Fò sí àkóónú

Jesus

3,872 ẹsẹ · 6 ọmọ ẹbí

A tún mọ̀ ọ́n sí: Jesus Christ, Immanuel, Emmanuel, Christ

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Jesus

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá mu nínú omi tí èmi ó fi fún un, òǹgbẹ kì yóò gbẹ ẹ́ mọ́ láé; ṣùgbọ́n omi tí èmi ó fi fún un yóò di kànga omi nínú rẹ̀, tí yóò máa sun si ìyè àìnípẹ̀kun.”

  2. Obìnrin náà sì wí fún u pé, “Alàgbà, fún mi ní omi yìí, kí òǹgbẹ kí ó má ṣe gbẹ mí, kí èmi kí ó má sì wá fa omi níbí mọ́.”

  3. Jesu wí fún un pé, “Lọ pe ọkọ rẹ, kí ó sì padà wá sí ìhín yìí.”

  4. Obìnrin náà dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Èmi kò ní ọkọ.” Jesu wí fún un pé, “Ìwọ́ dáhùn dáradára pé, èmi kò ní ọkọ:

  5. Obìnrin náà wí fún un pé, “Alàgbà, mo wòye pé, wòlíì ni ìwọ ń ṣe.

  6. Jesu wí fún un pé, “Gbà mí gbọ́ obìnrin yìí, àkókò náà ń bọ̀, nígbà tí kì yóò ṣe lórí òkè yìí tàbí ní Jerusalẹmu ni ẹ̀yin ó máa sin Baba.

  7. Ẹ̀mí ni Ọlọ́run: àwọn ẹni tí ń sìn ín kò lè ṣe aláìsìn ín ní Ẹ̀mí àti ní òtítọ́.”

  8. Obìnrin náà wí fún un pé, mo mọ̀ pé, “Messia ń bọ̀ wá, tí a ń pè ní Kristi, nígbà tí Òun bá dé, yóò sọ ohun gbogbo fún wa.”

  9. Jesu sọ ọ́ di mí mọ̀ fún un pé, “Èmi ẹni tí ń bá ọ sọ̀rọ̀ yìí ni Òun.”

  10. Lákokò yí ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ dé, ẹnu sì yà wọ́n pé ó ń bá obìnrin sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ó wí pé, “Kí ni ìwọ ń wá?” tàbí “Èéṣe tí ìwọ fi ń bá a sọ̀rọ̀?”

  11. “Ẹ wá wò ọkùnrin kan, ẹni tí ó sọ ohun gbogbo tí mo ti ṣe rí fún mi, èyí ha lè jẹ́ Kristi náà?”

  12. Nígbà náà ni wọ́n ti ìlú jáde, wọ́n sì tọ̀ ọ́ wá.

  13. Láàrín èyí, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń rọ̀ ọ́ wí pé, “Rabbi, jẹun.”

  14. Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé, “Èmi ní oúnjẹ láti jẹ, tí ẹ̀yin kò mọ̀.”

  15. Nítorí náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń bi ara wọn lérè wí pé, “Ẹnìkan mú oúnjẹ fún un wá láti jẹ bí?”

  16. Jesu wí fún wọn pé, “Oúnjẹ mi ni láti ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi, àti láti parí iṣẹ́ rẹ̀.

  17. Ẹ̀yin kò ha wí pé, ‘Ó ku oṣù mẹ́rin, ìkórè yóò sì dé?’ wò ó, mo wí fún un yín, Ẹ ṣí ojú yín sókè, kí ẹ sì wo oko; nítorí tí wọn ti pọ́n fún ìkórè.

  18. Mo rán yín lọ kórè ohun tí ẹ kò ṣiṣẹ́ fún. Àwọn ẹlòmíràn ti ṣiṣẹ́, ẹ̀yin sì kórè èrè làálàá wọn.”

  19. Ọ̀pọ̀ àwọn ará Samaria láti ìlú náà wá sì gbà á gbọ́ nítorí ìjẹ́rìí obìnrin náà pé, “Ó sọ gbogbo ohun tí mo ti ṣe fún mi.”

  20. Nítorí náà, nígbà tí àwọn ará Samaria wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n rọ̀ ọ́ pé, kí ó wà pẹ̀lú wọn, ó sì dúró fún ọjọ́ méjì.

  21. Àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì gbàgbọ́ sí i nítorí ọ̀rọ̀ rẹ̀.

  22. Wọ́n sì wí fún obìnrin náà pé, “Kì í ṣe nítorí ọ̀rọ̀ rẹ nìkan ni àwa ṣe gbàgbọ́, nítorí tí àwa tìkára wa ti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, àwa sì mọ̀ pé, nítòótọ́ èyí ni Kristi náà, Olùgbàlà aráyé.”

  23. Lẹ́yìn ọjọ́ méjì ó sì ti ibẹ̀ kúrò, ó lọ sí Galili.

  24. Nítorí Jesu tìkára rẹ̀ ti jẹ́rìí wí pé, Wòlíì kì í ní ọlá ní ilẹ̀ òun tìkára rẹ̀.

  25. Nítorí náà nígbà tí ó dé Galili, àwọn ará Galili gbà á, nítorí ti wọ́n ti rí ohun gbogbo tí ó ṣe ní Jerusalẹmu nígbà àjọ ìrékọjá; nítorí àwọn tìkára wọn lọ sí àjọ pẹ̀lú.