Fò sí àkóónú

circa 6 BC – AD 30

The Life of Jesus

The eternal Son of God enters history: born in Bethlehem, baptized in the Jordan, crucified at Golgotha, raised on the third day.

3,779 ẹsẹ · 4 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Luku 3:20nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi

    Ó fi èyí parí gbogbo rẹ̀ nígbà tí ó fi Johanu sínú túbú.

  2. Luku 3:21nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí a ṣe ìtẹ̀bọmi àwọn ènìyàn gbogbo tán, ó sì ṣe, a bamitiisi Jesu pẹ̀lú, bí ó ti ń gbàdúrà, ọ̀run ṣí sílẹ̀,

  3. Luku 3:22nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ̀mí Mímọ́ sì sọ̀kalẹ̀ sí orí rẹ̀ ní àwọ̀ àdàbà, ohùn kan sì ti ọ̀run wá, tí ó wí pé, “Ìwọ ni àyànfẹ́ ọmọ mi; ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi.”

  4. Luku 3:23nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi

    Jesu tìkára rẹ̀ ń tó bí ẹni ọgbọ̀n ọdún, nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ ó jẹ́ (bí a ti fi pè) ọmọ Josẹfu, tí í ṣe ọmọ Eli,

  5. Luku 3:24nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi

    tí í ṣe ọmọ Mattati, tí í ṣe ọmọ Lefi, tí í ṣe ọmọ Meliki, tí í ṣe ọmọ Janai, tí í ṣe ọmọ Josẹfu,

  6. Luku 3:25nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi

    tí í ṣe ọmọ Mattatia, tí í ṣe ọmọ Amosi, tí í ṣe ọmọ Naumu, tí í ṣe ọmọ Esili, tí í ṣe ọmọ Nagai,

  7. Luku 3:26nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi

    tí í ṣe ọmọ Maati, tí í ṣe ọmọ Mattatia, tí í ṣe ọmọ Ṣimei, tí í ṣe ọmọ Josẹfu, tí í ṣe ọmọ Joda,

  8. Luku 3:27nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi

    tí í ṣe ọmọ Joana, tí í ṣe ọmọ Resa, tí í ṣe ọmọ Serubbabeli, tí í ṣe ọmọ Ṣealitieli, tí í ṣe ọmọ Neri,

  9. Luku 3:28nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi

    tí í ṣe ọmọ Meliki, tí í ṣe ọmọ Adi, tí í ṣe ọmọ Kosamu, tí í ṣe ọmọ Elmadamu, tí í ṣe ọmọ Eri,

  10. Luku 3:29nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi

    tí í ṣe ọmọ Joṣua, tí í ṣe ọmọ Elieseri, tí í ṣe ọmọ Jorimu, tí í ṣe Mattati, tí í ṣe ọmọ Lefi,

  11. Luku 3:30nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi

    tí í ṣe ọmọ Simeoni, tí í ṣe ọmọ Juda, tí í ṣe ọmọ Josẹfu, tí í ṣe ọmọ Jonamu, tí í ṣe ọmọ Eliakimu,

  12. Luku 3:31nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi

    tí í ṣe ọmọ Melea, tí í ṣe ọmọ Menna, tí í ṣe ọmọ Mattata, tí í ṣe ọmọ Natani, tí í ṣe ọmọ Dafidi,

  13. Luku 3:32nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi

    tí í ṣe ọmọ Jese, tí í ṣe ọmọ Obedi, tí í ṣe ọmọ Boasi, tí í ṣe ọmọ Salmoni, tí í ṣe ọmọ Nahiṣoni,

  14. Luku 3:33nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi

    tí í ṣe ọmọ Amminadabu, tí í ṣe ọmọ Ramu, tí í ṣe ọmọ Hesroni, tí í ṣe ọmọ Peresi, tí í ṣe ọmọ Juda.

  15. Luku 3:34nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi

    Tí í ṣe ọmọ Jakọbu, tí í ṣe ọmọ Isaaki, tí í ṣe ọmọ Abrahamu, tí í ṣe ọmọ Tẹra, tí í ṣe ọmọ Nahori,

  16. Luku 3:35nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi

    tí í ṣe ọmọ Serugu, tí í ṣe ọmọ Reu, tí í ṣe ọmọ Pelegi, tí í ṣe ọmọ Eberi, tí í ṣe ọmọ Ṣela.

  17. Luku 3:36nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi

    Tí í ṣe ọmọ Kainani, tí í ṣe ọmọ Arfaksadi, tí í ṣe ọmọ Ṣemu, tí í ṣe ọmọ Noa, tí í ṣe ọmọ Lameki,

  18. Luku 3:37nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi

    tí í ṣe ọmọ Metusela, tí í ṣe ọmọ Enoku, tí í ṣe ọmọ Jaredi, tí í ṣe ọmọ Mahalaleli, tí í ṣe ọmọ Kainani.

  19. Luku 3:38nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi

    Tí í ṣe ọmọ Enosi, tí í ṣe ọmọ Seti, tí í ṣe ọmọ Adamu, tí í ṣe ọmọ Ọlọ́run.

  20. Luku 4:1nǹkan bí 27 lẹ́yìn Kristi

    Jesu sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó padà ti Jordani wá, a sì ti ọwọ́ Ẹ̀mí darí rẹ̀ sí ijù,

  21. Luku 4:2nǹkan bí 27 lẹ́yìn Kristi

    Ogójì ọjọ́ ni a fi dán an wò lọ́wọ́ èṣù. Kò sì jẹ ohunkóhun ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì: nígbà tí wọ́n sì parí, lẹ́yìn náà ni ebi wá ń pa á.

  22. Luku 4:3nǹkan bí 27 lẹ́yìn Kristi

    Èṣù sì wí fún un pé, “Bí ìwọ bá ṣe Ọmọ Ọlọ́run, pàṣẹ fún òkúta yìí kí ó di àkàrà.”

  23. Luku 4:4nǹkan bí 27 lẹ́yìn Kristi

    Jesu sì dáhùn, ó wí fún un pé, “A ti kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Ènìyàn kì yóò wà láààyè nípa àkàrà nìkan.’ ”

  24. Luku 4:5nǹkan bí 27 lẹ́yìn Kristi

    Lójúkan náà, èṣù sì mú un lọ sí orí òkè gíga, ó sì fi gbogbo ilẹ̀ ọba ayé hàn án.

  25. Luku 4:6nǹkan bí 27 lẹ́yìn Kristi

    Èṣù sì wí fún un pé, “Ìwọ ni èmi ó fi gbogbo agbára yìí àti ògo wọn fún: nítorí á sá ti fi fún mi. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì wù mí, èmi a fi í fún.