Fò sí àkóónú

Moses

774 ẹsẹ · 7 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Moses

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Mose àti Aaroni sí ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún wọn. Ó gbé ọ̀pá rẹ̀ sókè ni iwájú Farao àti àwọn ìjòyè rẹ̀, ó sì lu omi odò Naili, omi odò náà sì yípadà sí ẹ̀jẹ̀.

  2. Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, “Padà tọ Farao lọ kí ó sì sọ fún un pé, ‘Èyí ni Olúwa wí: Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, kí wọn ó bá à lè sìn mi.

  3. Ní ìgbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, “Sọ fún Aaroni, ‘Kí ó na ọwọ́ rẹ̀ jáde pẹ̀lú ọ̀pá sí orí àwọn odò kéékèèké àti odò ńlá, àti sí orí àwọn àbàtà kí ó sì mú àwọn ọ̀pọ̀lọ́ gòkè wá sí ilẹ̀ Ejibiti.’ ”

  4. Farao ránṣẹ́ pe Mose àti Aaroni, ó sì sọ fún wọn pé, “Gbàdúrà sí Olúwa kí ó mú àwọn ọ̀pọ̀lọ́ wọ̀nyí kúrò lọ́dọ̀ mi àti lára àwọn ènìyàn mi, Èmi yóò sì jẹ́ kí àwọn ènìyàn rẹ kí ó lọ láti rú ẹbọ sí Olúwa.”

  5. Mose sọ fún Farao pé, “Jọ̀wọ́ sọ fún mi ìgbà ti èmi yóò gbàdúrà fún ọ àti àwọn ìjòyè rẹ àti fún àwọn ènìyàn rẹ, kí àwọn ọ̀pọ̀lọ́ wọ̀nyí bá lè lọ lọ́dọ̀ rẹ àti ní àwọn ilé yín tí wọn yóò sì wà nínú odò Naili nìkan.”

  6. Lẹ́yìn tí Mose àti Aaroni tí kúrò ní iwájú Farao, Mose gbé ohùn ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ sókè sí Olúwa nípa àwọn ọ̀pọ̀lọ́ tí ó ti rán sí Farao.

  7. Olúwa sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Mose tí béèrè. Àwọn ọ̀pọ̀lọ́ sì kú nínú ilé àti ní ìta, gbangba àti nínú oko.

  8. Olúwa sọ fún Mose pé, “Sọ fún Aaroni, ‘Na ọ̀pá rẹ jáde kí ó sì lu eruku ilẹ̀,’ jákèjádò gbogbo ilẹ̀ Ejibiti ni erùpẹ̀ ilẹ̀ yóò ti di kòkòrò-kantíkantí.” (Kòkòrò kan tí ó ní ìyẹ́ méjì tí ó ṣì ń ta ni.)

  9. Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, “Lọ ní òwúrọ̀ kùtùkùtù kí o sì ko Farao lójú bí ó ṣe ń lọ sí odò, kí o sì sọ fún un pé, ‘Èyí ni Olúwa sọ: Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, kí wọn kí ó bá à lè sìn Mi.

  10. Nígbà náà ni Farao ránṣẹ́ pe Mose àti Aaroni, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ máa lọ kí ẹ sì rú ẹbọ sí Ọlọ́run yín ní ilẹ̀ yìí.”

  11. Ṣùgbọ́n Mose sọ pé, “Èyí ló tọ́, ẹbọ tí a ó rú sí Olúwa Ọlọ́run wa yóò jẹ́ ohun ìríra sí àwọn ará ilẹ̀ Ejibiti. Bí a bá ṣe ìrúbọ ti yóò jẹ́ ìríra ni ojú wọn ṣé wọn, ó ní sọ òkúta lù wá?

