Fò sí àkóónú

circa 930–586 BC

The Divided Kingdom

The kingdom splits into Israel and Judah; prophets warn of judgment as both nations slowly drift into idolatry and exile.

1,722 ẹsẹ · 3 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. 2 Ọba 18:3nǹkan bí 726 ṣáájú Kristi

    Ó sì ṣe ohun tí ó dára níwájú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí i baba rẹ̀ Dafidi ti ṣe.

  2. 2 Ọba 18:4nǹkan bí 726 ṣáájú Kristi

    Ó mú ibi gíga náà kúrò, ó sì fọ́ àwọn ère òkúta, ó sì gé àwọn ère Aṣerah lulẹ̀, ó sì fọ́ ejò idẹ tí Mose ti ṣe náà túútúú, títí di ọjọ́ tí àwọn ọmọ Israẹli ń sun tùràrí sí. (Wọ́n sì pè é ní Nehuṣitani.)

  3. 2 Ọba 18:5nǹkan bí 726 ṣáájú Kristi

    Hesekiah sì gbẹ́kẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run Israẹli. Kò sì ṣí ẹnìkan tí ó dàbí tirẹ̀ lára gbogbo àwọn ọba Juda, bóyá kí ó tó jẹ tàbí lẹ́yìn rẹ̀.

  4. 2 Ọba 18:6nǹkan bí 726 ṣáájú Kristi

    Ó súnmọ́ Olúwa, kò sì dẹ́kun láti tì í lẹ́yìn: ó sì pa òfin Olúwa mọ́ tí ó ti fi fún Mose.

  5. 2 Ọba 18:7nǹkan bí 726 ṣáájú Kristi

    Olúwa sì wà pẹ̀lú rẹ̀; ó sì ń ṣe rere nínú gbogbo ohun tí ó dáwọ́lé. Ó ṣe ọ̀tẹ̀ sí ọba Asiria kò sì sìn ín.

  6. 2 Ọba 18:8nǹkan bí 726 ṣáájú Kristi

    Láti ilé ìṣọ́ títí dé ìlú olódi, ó sì pa àwọn ará Filistini run, àti títí dé Gasa àti agbègbè rẹ̀.

  7. 2 Ọba 18:9nǹkan bí 723 ṣáájú Kristi

    Ní ọdún kẹrin ọba Hesekiah, nígbà tí ó jẹ́ ọdún keje Hosea ọmọ Ela ọba Israẹli. Ṣalamaneseri ọba Asiria yàn lára Samaria ó sì tẹ̀dó tì í.

  8. 2 Ọba 18:10nǹkan bí 721 ṣáájú Kristi

    Lẹ́yìn ọdún mẹ́ta Asiria gbé e. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kó Samaria ní ọdún kẹfà Hesekiah tí ó sì jẹ́ ọdún kẹsànán Hosea ọba Israẹli.

  9. 2 Ọba 18:11nǹkan bí 721 ṣáájú Kristi

    Ọba Asiria lé Israẹli kúrò ní Asiria, wọ́n sì ṣe àtìpó wọn ní Hala, ní Gosani létí odò Habori àti ní ìlú àwọn ará Media.

  10. 2 Ọba 18:12nǹkan bí 721 ṣáájú Kristi

    Èyí ṣẹlẹ̀ nítorí wọn kò pa àṣẹ Olúwa Ọlọ́run wọn mọ́. Ṣùgbọ́n wọ́n ti dà májẹ̀mú rẹ̀ gbogbo èyí tí Mose ìránṣẹ́ Olúwa ti pàṣẹ. Wọn kò fi etí wọn sílẹ̀ sí òfin wọn kò sì gbé wọn jáde.

  11. 2 Ọba 18:13nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi

    Ní ọdún kẹrìnlá tí Hesekiah jẹ ọba, Sennakeribu ọba Asiria kọlu gbogbo ìlú olódi ti Juda ó sì pa wọ́n run.

  12. 2 Ọba 18:14nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi

    Bẹ́ẹ̀ ni Hesekiah ọba Juda sì ránṣẹ́ yìí sí ọba Asiria ní Lakiṣi, wí pé, “Mo ti ṣẹ̀, padà lẹ́yìn mi: èmi yóò sì san ohunkóhun tí ìwọ bá béèrè lọ́wọ́ mi.” Ọba Asiria sì bu fún Hesekiah ọba Juda ọ̀ọ́dúnrún (300) tálẹ́ǹtì fàdákà àti ọgbọ̀n tálẹ́ǹtì wúrà.

  13. 2 Ọba 18:15nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi

    Hesekiah fún un ní gbogbo fàdákà tí a rí nínú ilé Olúwa àti nínú ìṣúra ilé ọba.

