Fò sí àkóónú

Jesus

3,872 ẹsẹ · 6 ọmọ ẹbí

A tún mọ̀ ọ́n sí: Jesus Christ, Immanuel, Emmanuel, Christ

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Jesus

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Lẹ́yìn èyí, ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí Kapernaumu, Òun àti ìyá rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀, àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, wọ́n sì gbé ibẹ̀ ní ọjọ́ pípẹ́.

  2. Àjọ ìrékọjá àwọn Júù sì súnmọ́ etílé, Jesu sì gòkè lọ sí Jerusalẹmu,

  3. Ó sì fi okùn tẹ́ẹ́rẹ́ ṣe pàṣán, ó sì lé gbogbo wọn jáde kúrò nínú tẹmpili, àti àgùntàn àti màlúù; ó sì da owó àwọn onípàṣípàrọ̀ owó nù, ó si ti tábìlì wọn ṣubú.

  4. Ó sì wí fún àwọn tí ń ta àdàbà pé, “Ẹ gbé nǹkan wọ̀nyí kúrò níhìn-ín; ẹ má ṣe sọ ilé Baba mi di ilé ọjà títà.”

  5. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì rántí pé, a ti kọ ọ́ pé, “Ìtara ilé rẹ jẹ mí run.”

  6. Nígbà náà ní àwọn Júù dáhùn, wọ́n sì bi í pé, “Àmì wo ni ìwọ lè fihàn wá, tí ìwọ fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí?”

  7. Jesu dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ wó tẹmpili yìí palẹ̀, Èmi ó sì tún un kọ ní ọjọ́ mẹ́ta.”

  8. Nígbà náà ní àwọn Júù wí pé, “Ọdún mẹ́rìndínláàádọ́ta ni a fi kọ́ tẹmpili yìí, ìwọ ó ha sì tún un kọ ní ọjọ́ mẹ́ta?”

  9. Ṣùgbọ́n òun ń sọ ti tẹmpili ara rẹ̀.

  10. Nítorí náà nígbà tí ó jíǹde kúrò nínú òkú, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ rántí pé, ó ti sọ èyí fún wọn, wọ́n sì gba Ìwé Mímọ́, àti ọ̀rọ̀ tí Jesu ti sọ gbọ́.

  11. Nígbà tí ó sì wà ní Jerusalẹmu, ní àjọ ìrékọjá, lákokò àjọ náà, ọ̀pọ̀ ènìyàn gba orúkọ rẹ̀ gbọ́ nígbà tí wọ́n rí iṣẹ́ àmì tí ó ṣe.

  12. Ṣùgbọ́n Jesu kò gbé ara lé wọn, nítorí tí ó mọ gbogbo ènìyàn.

  13. Òun kò sì nílò ẹ̀rí nípa ènìyàn, nítorí tí o mọ̀ ohun tí ń bẹ nínú ènìyàn.

  14. Òun náà ní ó tọ Jesu wá ní òru, ó sì wí fún un pé, Rabbi, àwa mọ̀ pé olùkọ́ni láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá ni ìwọ ń ṣe, nítorí pé kò sí ẹni tí ó lè ṣe iṣẹ́ àmì wọ̀nyí tí ìwọ ń ṣe, bí kò ṣe pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀.

  15. Jesu dáhùn ó sì wí fún un pé, “Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, bí kò ṣe pé a tún ènìyàn bí, òun kò lè rí ìjọba Ọlọ́run.”

  16. Nikodemu wí fún un pé, a ó ti ṣe lè tún ènìyàn bí nígbà tí ó di àgbàlagbà tan? Ó ha lè wọ inú ìyá rẹ̀ lọ nígbà kejì, kí a sì bí i?

  17. Jesu dáhùn wí pé, “Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, bí kò ṣe pé a fi omi àti Ẹ̀mí bí ènìyàn, òun kò lè wọ ìjọba Ọlọ́run.

  18. Kí ẹnu kí ó má ṣe yà ọ́, nítorí mo wí fún ọ pé, ‘A kò lè ṣe aláìtún yín bí.’

  19. Nikodemu dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Nǹkan wọ̀nyí yóò ti ṣe lè rí bẹ́ẹ̀?”

  20. Jesu dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Ṣé olùkọ́ni ní Israẹli ni ìwọ ń ṣe, o kò sì mọ nǹkan wọ̀nyí?

  21. Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, Àwa ń sọ èyí tí àwa mọ̀, a sì ń jẹ́rìí èyí tí àwa ti rí; ẹ̀yin kò sì gba ẹ̀rí wa.

  22. Bí mo bá sọ ohun ti ayé yìí fún yín, tí ẹ̀yin kò sì gbàgbọ́, ẹ̀yin ó ti ṣe gbàgbọ́ bí mo bá sọ ohun ti ọ̀run fún yín?

  23. Kò sì ṣí ẹni tí ó gòkè re ọ̀run bí kò ṣe ẹni tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, Ọmọ Ènìyàn tí ń bẹ ní ọ̀run.

  24. Bí Mose sì ti gbé ejò sókè ní aginjù, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni a kò le ṣe aláìgbé Ọmọ Ènìyàn sókè pẹ̀lú.

  25. Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́, kí ó má bà á ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó le ní ìyè àìnípẹ̀kun.”