: ọ̀kan jẹ ẹ́ ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) owó idẹ, èkejì sì jẹ ẹ́ ní àádọ́ta.

  18. Luku 7:42nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí wọn kò sì ní ohun tí wọn ó san, ó dáríjì àwọn méjèèjì. Wí nínú àwọn méjèèjì, ta ni yóò fẹ́ ẹ jù?”

  19. Luku 7:43nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Simoni dáhùn wí pé, “Mo ṣe bí ẹni tí ó dáríjì jù ni.” Jesu wí fún un pé, “Ìwọ ti dájọ́ náà dáradára.”

  20. Luku 7:44nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì yípadà sí obìnrin náà, ó wí fún Simoni pé, “Wo obìnrin yìí? Èmi wọ ilé rẹ, ìwọ kò fi omi wẹ ẹsẹ̀ fún mi: ṣùgbọ́n, omijé rẹ̀ ni ó fi ń rọ̀jò sí mi lẹ́sẹ̀ irun orí ni ó fi ń nù wọ́n nù.

  21. Luku 7:45nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Ìwọ kò fi ìfẹnukonu fún mi: ṣùgbọ́n òun, nígbà tí mo ti wọ ilé, kò dẹ́kun ẹnu fífi kò mí lẹ́sẹ̀.

  22. Luku 7:46nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Ìwọ kò fi òróró pa mí lórí, ṣùgbọ́n òun ti fi òróró pa mí lẹ́sẹ̀.

  23. Luku 7:47nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Ǹjẹ́ mo wí fún ọ, A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tí ó pọ̀ jì í: nítorí tí ó ní ìfẹ́ púpọ̀: ẹni tí a sì dárí díẹ̀ jì, òun náà ni ó ní ìfẹ́ díẹ̀.”

  24. Luku 7:48nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì wí fún un pé, “A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́!”

  25. Luku 7:49nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Àwọn tí ó bá a jókòó jẹun sì bẹ̀rẹ̀ sí í rò nínú ara wọn pé, “Ta ni èyí tí ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji ni pẹ̀lú?”