Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ṣùgbọ́n mo sọ pé, “Háà! Olúwa Olódùmarè. Àwọn wòlíì ń sọ fún wọn pé, ‘Ẹ kò ni rí idà tàbí ìyàn. Dájúdájú èmi ó fún yín ní àlàáfíà tí yóò tọ́jọ́ níbí yìí?’ ”

  2. Nígbà náà Olúwa sọ fún mi pé, “Àwọn wòlíì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké ní orúkọ mi. Èmi kò rán wọn, tàbí yàn wọ́n tàbí bá wọn sọ̀rọ̀. Ìran èké ni wọ́n ń rí sí i yín. Àsọtẹ́lẹ̀ èké ni wọ́n ń sọ fún un yín nípa ìran ìrírí, àfọ̀ṣẹ, ìbọ̀rìṣà àti ìtànjẹ ọkàn wọn.

  3. Nítorí náà, èyí ni Olúwa sọ nípa àwọn wòlíì tí wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ lórúkọ mi. Èmi kò rán wọn, síbẹ̀ wọ́n sì ń sọ pé, ‘Idà kan tàbí ìyàn, kì yóò dé ilẹ̀ yìí.’ Àwọn wòlíì kan náà yóò parẹ́ nípa idà àti ìyàn.

  4. Bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ènìyàn tí wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún ni a ó lé sí òpópónà Jerusalẹmu torí idà àti ìyàn. Wọn kò ní i rí ẹni tí yóò sìn wọ́n tàbí ìyàwó wọn, àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn. Èmi yóò mú ìdààmú tí ó yẹ bá ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn.

  5. “Kí ìwọ kí ó sì sọ ọ̀rọ̀ yìí fún wọn pé: “ ‘Jẹ́ kí ojú mi kí ó sun omijé ní ọ̀sán àti ní òru láìdá; nítorí tí a ti ṣá wúńdíá, ọmọ ènìyàn mi ní ọgbẹ́ ńlá pẹ̀lú lílù bolẹ̀.

  6. Bí mo bá lọ sí orílẹ̀-èdè náà, Èmi yóò rí àwọn tí wọ́n fi idà pa. Bí mo bá lọ sí ìlú ńlá, èmi rí àwọn tí ìyàn ti sọ di aláàrùn. Wòlíì àti Àlùfáà ti lọ sí ilẹ̀ tí wọn kò mọ̀.’ ”

  7. Ṣé o ti kọ Juda sílẹ̀ pátápátá ni? Ṣé o ti ṣá Sioni tì? Èéṣe tí o fi pọ́n wa lójú tí a kò fi le wò wá sàn? A ń retí àlàáfíà ṣùgbọ́n ohun rere kan kò tí ì wá, ní àsìkò ìwòsàn ìpayà là ń rí.

  8. Olúwa, a jẹ́wọ́ ìwà ibi wa àti àìṣedéédéé àwọn baba wa; lóòótọ́ ni a ti ṣẹ̀ sí ọ.

  9. Nítorí orúkọ rẹ má ṣe kórìíra wa; má ṣe sọ ìtẹ́ ògo rẹ di àìlọ́wọ̀. Rántí májẹ̀mú tí o bá wa dá kí o má ṣe dà á.

  10. Ǹjẹ́ èyíkéyìí àwọn òrìṣà yẹ̀yẹ́ tí àwọn orílẹ̀-èdè le ṣe kí òjò rọ̀? Ǹjẹ́ àwọsánmọ̀ fúnra rẹ̀ rọ òjò bí? Rárá, ìwọ ni, Olúwa Ọlọ́run wa. Torí náà, ìrètí wa wà lọ́dọ̀ rẹ, nítorí pé ìwọ lo ń ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí.

  11. Nígbà náà ni Olúwa sọ fún mi pé: “Kódà kí Mose àti Samuẹli dúró níwájú mi, ọkàn mi kì yóò lọ sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Mú wọn kúrò níwájú mi! Jẹ́ kí wọn ó lọ!

  12. Tí wọ́n bá sì bi ọ́ pé, ‘Níbo ni kí a lọ?’ Sọ fún wọn pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí: “ ‘Àwọn tí a kọ ikú mọ́, sí ikú; àwọn tí a kọ idà mọ́, sí idà; àwọn tí a kọ ìyàn mọ́, sí ìyàn; àwọn tí a kọ ìgbèkùn mọ́ sí ìgbèkùn.’

