God
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God
“Má ṣe gbàdúrà fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí tàbí kí o bẹ̀bẹ̀ fún wọn, nítorí pé, Èmi kì yóò dẹtí sí wọn nígbà tí wọ́n bá ké pè mí ní ìgbà ìpọ́njú.
“Kí ni olùfẹ́ mi ní í ṣe ní tẹmpili mi, bí òun àti àwọn mìíràn ṣe ń hu oríṣìíríṣìí ìwà àrékérekè? Ǹjẹ́ ẹran tí a yà sọ́tọ̀ lè mú ìjìyà kúrò lórí rẹ̀? Nígbà tí ó bá ń ṣe iṣẹ́ búburú rẹ̀, nígbà náà jẹ́ kí inú rẹ̀ kí ó dùn.”
Olúwa pè ọ́ ní igi olifi pẹ̀lú èso rẹ tí ó dára ní ojú. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ìjì líle ọ̀wọ́-iná ni yóò sun ún tí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ yóò sì di gígé kúrò.
Olúwa àwọn ọmọ-ogun tí ó dá ọ ti kéde ibi sí ọ, nítorí ilé Israẹli àti Juda ti ṣe ohun ibi, wọ́n sì ti mú inú bí mi, wọ́n ti ru ìbínú mi sókè nípa sísun tùràrí si Baali.
Nítorí Olúwa fi ọ̀tẹ̀ wọn hàn mí mo mọ̀ ọ́n; nítorí ní àsìkò náà ó fi ohun tí wọ́n ń ṣe hàn mí.
Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa àwọn ọmọ-ogun, tí ó ń ṣe ìdájọ́ òdodo, tí ó ń ṣe àyẹ̀wò ẹ̀mí àti ọkàn, jẹ́ kí n rí ẹ̀san rẹ lórí wọn; nítorí ìwọ ni mo fi ọ̀rọ̀ mi lé lọ́wọ́.
“Nítorí náà, èyí ni ohun tí Ọlọ́run sọ nípa àwọn arákùnrin Anatoti tí wọ́n ń lépa ẹ̀mí rẹ̀, tí wọ́n ń wí pé, ‘Má ṣe sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ Olúwa, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ ìwọ ó kú láti ọwọ́ wa.’
Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ pé, ‘Èmi yóò fì ìyà jẹ wọ́n, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wọn yóò tipasẹ̀ idà kú, ìyàn yóò pa àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn.
Kò ní ṣẹ́kù ohunkóhun sílẹ̀ fún wọn nítorí èmi yóò mú ibi wá sórí àwọn ènìyàn Anatoti ní ọdún ìbẹ̀wò wọn.’ ”
Olúwa, olódodo ni ọ́ nígbàkígbà, nígbà tí mo mú ẹjọ́ kan tọ̀ ọ́ wá. Síbẹ̀ èmi yóò bá ọ sọ̀rọ̀ nípa òdodo rẹ. Èéṣe tí ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú fi ń ṣe déédé? Èéṣe tí gbogbo àwọn aláìṣòdodo sì ń gbé ní ìrọ̀rùn?
Ó ti gbìn wọ́n, wọ́n sì ti fi egbò múlẹ̀, wọ́n dàgbà wọ́n sì so èso. Gbogbo ìgbà ni ó wà ní ètè wọn, o jìnnà sí ọkàn wọn.
Síbẹ̀ o mọ̀ mí ní Olúwa, o ti rí mi o sì ti dán èrò mi nípa rẹ wò. Wọ, wọ́n lọ bí àgùntàn tí a fẹ́ pa. Yà wọ́n sọ́tọ̀ fún ọjọ́ pípa.
Èmi yóò kọ ilé mi sílẹ̀, èmi yóò fi ìní mi sílẹ̀. Èmi yóò fi ẹni tí mo fẹ́ lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́.
Ogún mi ti rí sí mi bí i kìnnìún nínú igbó. Ó ń bú ramúramù mọ́ mi; nítorí náà mo kórìíra rẹ̀.
Ogún mi kò ha ti rí sí mi bí ẹyẹ kannakánná tí àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ dòyì ka, tí wọ́n sì kọjú ìjà sí i? Ẹ lọ, kí ẹ sì kó gbogbo ẹranko igbó jọ, ẹ mú wọn wá jẹ.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùṣọ́-àgùntàn ni yóò sì ba ọgbà àjàrà mi jẹ́, tí wọn yóò sì tẹ oko mi mọ́lẹ̀; wọ́n ó sọ oko dídára mi di ibi tí a ń da ìdọ̀tí sí.
A ó sọ ọ́ di aṣálẹ̀ ilẹ̀ tí kò wúlò níwájú mi, gbogbo ilẹ̀ ni yóò di ahoro nítorí kò sí ẹnìkankan tí yóò náání.
Gbogbo ibi gíga tí ó wà nínú aṣálẹ̀ ni àwọn apanirun ti gorí, nítorí idà Olúwa yóò pa láti ìkangun kìn-ín-ní dé ìkangun èkejì ilẹ̀ náà; kò sí àlàáfíà fún gbogbo alààyè.
Àlìkámà ni wọn yóò gbìn, ṣùgbọ́n ẹ̀gún ni wọn yóò ká, wọn yóò fi ara wọn ṣe wàhálà, ṣùgbọ́n òfo ni èrè wọn. Kí ojú kí ó tì yín nítorí èrè yín, nítorí ìbínú gbígbóná Olúwa.
Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Ní ti gbogbo àwọn aládùúgbò mi búburú tí wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé ogún tí mo fún àwọn ènìyàn Israẹli mi, Èmi yóò fà wọ́n tu kúrò lórí ilẹ̀ wọn, èmi yóò fa ìdílé Juda tu kúrò ní àárín wọn.
Ṣùgbọ́n tí mo bá fà wọ́n tu tán, Èmi yóò padà yọ́nú sí wọn. Èmi yóò sì padà fún oníkálùkù ní ogún ìní rẹ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ ìní oníkálùkù.
Bí wọ́n bá sì kọ ìwà àwọn ènìyàn mi, tí wọ́n sì fi orúkọ mi búra wí pé, ‘Níwọ̀n bí Olúwa ń bẹ láààyè,’ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti kọ́ àwọn ènìyàn mi láti fi Baali búra, nígbà náà ni a ó gbé wọn ró láàrín àwọn ènìyàn mi.
Ṣùgbọ́n bí orílẹ̀-èdè kan kò bá gbọ́, Èmi yóò fà á tu pátápátá, èmi yóò sì pa wọ́n run,” ni Olúwa wí.
Èyí ni ohun tí Olúwa wí fún mi: “Lọ kí o sì ra àmùrè aṣọ ọ̀gbọ̀, kí o sì dì í mọ́ ẹ̀gbẹ́ rẹ, kí o má sì ṣe jẹ́ kí omi kí ó kàn án.”
Bẹ́ẹ̀ ni mo ra àmùrè gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti wí, mo sì dì í mọ́ ẹ̀gbẹ́ mi.