Fò sí àkóónú

circa 6 BC – AD 30

The Life of Jesus

The eternal Son of God enters history: born in Bethlehem, baptized in the Jordan, crucified at Golgotha, raised on the third day.

3,779 ẹsẹ · 4 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Luku 6:49nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́, tí kò sì ṣe é, ó dàbí ọkùnrin tí ó kọ́ ilé sí orí ilẹ̀ láìní ìpìlẹ̀; nígbà tí ìgbì omi kọlù ú, lọ́gán, ó sì wó; wíwó ilé náà sì pọ̀ púpọ̀.”

  2. Luku 7:1nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí ó sì parí gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀ fun àwọn ènìyàn, ó wọ Kapernaumu lọ.

  3. Luku 7:2nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Ọmọ ọ̀dọ̀ balógun ọ̀rún kan, tí ó ṣọ̀wọ́n fún un, ṣàìsàn, ó sì ń kú lọ.

  4. Luku 7:3nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí ó sì gbúròó Jesu, ó rán àwọn àgbàgbà Júù sí i, ó ń bẹ̀ ẹ́ pé kí ó wá mú ọmọ ọ̀dọ̀ òun láradá.

  5. Luku 7:4nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí wọ́n sì dé ọ̀dọ̀ Jesu, wọ́n fi ìtara bẹ̀ ẹ́, pé, “Ó yẹ ní ẹni tí òun ìbá ṣe èyí fún.

  6. Luku 7:5nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí tí ó fẹ́ràn orílẹ̀-èdè wa, ó sì ti kọ́ Sinagọgu kan fún wa.”

  7. Luku 7:6nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Jesu sì ń bá wọn lọ. Nígbà tí kò sì jìn sí etí ilé mọ́, balógun ọ̀rún náà rán àwọn ọ̀rẹ́ sí i, pé, “Olúwa, má ṣe yọ ara rẹ lẹ́nu, nítorí tí èmi kò yẹ tí ìwọ ìbá fi wọ abẹ́ òrùlé mi.

  8. Luku 7:7nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà èmi kò sì rò pé èmi náà yẹ láti tọ̀ ọ́ wá, ṣùgbọ́n sọ ní gbólóhùn kan, a ó sì mú ọmọ ọ̀dọ̀ mi láradá.

  9. Luku 7:8nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí èmi náà pẹ̀lú jẹ́ ẹni tí a fi sí abẹ́ àṣẹ, tí ó ní ọmọ-ogun lẹ́yìn mi, mo sì wí fún ọ̀kan pé, ‘Lọ,’ a sì lọ; àti fún òmíràn pé, ‘Wá,’ a sì wá; àti fún ọmọ ọ̀dọ̀ mi pé, ‘Ṣe èyí,’ a sì ṣe é.”

  10. Luku 7:9nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí Jesu gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, ẹnu sì yà, ó sì yípadà sí ìjọ ènìyàn tí ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ó wí pé, “Mo wí fún yín pé èmi kò rí irú ìgbàgbọ́ ńlá bí èyí nínú àwọn ènìyàn Israẹli.”

  11. Luku 7:10nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí àwọn oníṣẹ́ sì padà sí ilé, wọ́n bá ọmọ ọ̀dọ̀ náà tí ń ṣàìsàn, ara rẹ̀ ti dá.

  12. Luku 7:11nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Ní ọjọ́ kejì, ó lọ sí ìlú kan tí a ń pè ní Naini, àwọn púpọ̀ nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì ń bá a lọ àti ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn.

  13. Luku 7:12nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Bí ó sì ti súnmọ́ ẹnu ibodè ìlú náà, sì kíyèsi i, wọ́n ń gbé òkú ọkùnrin kan jáde, ọmọ kan ṣoṣo náà tí ìyá rẹ̀ bí, ó sì jẹ́ opó: ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn ìlú náà sì wà pẹ̀lú rẹ̀.

  14. Luku 7:13nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí Olúwa sì rí i, àánú rẹ̀ ṣe é, ó sì wí fún un pé, “Má sọkún mọ́.”

  15. Luku 7:14nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì wá, ó sì fi ọwọ́ tọ́ pósí náà: àwọn tí ń rù ú dúró jẹ́. Ó sì wí pé, “Ọ̀dọ́mọkùnrin, mo wí fún ọ, dìde!”

  16. Luku 7:15nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Ẹni tí ó kú náà sì dìde jókòó, ó bẹ̀rẹ̀ sí i fọhùn. Ó sì fà á lé ìyá rẹ̀ lọ́wọ́.

  17. Luku 7:16nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ̀rù sì ba gbogbo wọn: wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo, pé, “Wòlíì ńlá dìde nínú wa,” àti pé, “Ọlọ́run sì wá bẹ àwọn ènìyàn rẹ̀ wò!”

  18. Luku 7:17nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Òkìkí rẹ̀ sì kàn ní gbogbo Judea, àti gbogbo agbègbè tí ó yí i ká.

  19. Luku 7:18nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu sì sọ gbogbo nǹkan wọ̀nyí fún un.

  20. Luku 7:19nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí Johanu sì pe àwọn méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó rán wọn sọ́dọ̀ Olúwa, wí pé, “Ìwọ ni ẹni tí ń bọ̀, tàbí kí a máa retí ẹlòmíràn?”

  21. Luku 7:20nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí àwọn ọkùnrin náà sì dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n wí pé, “Johanu onítẹ̀bọmi rán wa sọ́dọ̀ rẹ, pé, ‘Ìwọ ni ẹni tí ń bọ̀, tàbí kí a máa retí ẹlòmíràn?’ ”

  22. Luku 7:21nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Ní wákàtí náà, ó sì ṣe ìmúláradá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn nínú àìsàn, àti ààrùn, àti ẹ̀mí búburú; ó sì fi ìríran fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn afọ́jú.

  23. Luku 7:22nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Jesu sì dáhùn ó wí fún wọn pé, “Ẹ padà lọ, ẹ ròyìn nǹkan tí ẹ̀yin rí, tí ẹ̀yin sì gbọ́ fún Johanu: àwọn afọ́jú ń ríran, àwọn amúnkùn ún rìn, a sọ àwọn adẹ́tẹ̀ di mímọ́, àwọn adití ń gbọ́rọ̀, a ń jí àwọn òkú dìde, àti fún àwọn òtòṣì ni à ń wàásù ìyìnrere.

  24. Luku 7:23nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Alábùkún fún sì ni ẹnikẹ́ni tí kò kọsẹ̀ lára mi.”

  25. Luku 7:24nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí àwọn oníṣẹ́ Johanu padà lọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún ìjọ ènìyàn ní ti Johanu pé, “Kí ni ẹ̀yin jáde lọ sí ijù lọ wò? Ewéko tí afẹ́fẹ́ ń mì?