  14. 2 Ọba 18:16nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi

    Ní àkókò yìí Hesekiah ọba Juda ké wúrà tí ó wà ní ẹnu ìlẹ̀kùn ilé Olúwa, kúrò àti ti òpó tí Hesekiah ọba Juda ti gbéró ó sì fi fún ọba Asiria.

  15. 2 Ọba 18:17nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi

    Ọba Asiria rán alákòóso gíga jùlọ, ìjòyè pàtàkì àti àwọn adarí pápá pẹ̀lú àwọn ọmọ-ogun tí ó pọ̀, láti Lakiṣi sí ọba Hesekiah ní Jerusalẹmu. Wọ́n wá sí òkè Jerusalẹmu wọ́n sì dúró ní etí ìdarí omi àbàtà òkè, ní ojú ọ̀nà tó lọ sí òpópó pápá alágbàfọ̀.

  16. 2 Ọba 18:18nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi

    Wọ́n sì pe ọba; àti Eliakimu ọmọ Hilkiah ẹni tí í ṣe ilé olùtọ́jú, Ṣebna akọ̀wé, àti Joah ọmọkùnrin Asafu tí ó jẹ́ akọ̀wé ìrántí jáde pẹ̀lú wọn.

  17. 2 Ọba 18:19nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi

    Olùdarí pápá wí fún wọn pé, “Sọ fún Hesekiah pé, “ ‘Èyí ni ohun tí ọba ńlá, ọba Asiria sọ: Kí ni ìgbẹ́kẹ̀lé yìí tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé?

  18. 2 Ọba 18:20nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi

    Ìwọ wí pé ìwọ ni ìmọ̀ àti agbára láti jagun, ṣùgbọ́n ìwọ sọ̀rọ̀ òfìfo lásán. Ǹjẹ́ ta ni ìwọ gbẹ́kẹ̀ rẹ lé, tí ìwọ fi ń ṣe ọ̀tẹ̀ sí mi?

  19. 2 Ọba 18:21nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi

    Wò ó, nísinsin yìí, ìwọ gbẹ́kẹ̀ rẹ lé Ejibiti, ẹ̀rún ọ̀pá pẹlẹbẹ ìyè fífọ́ yìí, èyí tí yóò wọ inú ọwọ́ ẹni tí ó sì bá fi ara tì í. Bẹ́ẹ̀ ni Farao ọba Ejibiti ṣe rí fún gbogbo àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀ wọn lé e.

  20. 2 Ọba 18:22nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi

    Tí ìwọ bá sì sọ fún mi pé, “Àwa gbẹ́kẹ̀ wa lé Olúwa Ọlọ́run.” Òun ha kọ́ ní ẹnìkan náà tí ibi gíga àti àwọn pẹpẹ tí Hesekiah mú kúrò, tí ó wí fún Juda àti Jerusalẹmu pé, “O gbọdọ̀ sìn níwájú pẹpẹ yìí ní Jerusalẹmu”?

  21. 2 Ọba 18:23nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi

    “ ‘Wá nísinsin yìí, ṣe àdéhùn pẹ̀lú ọ̀gá mi, ọba Asiria èmi yóò sì fún ọ ní ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ẹṣin tí ìwọ bá lè kó àwọn tí yóò gùn ún sí orí rẹ!

  22. 2 Ọba 18:24nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi

    Báwo ni ìwọ yóò ha ti ṣe le yí ojú balógun kan tí ó kéré jùlọ padà nínú àwọn ìránṣẹ́ olúwa mi, tí ìwọ sì gbẹ́kẹ̀ rẹ lé Ejibiti fún àwọn kẹ̀kẹ́ àti ẹlẹ́ṣin?

  23. 2 Ọba 18:25nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi

    Síwájú sí i, èmi ti wá láti mú àti láti parun ibí yìí láìsí ọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Olúwa? Olúwa fún rara rẹ̀ sọ fún mi pé kí n yára láti yan lórí ìlú yìí, kí n sì pa á run.’ ”

  24. 2 Ọba 18:26nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà Eliakimu ọmọ Hilkiah, àti Ṣebna àti Joah sọ fún olùdarí pápá pé, “Jọ̀wọ́ sọ̀rọ̀ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ ní èdè Aramaiki, nítorí ti ó tí yé wa, má ṣe sọ̀rọ̀ fún wa pẹ̀lú èdè Heberu ní etí ìgbọ́ àwọn ènìyàn tí ń bẹ lórí odi.”

  25. 2 Ọba 18:27nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n aláṣẹ dáhùn pé, “Ṣé fún ọ̀gá rẹ àti ìwọ nìkan ní ọ̀gá mi rán mi sí láti sọ àwọn nǹkan wọ̀nyí kì í sì í ṣe fún àwọn ọkùnrin tí ó jókòó lórí odi ni gẹ́gẹ́ bí ìwọ, ni yóò ní láti jẹ ìgbẹ́ ará wọn kí wọ́n sì mu ìtọ̀ ará wọn?”