circa 6 BC – AD 30
The Life of Jesus
The eternal Son of God enters history: born in Bethlehem, baptized in the Jordan, crucified at Golgotha, raised on the third day.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Luku 2:47nǹkan bí 8 lẹ́yìn Kristi
Ẹnu sì ya gbogbo àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ fún òye àti ìdáhùn rẹ̀.
- Luku 2:48nǹkan bí 8 lẹ́yìn Kristi
Nígbà tí wọ́n sì rí i, háà ṣe wọ́n, ìyá rẹ̀ sì bi í pé, “Ọmọ, èéṣe tí ìwọ fi ṣe wá bẹ́ẹ̀? Sá wò ó, baba rẹ̀ àti èmi ti ń fi ìbànújẹ́ wá ọ kiri.”
- Luku 2:49nǹkan bí 8 lẹ́yìn Kristi
Ó sì dáhùn wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń wá mi kiri? Ẹ̀yin kò mọ̀ pé èmi kò lè ṣàìmá wà níbi iṣẹ́ Baba mi?”
- Luku 2:50nǹkan bí 8 lẹ́yìn Kristi
Ọ̀rọ̀ tí o sọ kò sì yé wọn.
- Luku 2:51nǹkan bí 8 lẹ́yìn Kristi
Ó sì bá wọn sọ̀kalẹ̀ lọ sí Nasareti, sì fi ara balẹ̀ fún wọn, ṣùgbọ́n ìyá rẹ̀ pa gbogbo nǹkan wọ̀nyí mọ́ nínú ọkàn rẹ̀.
- Luku 2:52nǹkan bí 8 lẹ́yìn Kristi
Jesu sì ń pọ̀ ní ọgbọ́n, sì ń dàgbà, ó sì wà ní ojúrere ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́run àti ènìyàn.
- Luku 3:1nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi
Ní ọdún kẹ́ẹ̀dógún ìjọba Tiberiu Kesari, nígbà tí Pọntiu Pilatu jẹ́ baálẹ̀ Judea, tí Herodu sì jẹ́ tetrarki Galili, Filipi arákùnrin rẹ̀ sì jẹ́ tetrarki Iturea àti ti Trakoniti, Lisania sì jẹ́ tetrarki Abilene,
- Luku 3:2nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi
tí Annasi òun Kaiafa ń ṣe olórí àwọn àlùfáà, nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ Johanu ọmọ Sekariah wá ní ijù.
- Luku 3:3nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi
Ó sì wá sí gbogbo ilẹ̀ aginjù Jordani, ó ń wàásù ìtẹ̀bọmi ìrònúpìwàdà fún ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀,
- Luku 3:4nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi
bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé ọ̀rọ̀ wòlíì Isaiah pé, “Ohùn ẹni tí ń kígbe ní ijù, ‘Ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe, ẹ mú ipa ọ̀nà rẹ̀ tọ́.
- Luku 3:5nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi
Gbogbo ọ̀gbun ni a yóò kún, gbogbo òkè ńlá àti òkè kékeré ni a ó tẹ́ pẹẹrẹ. Wíwọ́ ni a ó ṣe ní títọ́, àti ọ̀nà gbọ́ngungbọ̀ngun ni a o sọ di dídán.
- Luku 3:6nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi
Gbogbo ènìyàn ni yóò sì rí ìgbàlà Ọlọ́run.’ ”
- Luku 3:7nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi
Nígbà náà ni ó wí fún ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn tí ó wá láti ṣe ìtẹ̀bọmi lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Ẹ̀yin ìran paramọ́lẹ̀, ta ni ó kìlọ̀ fún un yín láti sá kúrò nínú ìbínú tí ń bọ̀?
- Luku 3:8nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi
Nítorí náà kí ẹ̀yin kí ó so èso tí ó yẹ fún ìrònúpìwàdà, kí ẹ má sì ṣe sí í wí nínú ara yín pé, ‘Àwa ní Abrahamu ní baba.’ Kí èmi kí ó wí fún un yín, Ọlọ́run lè gbé ọmọ dìde fún Abrahamu nínú òkúta wọ̀nyí.
- Luku 3:9nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi
Àti nísinsin yìí pẹ̀lú, a fi àáké lé gbòǹgbò igi náà, gbogbo igi tí kò bá so èso rere, a óò ge lulẹ̀, a sì wọ jù sínú iná.”
- Luku 3:10nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi
Àwọn ènìyàn sì ń bi í pé, “Kí ni kí àwa kí ó ṣe?”
- Luku 3:11nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi
Ó dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ẹni tí ó bá ní ẹ̀wù méjì, kí ó fi ọ̀kan fún ẹni tí kò ní; ẹni tí ó bá sì ní oúnjẹ, kí ó ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.”
- Luku 3:12nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi
Àwọn agbowó òde sì tọ̀ ọ́ wá láti ṣe ìtẹ̀bọmi lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì bi í pé, “Olùkọ́, kí ni àwa ó ha ṣe?”
- Luku 3:13nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi
Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe fi agbára gbà jù bí a ti rán yín lọ mọ́.”
- Luku 3:14nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi
Àwọn ọmọ-ogun sì béèrè lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Àti àwa, kí ni àwa ó ṣe?” Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe hùwà ipá sí ẹnikẹ́ni, kí ẹ má sì ṣe ka ẹ̀sùn èké sí ẹnikẹ́ni; kí òwò ọ̀yà yín tó yín.”
- Luku 3:15nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi
Bí àwọn ènìyàn sì ti ń retí, tí gbogbo wọn sì ń rò nínú ara wọn nítorí Johanu, bí òun ni Kristi tàbí òun kọ́;
- Luku 3:16nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi
Johanu dáhùn ó sì wí fún gbogbo wọn pé, “Lóòótọ́ ni èmi ń fi omi bamitiisi yín, ṣùgbọ́n ẹni tí ó lágbára jù mí lọ ń bọ̀, okùn bàtà ẹsẹ̀ ẹni tí èmi kò tó tú, Òun ni yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ àti iná bamitiisi yín.
- Luku 3:17nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi
Ẹni tí àtẹ rẹ̀ ń bẹ ní ọwọ́ rẹ̀, láti gbá ilẹ̀ ìpakà rẹ̀ mọ́ tó tó, kí ó sì kó alikama rẹ̀ sínú àká; ṣùgbọ́n ìyàngbò ni yóò fi iná àjóòkú sun.”
- Luku 3:18nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi
Johanu lo oríṣìíríṣìí ọ̀rọ̀ púpọ̀ láti gba àwọn ènìyàn níyànjú àti láti wàásù ìyìnrere fún wọn.
- Luku 3:19nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n nígbà ti Johanu bú Herodu tetrarki, tí ó bá wí nítorí Herodia aya Filipi arákùnrin rẹ̀, àti nítorí ohun búburú gbogbo tí Herodu tí ṣe,