  13. “Èmi yóò rán oríṣìí ìjìyà mẹ́rin láti kọlù wọ́n,” ni Olúwa wí, “Idà láti pa, àwọn ajá láti wọ́ wọn lọ, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti àwọn ẹranko orí ilẹ̀ láti jẹ àti láti parun.

  14. N ó sọ wọ́n di ẹni ìkórìíra níwájú gbogbo ìjọba ayé torí ohun tí Manase ọmọ Hesekiah ọba Juda ṣe ní Jerusalẹmu.

  15. O ti kọ̀ mí sílẹ̀,” ni Olúwa wí, “Ìwọ sì wà nínú ìpadàsẹ́yìn. Nítorí náà, Èmi yóò dáwọ́lé ọ, èmi ó sì pa ọ́ run, Èmi kò sì ní fi ojú àánú wò ọ́ mọ́.

  16. Èmi kò tún lè fi ìfẹ́ hàn si ọ, Èmi yóò fi àtẹ fẹ́ wọn sí ẹnu-ọ̀nà ìlú náà. Èmi yóò mú ìṣọ̀fọ̀ àti ìparun bá àwọn ènìyàn mi nítorí pé wọn kò tí ì yípadà kúrò lọ́nà wọn.

  17. Èmi yóò jẹ́ kí àwọn opó wọn pọ̀ ju yanrìn Òkun lọ. Ní ọjọ́-kanrí ni èmi ó mú apanirun kọlu àwọn ìyá ọmọkùnrin wọn. Lójijì ni èmi yóò mú ìfòyà àti ìbẹ̀rù bá wọn.

  18. Ìyá ọlọ́mọ méje yóò dákú, yóò sì mí ìmí ìgbẹ̀yìn. Òòrùn rẹ yóò wọ̀ lọ́sàn án gangan, yóò di ẹni ẹ̀tẹ́ òun àbùkù. Èmi yóò fi àwọn tí ó bá yè síwájú àwọn ọ̀tá wọn tí idà wà lọ́wọ́ wọn,” ni Olúwa wí.

  19. Olúwa sọ pé, “Dájúdájú èmi ò dá ọ sí fún ìdí kan pàtó; dájúdájú mo mú kí àwọn ọ̀tá rẹ tẹríba níwájú rẹ nígbà ibi àti ìpọ́njú.

  20. Ó yé ọ, ìwọ Olúwa; rántí mi kí o sì ṣe ìtọ́jú mi. Gbẹ̀san mi lára àwọn tó dìtẹ̀ mi. Ìwọ ti jìyà fún ìgbà pípẹ́, má ṣe mú mi lọ; nínú bí mo ṣe jìyà nítorí tìrẹ.

  21. Nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ dé, mo jẹ wọ́n, àwọn ni ìdùnnú àti ayọ̀ ọkàn mi, nítorí pé orúkọ rẹ ni a fi ń pè mí, Ìwọ Olúwa Ọlọ́run Alágbára.

  22. Èmi kò fìgbà kan jókòó láàrín àwọn ẹlẹ́gàn, n ko bá wọn yọ ayọ̀ pọ̀; mo dá jókòó torí pé ọwọ́ rẹ wà lára mi, ìwọ sì ti fi ìbínú rẹ kún inú mi.

  23. Èéṣe tí ìrora mi kò lópin, tí ọgbẹ́ mi kò sì ṣe é wòsàn? Ní òtítọ́ ìwọ yóò dàbí kànga ẹ̀tàn sí mi, gẹ́gẹ́ bí ìsun tó kọ̀ tí kò sun?

  24. Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí, “Tí o bá ronúpìwàdà, Èmi ó dá ọ padà wá kí o lè máa sìn mí; tí ó bá sọ ọ̀rọ̀ tó dára, ìwọ yóò di agbẹnusọ mi. Jẹ́ kí àwọn ènìyàn yìí kọjú sí ọ; ṣùgbọ́n ìwọ kò gbọdọ̀ kọjú sí wọn.

  25. Èmi fi ọ́ ṣe odi idẹ tí ó lágbára, sí àwọn ènìyàn wọ̀nyí; wọn ó bá ọ jà ṣùgbọ́n wọn kò ní lè borí rẹ, nítorí pé, mo wà pẹ̀lú rẹ láti gbà ọ́ là, kí n sì dáàbò bò ọ́,” ni Olúwa wí.