Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá nígbà kejì,

  2. Nígbà náà ni mo lọ pa á mọ́ ní Perati gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti wí fún mi.

  3. Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, Olúwa sọ fún mi, “Lọ sí Perati kí o lọ mú àmùrè tí mo ní kí o pamọ́ síbẹ̀.”

  4. Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá pé:

  5. “Èyí ni ohun tí Olúwa sọ: ‘Bákan náà ni èmi yóò run ìgbéraga Juda àti ìgbéraga ńlá ti Jerusalẹmu.

  6. Àwọn ènìyàn búburú tí ó kùnà láti gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí wọ́n ń lo agídí ọkàn wọn, tí ó sì ń rìn tọ àwọn òrìṣà láti sìn wọ́n, àti láti foríbalẹ̀ fún wọn, yóò sì dàbí àmùrè yìí tí kò wúlò fún ohunkóhun.

  7. Nítorí bí a ti lẹ àmùrè mọ́ ẹ̀gbẹ́ ènìyàn, bẹ́ẹ̀ ni a lẹ agbo ilé Israẹli àti gbogbo ilé Juda mọ́ mi,’ ni Olúwa wí, ‘kí wọn kí ó lè jẹ́ ènìyàn ògo àti ìyìn fún mi, ṣùgbọ́n wọn kò fẹ́ gbọ́.’

  8. “Sọ fún wọn, ‘Èyí ni Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ Israẹli wí, gbogbo ìgò ni à ó fi ọtí wáìnì kún.’ Bí wọ́n bá sì sọ fún ọ pé, ‘Ṣé a kò mọ̀ pé gbogbo ìgò ni ó yẹ láti bu ọtí wáìnì kún?’

  9. Nítorí náà sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí: Èmi yóò fi ìmutípara kún gbogbo olùgbé ilẹ̀ yìí pẹ̀lú ọba tí ó jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi, àwọn àlùfáà, àwọn wòlíì gbogbo àwọn tó ń gbé ní Jerusalẹmu.

  10. Èmi yóò ti èkínní lu èkejì, àwọn baba àti ọmọkùnrin pọ̀ ni Olúwa wí. Èmi kì yóò dáríjì, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò ṣàánú, èmi kì yóò ṣe ìyọ́nú láti máa pa wọ́n run.’ ”

  11. Gbọ́ kí o sì fetísílẹ̀, ẹ má ṣe gbéraga, nítorí Olúwa ti sọ̀rọ̀.

  12. Ẹ fi ògo fún Olúwa Ọlọ́run yín, kí ó tó mú òkùnkùn wá, àti kí ó tó mú ẹsẹ̀ yín tàsé lórí òkè tí ó ṣókùnkùn. Nígbà tí ẹ̀yin sì ń retí ìmọ́lẹ̀, òun yóò sọ ọ́ di òjìji yóò sì ṣe bi òkùnkùn biribiri.

  13. Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá fetísílẹ̀, Èmi yóò sọkún ní ìkọ̀kọ̀ nítorí ìgbéraga yín. Ojú mi yóò sun ẹkún kíkorò, tí omi ẹkún, yóò sì máa sàn jáde, nítorí a kó agbo Olúwa lọ ìgbèkùn.

  14. Kí ni ìwọ yóò wí nígbà tí Olúwa bá dúró lórí rẹ àwọn tí o mú bí ọ̀rẹ́ àtàtà. Ǹjẹ́ kò ní jẹ́ ìrora fún ọ bí aboyún tó ń rọbí?

  15. “N ó fọ́n ọn yín ká bí i ìyàngbò tí ẹ̀fúùfù ilẹ̀ aṣálẹ̀ ń fẹ́.

  16. Èyí ni ìpín tìrẹ; tí mo ti fi sílẹ̀ fún ọ,” ni Olúwa wí, “Nítorí ìwọ ti gbàgbé mi o sì gbẹ́kẹ̀lé àwọn ọlọ́run àjèjì.

  17. N ó sí aṣọ lójú rẹ, kí ẹ̀sín rẹ le hàn síta—

  18. ìwà àgbèrè àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, àìlójútì panṣágà rẹ! Mo ti rí ìwà ìríra rẹ, lórí òkè àti ní pápá. Ègbé ni fún ọ ìwọ Jerusalẹmu! Yóò ti pẹ́ tó tí o ó fi máa wà ní àìmọ́?”

  19. Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa sí Jeremiah nípa ti àjàkálẹ̀-ààrùn:

  20. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ wa jẹ́rìí lòdì sí wa, wá nǹkan kan ṣe sí i Olúwa, nítorí orúkọ rẹ. Nítorí ìpadàsẹ́yìn wa ti pọ̀jù, a ti ṣẹ̀ sí ọ.

  21. Ìrètí Israẹli; ìgbàlà rẹ lásìkò ìpọ́njú, èéṣe tí ìwọ dàbí àlejò ní ilẹ̀ náà bí arìnrìn-àjò tí ó dúró fún bí òru ọjọ́ kan péré?

  22. Èéṣe tí ìwọ dàbí ẹni tí a dààmú, bí jagunjagun tí kò le ran ni lọ́wọ́? Ìwọ wà láàrín wa, Olúwa, orúkọ rẹ ni a sì ń pè mọ́ wa; má ṣe fi wá sílẹ̀.

  23. Báyìí ni Olúwa sọ nípa àwọn ènìyàn wọ̀nyí: “Wọ́n fẹ́ràn láti máa rìn kiri; wọn kò kó ọkàn wọn ní ìjánu. Nítorí náà Olúwa kò gbà wọ́n; yóò wá rántí ìwà búburú wọn báyìí, yóò sì fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn jẹ wọ́n.”

  24. Nígbà náà ni Olúwa sọ fún mi pé, “Má ṣe gbàdúrà fún àlàáfíà àwọn ènìyàn wọ̀nyí.

  25. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n gbààwẹ̀, èmi kò ní tẹ́tí sí igbe wọn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n rú ẹbọ sísun àti ẹbọ ìyẹ̀fun, èmi ò nígbà wọ́n. Dípò bẹ́ẹ̀, èmi ó fi idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn pa wọ́n run.”