  12. Mose dáhùn ó wí pé, “Bí èmi bá ti kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ, èmi yóò gbàdúrà sí Olúwa, àwọn ọ̀wọ́ eṣinṣin yóò fi Farao, àwọn ìjòyè rẹ, àti àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀ ní ọ̀la ṣùgbọ́n ǹjẹ́ ìdánilójú wa pé Farao kò tún ni lo ẹ̀tàn láti má jẹ́ kí àwọn ènìyàn kí ó lọ rú ẹbọ sí Olúwa.”

  13. Nígbà náà ni Mose kúrò ni ọ̀dọ̀ Farao, ó sì gbàdúrà sí Olúwa;

  14. Olúwa sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Mose ti béèrè. Àwọn ọ̀wọ́ eṣinṣin kúrò lára Farao àti àwọn ìjòyè rẹ̀ àti lára àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú, eṣinṣin kan kò sì ṣẹ́kù.

  15. Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, “Lọ sọ fún Farao, ‘Èyí ni Olúwa Ọlọ́run àwọn Heberu sọ, “Jẹ́ kí àwọn ènìyàn Mi kí ó lọ, kí wọn bá à lè sìn Mí.”

  16. Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni, “Ẹ bu ẹ̀kúnwọ́ eérú gbígbóná láti inú ààrò, kí Mose kù ú sí inú afẹ́fẹ́ ni iwájú Farao.

  17. Nígbà náà ni wọ́n bú eérú gbígbóná láti inú ààrò, wọ́n dúró ní iwájú Farao. Mose sì ku eérú náà sínú afẹ́fẹ́, ó sì di oówo tí ń tú pẹ̀lú ìléròrò ni ara àwọn ènìyàn àti lára ẹran.

  18. Àwọn onídán kò le è dúró níwájú Mose nítorí oówo ti ó wà lára wọn àti ni ara gbogbo àwọn ara Ejibiti.

  19. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run sé ọkàn Farao le, kò sì gbọ́ ti Mose àti Aaroni, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ fún Mose.

  20. Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, “Dìde ni òwúrọ̀ kùtùkùtù, kí o sì tọ Farao lọ, kí o sì wí fún un pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run àwọn Heberu wí, Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, kí wọn bá à lè sìn mí,

  21. Olúwa sọ fún Mose pé, “Gbé ọwọ́ rẹ sókè sí ọ̀run kí yìnyín bá à lè rọ̀ sí orí gbogbo ilẹ̀ Ejibiti, sí orí ènìyàn àti ẹranko, àti sí orí gbogbo ohun ọ̀gbìn tí ó wà ni inú oko.”

  22. Nígbà tí Mose gbé ọ̀pá rẹ̀ sókè sí ojú ọ̀run, Olúwa rán àrá àti yìnyín, mọ̀nàmọ́ná sì bùsi orí ilẹ̀. Olúwa rọ òjò yìnyín sí orí ilẹ̀ Ejibiti.

  23. Nígbà náà ni Farao pe Mose àti Aaroni sì ọ̀dọ́ rẹ̀, ó sì wí fún wọn pé, “Èmi ti ṣẹ̀ ní àkókò yìí; Olúwa jẹ́ olódodo ṣùgbọ́n èmi àti àwọn ènìyàn mi ni aláìṣòdodo.

  24. Mose dá a lóhùn pé, “Bí mo bá ti jáde kúrò ní àárín ìlú, èmi yóò gbé ọwọ́ mi sókè sí Olúwa, sísán àrá yóò dáwọ́ dúró, yìnyín kò sì ni rọ̀ mọ́, kí ìwọ kí ó lè mọ̀ pé Olúwa ni ó ni ilẹ̀.

  25. Nígbà náà ni Mose jáde kúrò ni iwájú Farao, ó kúrò ni àárín ìgboro kọjá lọ sí ẹ̀yìn odi ìlú, ó sì gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè sí Olúwa, sísán àrá àti òjò yìnyín ti ń rọ̀ sì dáwọ́ dúró, òjò kò sì rọ̀ sí orí ilẹ̀ mọ́.